Deborah Samuel Killed in Sokoto: Àwon ìròyìn òfégè nípa ikú Deborah ní Sokoto rèé ati ìkọlù sí Bishop Kukah

Oríṣun àwòrán, Imam Abubakar
Ọpọlọpọ iroyin ofege lo ti ṣuyọ lẹyin iku arabinrin Deborah to jẹ ọmọ akẹkọọ ipele keji ni ileẹkọ imọ eto ẹkọ ti Shehu Shagari College of Education ni Sokoto ni Ọjọ Kejila, Oṣu Karun un, ọdun 2022.
Arabinrin Deborah ọhun ni wọn pa lẹyin ẹsun pe o sọ ọrọ odi si Muhammed.
Akojọpọ awọn iroyin ofege to waye naa ni BBC ṣewadii ti wọn si salaye rẹ si ibi;

Oríṣun àwòrán, Emeka fans page
Twitter gbona jainjain
Ohun akọkọ to kọkọ ṣẹlẹ lẹyin iṣẹlẹ naa lori ayelujara ni bi awọn Musulumi kan ati Kristẹni kan ṣe n tahun si ara wọn pẹlu ẹsun pe awọn ẹlẹsin Musulumi ni wọn n ṣe alakatakiti julọ.
Lẹyin naa ni ọpọlọpọ aworan, fidio ati atẹjade ti ko jẹ otitọ bẹrẹ si ni jade lori ẹrọ ayelujara.
Awọn iroyin ofege yii ti mu ki awọn eniyan maa kede pe iyapa ni ọna abayọ si ọrọ Naijiria.
Aworan ati fidio ni wọn ti pa awọn Kristẹni ni Sokoto
Emeka Fans Page lori ẹrọ idọrẹ Facebook lo kọkọ fi fidio lede pe ifẹhọnuhan ti bẹ silẹ ni Sokoto, to si ni wọn ti pa gbogbo awọn Kristẹni to wa nibẹ.
Eniyan bii 670,000 ni wọn ti wo fidio naa to si rọ awọn ọrẹ rẹ lati ṣe apinka fidio naa.
Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn yinbọn lu oluwọde meji amọ ko si aridaju pe ẹnikẹni ku ninu ifẹhọnuhan naa.
Bio tilẹ jẹpe fidio wa to ṣafihan awọn afẹhọnuhan to n jo taya ọkọ lori titi pẹlu ada, ti wọn si n gbadura ni ọna Islam, ṣugbọn ko si aridaju pe ẹnikẹni ku, ti ijọba si ti kede ofin konile-gbele fun ọjọ kan gbako.
Fidio obinrin ti wọn fi igi lu
Fidio miran ti wọn pin lo ṣafihan obinrin to wọ aṣọ funfun ti awọn ọkunrin kan si n fi igi lu u, ti awon obinrin miran to wo hijab si n wo iran re.
Ninu fidio naa lo ti n sọ ni ede Hausa pe ki wọn dariji o, oun ko ni ṣe bẹẹ mọ.

Oríṣun àwòrán, @w_ikem
Amọ iwadii ikọ BBC Disinformation Unit fihan pe o kere tan o ti pe ọdun meji ti fidio naa ti n ja ranyin, ti ko si niiṣe pẹlu iṣẹlẹ to waye ni Sokoto.
Iwadii fihan pe Kaduna ni iṣẹlẹ naa ti waye lẹyin ti ọwọ tẹ obinrin to wa ninu fidio naa fun ẹsun pe o ji awọn ọmọ to ṣi n ta wọn.
Amọ niiṣe ni awọn eniyan pinka pẹlu akọle pe wọn ti n pa awọn Kristẹni ni Sokoto.
Aworan akọroyin ti wọn sọ da ti dokita apaniyan
Aworan kan to n ja ranyin ṣafihan arakunrin Christopher Uche- Ayodeji (Dr Chris) to jẹwọ wi pe oun gba ki awọn Musulumi ku nigba to n ṣiṣẹ gẹgẹ bi dokita ni iha Ariwa Naijiria.
Aworan naa fihan pe dokita naa n ṣiṣẹ lọwọlọwọ ni ileewosan fasiti Birmingham.
To si ni oun ko tilẹ ni ibanujẹ ọkan lori ohun ti oun ṣe nitori oun gbẹsan ipaniyan alabagbele pọ oun ti wọn pa ni ọdun 2015.

Oríṣun àwòrán, @Sumy_ALIYU
Amọ ileewosan Birmingham ọhun ti ni ko si ẹni to n jẹ Dr Chris ni ọdọ awọn.
Ati wi pe fọto ti wọn lo naa ni akọroyin kan ni Niajiria ni, ti orukọ rẹ n jẹ Ayodeji Rotinwa, to si rawọ ẹbẹ si awọn eniyan lati jawọ lilo aworan ọhun.
Bakan naa ni ko si oju opo ẹnikankan to n jẹ Christopher Uche-Ayodeji (Dr Chris) lori Facebook ati awọn atẹjade to tẹlẹ.
Iroyin nipa ile Eniọwọ Mattew Hassan Kukah ti wọn jo
Iroyin ofege miran ti wọn tun pinka ni iroyin pe wọn jo ile Bisọọbu ijọ Aguda ni ipinlẹ Sokoto, Ẹniọwọ Mattew Hassan Kuku ni ilu Sokoto lasiko ifẹhọnuhan naa.
Amọ atẹjade ti ijọ naa fi lede ni wọn ko jo ijọ tabi ile Bisọọbu Mattew Hassan Kukah.
Bakan naa ni iroyin ni ferese ijọ Holy Family Catholic Cathedral to wa ni agbegbe Bello Way ati ijọ Kevin Catholic Church ni wọn jo lara rẹ.














