Sokoto Deborah Blasphemy: Ìjọ Kátólìkì ní Sokoto fèsì sí ikọlù s'àwon ilé ìjósìn,wo ohun tí Kukah sọ

Ijọ Aguda ẹka ti ipinlẹ Sokoto ti fesi lori laasigbo to n waye n'ipinlẹ naa.
Eyi kò sẹyìn b'awọn ọdọ musulumi kan ni ilu Sokoto ṣe n kọlù awọn ile ijọsin ti wọn sì n ba nkan jẹ.
Olórí ijọ naa Rev Father Mathew Kukah ti Rev Fr Christopher Omotosho gbenusọ fun sọ pé kò sí ootọ ninu iroyin to gbode pe wọn se ikọlù sí ile Bishop Matthew Hassan Kukah.
- Ìjọba Sokoto kéde òfin kóníléógbélé lẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn lórí bí ọlọ́pàá mú àwọn tó pa Deborah Samuel
- Àsìkò ti tó kí ìjọba fihàn pé kò sẹ́ni tó kọjá òfin lórí ikú Deborah- Ẹgbẹ́ Mususlumi ní Nàìjíríà
- Osinbajo,Tinubu àti àwọn míì tó ṣetán láti kojú ìgbìmọ̀ àyẹwò APC réè lẹyìn tí wọn fí fọ́ọ̀mù ṣọ̀wọ̀
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
Àlàáfíà ni mo wà, wọn kò dáná sun ilé mi - Rev Father Matthew Kukah
O salaye pe awon agbalagba ati awọn ọdọ kan ṣe ikọlu lootọ ṣugbọn awọn ile ijọsin bi Golu Family Catholic Church to wa ni opopona Bello ati St Kevin's Catholic church to wa ni Gidan Dere ni wọn kọlù ti wọn sì jó apa kan ile ijosin naa.
Ẹwẹ o ni wọn fọ ferese Bishop Lawson Secretariat ti wọn sì ba ọkọ bọọsi ile ijosin naa ti wọn gbe sinu ọgbà wọn.
O fi kun pe wọn tún ṣe ikọlù sí Bakhita Centre to wa loju ọnà Aliyu Jodi ti wọn sì dana sun ọkọ bọọsi kanna níbẹ.
- Ṣé lóòtọ́ ni Jonathan ti gbẹ̀yìn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC? Nkan tí PDP àti APC sọ rèé
- Buhari kò ní fi oṣù mẹ́fà kún ìjọba rẹ̀ bí àwọn kan ṣe ń bèrè - Ìjọba àpapọ̀̀̀
- Ẹ má torí ìyansẹ́lódì ASUU dá ètò òṣèlú rú- Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà sì ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ NANS
- "Ọlọ́pàá ní kí n bọra sílẹ láti mọ bóyá obìnrin ní mí torí mo ní irùngbọ̀n"
- Ṣé lóòótọ́ ní pé arábìnrin tó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá tí pàdánù ẹ̀mí rẹ̀?
Ni gbogbo ẹ, atẹjade naa sọ pe awọn agbofinro ìkọ ọlọpaa kogberegbe yara tu àwọn alaburu yi ka ati pe ko si eeyan kankan to padanu ẹmi rẹ.
Hassan Kukah wa kàn sáárá sí Gómìnà Aminu Tambuwal fún bo se yara kede konileogbele wakati mẹrinlelogun ni Sokoto.
O wa rọ àwọn Kristẹni ni ipinlẹ naa lati bọwọ fún òfin kì wọn sì kún fún ádùrá ki alaafia le pada si ilu.
O ni gbogbo ìsìn ilé ìjósìn ni wọn ti so rọ titi di igba ti wọn yóò fi gbe'sẹ kuro lori konileogbele to wa nita












