Mummy Calm Down: Oreofeoluwa báwọn àgbà òṣèré kópa nínú sinimá

Oríṣun àwòrán, ore_mommycalmdown/Instagram
Yoruba ni ọmọ ti yoo jẹ asamu, kekere lo ti maa n jẹ ẹnu samusamu.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ọmọdekunrin kan, Lawal Babalola Ooreofeoluwa ti ọpọ eeyan mọ si ọmọ Mummy Calm Down, ẹni tii se ọmọ ọdun marun.
Bẹẹ ba gbagbe, fidio Ooreofeoluwa yii lo gba ori ayelujara kan ni bi ọdun meji sẹyin ninu ibi ti ọmọdekunrin naa ti n bẹ iya rẹ to fẹ na nitori ẹsẹ to sẹ.
Ooreofeoluwa lo wa n sọkun, to si n sọ fun iya rẹ pe ko 'Calm Down' eyi to tumọ si pe ki iya rẹ fi ara balẹ.
Ọna awada ti Ooreofeoluwa fi n sọrọ ninu Fidio naa lo pa ọpọ eeyan lẹrin, ti wọn si n beere pe iru ọmọ wo ree, ti wọn fẹ ba wi, to si ni ki iya oun fara balẹ.
Lẹyin ti fidio naa lu ori ayelujara pa, ni Ooreofeoluwa di ilumọọka ni kekere, ti ọpọ eeyan si n seranwọ fun.
Koda, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu naa wa lara awọn to ni ki wọn gbe Ooreofeoluwa wa ki oun lọọfisi rẹ, ti awọn ileesẹ kan si tun yan ọmọde naa bi asoju ipolongo isẹ wọn, ta mọ si Ambassador.

Oríṣun àwòrán, ore_mommycalmdown/Instagram
Bawo ni Ooreofeoluwa se di osere tiata?
Asiko ti okiki ọmọdekunrin yii kan kaakiri lati ipasẹ fidio Mummy Calm Down yii naa ni gbajugbaja osere tiata kan, Kunle Afolayan mọ Ooreofeoluwa, to si ri abuda ere sise lara rẹ, eyi to tete se amulo rẹ ni kiamọsa.
Kunle Afolayan tii se osere tiata, oludari ere sinima ati agbesinima jade lo fi Ooreofeoluwa sinu sinima rẹ kan to gbe jade lọdun 2021 yii, eyi to gbe akọle rẹ ni 'Swallow'.
Ta ba si wo ọpọ ara ti Ooreofeoluwa da ninu sinima naa, a mọ pe abuda ere itage wa ninu aye ọmọ naa, abinibi si ni ere sise jẹ fun ninu sinima naa, lati ọrn lo ti mu abuda yii wa sile aye.
Ooreofeoluwa to fi ọpọ aworan to ti kopa ninu sinima naa loju opo Instagram rẹ lo se afihan pe kekere ni ọmọ yii wa, to ti n ba awọn agba osere jẹun.
Yoruba sa ni ọmọ to ba mọ ọwọ wẹ, yoo ba agba jẹun.
Lara awọn agba osere tiata ti Ooreofeoluwa ba kopa ninu ere sinima alarinrin naa ni Kunle Afolayan funra rẹ pẹlu Deyemi Okanlawon.

Oríṣun àwòrán, ore_mommycalmdown/Instagram
Awọn agba osere yoku ni Eniola Badmus, Chioma Akpotha, Adaku Lolo1, Kelvin Ikeduba ati Frank Donga.
Ninu ere sinima naa ni Eniola Badmus ti jẹ iya Ooreofeoluwa, ẹni ti wọn sọ ni Ayo ninu ere naa.
Lọwọ lọwọ bayii, irawọ Ooreofeoluwa ti n tan lagbo awọn osere tiata, adura wa si ni pe ina ọmọde naa to n tan, ko ni wọọkun laipẹ.
















