Justice for Richard: Òbí àkẹ́kọ̀ọ́ tó kú síléeṣẹ́ ọṣẹ ń bèèrè fún ìdájọ́ lórí ikú ọmọ wọn

Àkọlé fídíò, Justice for Richard: Òbí àkẹ́kọ̀ọ́ tó kú síléeṣẹ́ ọṣẹ ń bèèrè fún ìdájọ́ lórí ikú ọmọ wọn

Ọlọrun ma jẹ ka foju sunkun ọmọ laye ni adura ti obi maa n gba sugbọn to ba ri bẹẹ, Ọba oke la gbadura si pe ko tu obi ninu.

BBC Yoruba kan si obi Richard Gbadebo ti wọn kede iku rẹ lọjọ Isẹgun pe o ku sẹnu ẹrọ kan to n se ọsẹ nileesẹ kan nilu Ibadan.

Wọn ni Richard nikan soso ni ọkunrin tawọn bi, iku rẹ si ti mu ki orukọ idile parun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn mejeeji wa n beere pe o se jẹ ifun Richard nikan lo jade sita , ti ko sisi ipa ẹjẹ lara rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, baba Richard, Sola Phillips Gbadebo ni ejo lọwọ ninu iku ọmọ oun, ti awọn si n beere fun idajọ ki ọmọ naa ma ku iku sara lasan.