Disinformation, Nigeria elections: Ìwádìí BBC tú àṣírí àwọn ojú òpó kàn tó n tan ayédèrú ìròyìn kà nípa ìdìbò Nàìjíríà

Aworan ọdọ kan to n ka iroyin lori foonu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oju opo ayelujara lọpọ ti n ka iroyin ni Naijiria
    • Author, Akojọpọ lati ọwọ Chiagozie Nwonwu, Fauziyya Tukur, ati Olaronke Alo
    • Role, BBC Global Disinformation Team

BBC sewadii ti a si ri pe ọpọ awọn ou opo ti wọn da silẹ lasiko idibo apapọ Naijiria ni oṣu Keji 2023 lo n kan si ọpọ eeyan pẹlu iroyin ayederu.

Ipolowo ọja to n tẹle awọn iroyin yi loju opo wn tọka si ere tabua pẹlu bi wọn ṣe n tan iroyin ẹlẹjẹ kaakiri.

Wọn a maa da iroyin ere idaraya, oṣelu ati faaji papọ mọ aayederu iroyin wọn.O kere tan loṣu wọn a maa gbe iroyin ayederu ẹẹdẹgbẹrin jade bẹẹ wọn si nifẹ si gbigbe iroyin atako awọn oloṣelu sita.

Lẹyin nkan bi oṣu meje ti idibo pari,irori ṣi ṣe ọtọọtọ ni paapa a ri apẹrẹ nibi atako si idajọ igbimọ to n gbọ awuyewuye esi idibo lọsẹ to kọja.

O ṣeeṣe ki awọn iroyin ayederu ti o n jade lawọn oju opo yi maa da kun iyapa to n waye.

Agbẹjọro Mojirayo Ogunlana loun ranti pe bi idibo ṣe n sunmọ loun n ṣe alabapade awọn ayederu iroyin loju opo Twitter to yi orukọ pada si X bayii.

O loun ti ri iroyin lawọn oju opo toun ko gbọ orukọ wọn ri.Bakan naa lawọn eeyan n fi ayederu iroyin ranṣẹ loju opo Whatsapp.

O ni iṣọwọ fi iroyin aytederu ranṣẹ yi kọja bẹẹ. Arabinrin Ogunlana sọ pe "Ojumọ kan kii kja lai ṣe pe a ri ayederu iroyin loju opo ayelujara.O j ki n ma ni igbagbọ ninu iroyin mọ''

Ni ti tiẹ oluwadii nipa ayederu iroyin Mayowa Tijani n fọkan tele idagbasoke awọn oju opo yi.

O ni wọn ''kopa ribi to foju han lori idibo nitori pe awọn ọrọ ti wọn gbe jade di ohun taraaalu n jẹ lẹnu.''

O ni wọn o si sinmi lati maa gbe ayederu iroyin jade.

Bayi ti ọkan ninu awọn oju opo yi ba gbe iroyin ayederu jade, ohun to daju ni pe awọn to ku naa yoo gbe irufẹ iroyin naa sita pẹlu.Bayi ni wọn yoo ṣe tan iroyin naa kaakiri titi ti yoo fi gbalẹ.''

Ẹka iwadii BBC se agbeyẹwo mẹta ninu awọn oju opo yi to si ni orukọ wọn ni Podium Reporters ti wọn fi lọlẹ ni 2021,Reportera ti wọn gbe kalẹ ni oṣu Keje ọdun 2022 ati Parallel Facts to do ori ayelujara ni oṣu Kaarun dun 2023.

v

Ọgbẹni Tijani sọ pe asiko idasilẹ wọn ni ohun ṣe pẹlu iru iroyin ti wọn n gbe jade.Lakọkọ, o sọ pe o dabi pe awn oju opo yi n gbiyanju lati ṣatilyin fawọn oludije kan ni.Amọ o tun ni wọn n gbero lati pawo wọle soju opo wọn bakan naa.

A ba awọn to mọ nipa iroyin oju opo ayelujara ti wọn si s iru owo tawọn oju opo yi yoo maa pa wọle.

Yusufudeen A Yusuf to mọ nipa iṣ yi sọ pe wọn le maa pa to ọgrun dọla si ẹgbrun dọla loṣu kan $100-$10,000 (£80-£8,000).O ni bawọn eeyan ba ṣe n duro sọrọ lori iroyin wọn, bẹẹ ni owo yoo ṣe maa wọle fun oju opo yi.

Ṣugbọn Adebayo Ilupeju to n ba Africa Media Works ṣiṣẹ sọ pe nitori awọn oju opo yi ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, owo ti wọn yoo pa le ma pọ to bẹ gẹ.

A kan si oju opo Podium Reporters,Reportera ati Parallel Facts.Wọn ko fesi si ibeere taa fi ṣwọ nipa iroyin ofege to n jade loju opo wọn ati owo ti wọn n pa nidi rẹ.

Bola Ahmed Tinubu, Aarẹ Naijiria lasiko ti o fẹ dibo ninu idibo aarẹ ọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lasiko idibo 2023 ati lẹyin idibo awọn oludije mta to lewaju naa ni awọn oju opo yi gbe iroyin ofege jade nipa wọn.

Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC jawe olubori pẹu ida mẹtadinlogoji ibo .

Titi di isin awọn to ṣe ipo keji ati ipo kẹta ninu idibo ṣi n tako ijaweolubori rẹ.

Laipẹ yi igbimọ to n gbẹjọ awuyewuye esi idibo aarẹ tako awọn oludije meji yi ṣugbọn wọn sọ pawọn yoo tsiwaju lọ si ile ẹjọ to ag julọ ni Naijiria.

Awọn oloṣelu naa ṣe alabapin iroyin lati oju opo wọnyi to si mu ki wọn gbalẹ.

Festus Keyamo to jẹ Minisista feto irina ọkọ ofurufu Naijiria lọwọlọwọ wa lara awọn to pin ọpọ ninu iroyin Podium Reporters lasiko idibo.Bẹẹ naa ni Ọgbẹni Peter Obi naa kopa ninu itakurọsọ ojuopo Twitter lẹ̀ẹẹmeeji pẹlu Parallel Facts eleyi to mu ki awọn to n darukọ oju opo yi lọ soke lati ẹgbẹrun mẹwaa si ẹgbẹrun lọna ogoji laarin oṣu Kaarun si oṣu Keje ọdun 2023.

Kingsley Izuchukwu to juwe ara rẹ loju opo rẹ gẹgẹ bi ẹni to nifẹ si imọ ẹrọ tẹkinọlọji to si tako ijọba ti ko duro deede

O ti fi igba kan ṣalabapin aworan Peter Obi to si kọ akọle sabẹ rẹ pe ''Obi lẹni naa''

Akọmọna oju opo rẹ s pe awọn ko faaye gba iroyin ofege ṣugbn iwadii wa fihan pe eleyi jina sootọ.Laarin oṣu kan iyẹn BBC ka aimọye iroyin ofege to jade loju opo Parallel Facts.

Iroyin kan ti wọn gbe jade ni ọjọ Kẹtadinlogun sọ pe Yakubu Mahmoud,alaga ajọ eleto idibo INEC n gbimoran lati lo ọna ẹburu fi fun APC ni ibo ida 25% niluu Abuja. Amọ ko si ẹri kankan ti wọn fi kin ọrọ wọn pe INEC tabi arakunrin Mahmood yi esi idibo bi wọn ṣe sọ.

Lootọ ni awọn to n tan imọlẹ soot ti fi ododo han nipa irufẹ iroyin bayii,sibẹ wọn ko yi wọn pada loju opo wọn titi di asiko yi tawọn eeyan si n tsiwajulati ka iru iroyin bẹẹ.

Fẹndọ to n ta iwe iroyin lasiko idibo ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Reportera jẹ oju opo kan ti oun naa jọ pe o tẹri sọdọ oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

Ninu ọrọ kan to kọ si oke tente oju opo rẹ, o ni awọn ko faramọ ijọba Tinubu.

Laarin oṣu kan a ri pe wn gbe iroyin ofege mẹrin ọtọọtọ ti fi mọ ọkan to ni ipo kẹta ni Tinubu gbe ninu idibo to waye.

Bẹẹ lo tun yi abajade iwadii BBC kan lori idibo.

Ninu iroyin ti wọn gbe jade ni ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹfa 2023,Reportera sọ pe ''BBC fidi rẹ mulẹ pe gbangba lo han pe wọn ko jẹ kawọn eeyan jade dibo'' ati pe ko ṣeeṣe pe Ọgbẹni Tinubu ni wọn kede gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.

Amọ ko si nkan to jọ bẹ ninu iwadii BBC yi. Iwadii wa fi han pe lawọn aaye kan ni ipinlẹ Rivers ibo ti wọn fun ẹgbẹ Labour Party dinku ti tawọn APC si lọ soke.

A lo iroyin ti Inec gbe sita loju opo wọn eyi to tọka si pe iye ibo ti Labour Party ri yẹ ko mu wọn gba ibo to pọju lọ dipo ẹgbẹ APC.

Amọ a ko sọ wi pe a ni ẹri to fihan pe bẹẹ lọrọ yi ni ibomiran ni Naijiria debi pe a o tiẹ sọ pe ko yẹ ki Tinubu jaweolubori ninu idibo.

Ohun ti Reportera s ni pe awọn se agbeyẹw lalae sọ bi wọn ṣe fẹsẹ rẹ mulẹ pe Ọgbẹni Obi lo jaweolubori.

Kaka bẹẹ, nkan ti wọn sọ ni pe awọn gba ero awọn eeyan lori Twitter eyi to s pe ida 93% awọn eeyan 31,000 to kopa sọ pe Ọgbẹni Obi lo jaweolubori ninu idibo.

Lai pẹ yi oludasilẹ oju opo naa Nnamdi Ibezim gba pe lootọ lawọn gbe iroyin ofege jade.

Loju opo ayelujara Ọgbẹni Ibezim juwe ara rẹ gẹgẹ bi oniṣowo ati ẹni to mọ nipa iṣiro.Ni ọjọ Kẹfa oṣu Kẹjọ oju opo rẹ sọ pe minista feto ile igbe ati iṣẹ oju ọna to kọja Babatunde Fashola n ba awọn adajọ igbimọ to n gbẹjọ awuyewuye esi idibo kọ idajọ eyi to gbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu APC.

Fashola kede pe ohun ti kọwe ẹhonu ranṣẹ si ọga ọlọpaa to si ni Reportera ''fẹsun eke kan oun ti wọn si tun n tọ pinpin oun loju opo ayelujara''

Ọgbẹni Ibezim ni awọn ajọ ọtẹlmuyẹ DSS gbe aburo oun lọna aitọ nitori iroyin tawọn gbe jade yi.

Ileeṣẹ ọlọpaa fidi ọrọ mulẹ pe lootọ lawọn mu Chike Ibezim.

Awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP nibi iwọde ti wọn ṣe niwaju ileeṣẹ ajọ idibo INEC lori abajade ibo oṣu keji ọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwẹ,oju opo Podium Reporters a maa gbe iroyin to n gbe lẹyin APC nipa iroyin ti wọn n gbe jade.

Lọjọ Kẹrin oṣu Keje, 2023 wọn gbe iroyin jade nipa ẹgbẹ IPOB ti ijọba Naijiria ṣapejuwe gẹgẹ bi ẹgbẹ atgbesunmọmi.

Iroyin ti wọn gbe jade yi fi awọn ẹsun ti kii ṣe ootọ kọọkan kan wọn.

O ni bi apẹrẹ,IPOB font lu yiyan Obi gẹgẹ bi oludije.

Wọn o ṣẹṣẹ maa pa iru irọ ajọṣepọ Peter Obi ati IPOB yi.

Iroyin meje iru rẹ la ka ti Podium gbe jade laarin oṣu kan.

Ati Obi ati IPOB ni wọn ti s wi pe awọn ko lajọṣepọ to so wọn pọ.

Iwadii wa ko ribi fẹsẹ ẹni to ni ileeṣẹ iroyin Podium Reporters rinlẹ.