Lady sleeping with dog update: Obìnrín tó bá ajá ní ìbálòpọ̀, kíni ọlọ́pàá sọ nípa ìròyìn ikú rẹ̀ tó gbòde

Aworan afihan arabinrin to ni oun ba aja lo pọ

Iroyin to gbode laipẹ yi pe arabinrin kan ni Ibalopọ pẹlu aja tun ti gba ọna mii yọ bayi.

Ohun taa tun gbọ ti o n mu awuyewuye wa sí ní pe arabinrin naa ti dagbere faye lẹyin iṣẹlẹ naa.

Ileesẹ ọlọpaa n'ipinlẹ Eko naa gbọ nipa iroyin yi ti wọn si ti fesi pe ko si ootọ ninu iroyin yi.

Alukoro ọlọpaa ni Eko Benjamin Hundeyin fi ọrọ yi lede ninu atẹjade kan to si ṣe alaye lori ohun ti iwadii awọn gbe jade.

Hundeyin ni nigba t'awọn gbọ nipa iroyin to sọ pe arabinrin naa ku nipasẹ kiko aisan latara Ibalopọ pẹlu aja, awọn kan si arakunrin to gbe iroyin yi si'ta ninu iwe iroyin Independent Newspapers.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Gẹgẹ bo ṣe salaye, arakunrin Kayode Ajiboye ni lootọ loun gbe iroyin jade nipa iku arabinrin naa ṣugbọn oun naa kan gbe iroyin naa loju opo mi ni lalai ṣe iwadii to yẹ.Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ti sọ ìgbésẹ̀ tuntun tí wọ́n fẹ́ gbé nípa ẹ̀sùn àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá

"Yatọ sí pe arakunrin yi kọ lo ni ọrọ to gbe jade yi ko bikita lati ṣe iwadii ọfintoto lori ọrọ yi.

Tori naa, o fi ara rẹ sí ipo biba wọn Pin iroyin ofege lawujọ."

O tẹsiwaju pe iwa to hu yi fihan pe o ṣeéṣe ki o maa lẹdi apo pẹlu arabinrin naa lati sa mọ awọn agbofinro lọwọ.

Bi a ko ba gbagbe ileesẹ ọlọpaa Eko n ṣe iwadii lori arabinrin yi ti wọn sì ni àwọn n wa lati wa sọ tẹnu rẹ lori iwa to hu ni itako si ofin Naijiria.

Ofin yi ni eleyi to lodi sí kí eeyan mọọmọ ni Ibalopọ pẹlu ẹranko.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Yala ajá tàbí ẹranko mìíràn ofin Naijiria fi ijiya ẹwọn ọdun mẹrinla le'lẹ fun ẹnikẹni tó bá ni Ibalopọ pẹlu ẹranko.

Lawujọ Naijiria lóde oni, awọn onwoye ni eyi to sunmọ òtítọ ni pé àwọn tó n ba ẹranko ni Ibalopọ n ṣe bẹ nitori pe ki wọn fi ṣe oogun owo.

Iru ihuwasi sí yi ni ìpalára fun ẹni to ba n ṣé iru rẹ nitori pé wọn lè ko aisan oríṣi nipa Ibalopọ pẹlu ẹranko.