Deborah Samuel's Death: Ẹ yé gbé ìròyìn òfégè, a ò sọ pé ọmọ orílẹ̀ èdè Niger ni àwọn afurasí ta mú ní Sokoto - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Deborah Samuel

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Sokoto ti kéde wí pé ìròyìn òfégè ni ìròyìn tó gba orí ayélujára kan látọwọ́ akọ̀ròyìn iléeṣẹ́ NEWSLEAK, Segun Adegbite.

Adegbite nínú àtẹ̀jáde kan ní Ọlọ́pàá kan fi tó Iléeṣẹ́ Peoples Gazette létí wí pé ọkàn lára àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn wí pé ó lọ́wọ́ níbi ìṣekúpànìyàn ní ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni Shagari jẹ àjòjì láti orílẹ̀ èdè Niger.

Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà tí kò sì rí ẹsẹ̀ walẹ̀ àti pé àwọn kò fi àtẹ̀jáde kankan léde láti fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Sokoto, Sanusi Abubakar ní àwọn tó gbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ọ̀hún fẹ́ da omi àlàáfíà èyí tí àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ dá padà rú nítorí ìfẹ́ inú wọn lásán àti ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó wáyé ní ìpínlẹ̀ náà lọ́jọ́bọ̀.

Abubakar wá rọ̀ gbogbo àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn àti àwọn ará ìlú láti máa ṣe ìwádìí lórí àwọn ìròyìn yóò máa gbé, kí wọ́n yé kọ ẹ̀yìn àwọn ènìyàn síra wọn tàbí pète ogun.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Bákan náà ló fi kun pé ìwádìí sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣì ń lọ lọ́wọ́, tí àwọn yóò sì ṣe iṣẹ́ àwọn gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe làá kalẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Sokoto, Kamaldeen Kola Okunola ti rọ àwọn ará ìlú láti tẹ̀lé òfin kónílé-ógbélé èyí tí ìjọba kéde.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Ki lo ti ṣẹyin?

Àwọn Mùsùlùmí tó ṣekúpa Deborah nítori ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kò ní wọ párádísè - Sheikh Gumi

DSeborah Samuel

Oríṣun àwòrán, Gumi

Olukọ ẹsin Musulumi, Sheikh Ahmad Gumi ti darapọ mọ awọn to bu ẹnu atẹ lu bi awọn eeyan kan ṣe ṣekupa Deborah Samuel ni Sokoto lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o sọrọ kobakungbe si Anọbi.

Gunmi sọ pe ko si igba kankan ninu iwe mimọ Musulumi ti Anọbi funra rẹ ṣekupa ẹnikẹni nitori pe wọn sọrọ abuku si i bo tilẹ jẹ pe wọn sọrọ abuku si i ni aimoye igba.

Sheikh Gumi lo sọ ọrọ naa lasiko to n ṣe waasi ninu mọṣalaṣi kan niluu Kaduna.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Ninu fidio kan ti ileesẹ iroyin abẹle PR Nigeria fi lede, Gumi sọ pe idi ti anọbi ko ṣe gbẹsan lara awọn to n bu ni pe ko fẹ ki awọn eeyan ri oun bii apaniyan.

Ọrọ ti Gumi sọ yii ko ṣeyin bi awọn alakakiti ẹsin kan ṣe pa Deborah Samuel, to jẹ ọmọlẹyin Kristi ati akẹkọọ nile ẹkọ Shehu Shagari College of Education, niluu Sokoto lẹyin ti wọn ni o sọrọ odi si Anọbi.

Gumi ni "Ẹnikẹni to ba pa ẹni ti kii ṣe Musulumi, lẹyin ti wọn ti kọkọ ni adehun pe awọn yoo maa gbe pẹlu alaafia ko ni kofiri paradise fun ogoji ọdun."

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

"Ti a ba ro pe awọn ti kii ṣe ẹlẹsin kan naa pẹlu wa yoo dẹkun ati maa sọrọ abuku si Anọbi wa nitori pe wọn ti ṣekupa Deborah, niṣe ni a n tan ara wa jẹ."

Ọpọ araalu bu ẹnu atẹ iku Deborah

Titi di akoo yii, ori ẹrọ ayelujara ni Naijiria ṣi n gbona janyin-janyin lẹyin iṣekupani akẹkọbinrin naa lori ẹsun pe o sọ ọrọ odi si ẹsin Islam.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni arabinrin naa tabuku orukọ adari ẹsin Islam.

Nitori naa ni awọn akẹẹkọ kan ni ileẹkọ naa ṣe wọ jade ninu yara igbele ni ileẹkọ to wa, ti wọn si bẹrẹ si ni ju okuta lu, ti wọn si n naa pẹlu igi.

Lẹyin naa ni wọn pa a ti wọn si dana sun oku rẹ.

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji