Rape: Okùnrin ẹni ọdún 25 dèrò àtímọ́lé lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ àti ìbanilórúkọ jẹ́

Oríṣun àwòrán, POLICE
Okunrin ẹni ọdun marundinlọgbọn kan, Ebenezer Adeshina, ti ko si gbaga ọlọpaa ipinlẹ Ogun lori ẹsun ifipabanilopọ ati ibanilorukọjẹ.
Wọn ni Adeshina ba ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan lopọ, o tun gbiyanju lati ba orukọ ọmọ naa jẹ.
Ọlọpaa fi ṣikun ofin mu afurasi naa lọjọ kẹfa, oṣu Karunn un yii lẹyin ti ọmọ naa fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Owode Egbado.
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
- Óṣe! ènìyàn kan kú ẹlòmíràn farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe jábọ́ léwọn lórí l'Eko
- Fí fún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
- Ààrẹ Buhari pàrọwà sí ASUU láti padà sẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari
Ọmọ ọhun sọ fun awọn ọlọpaa pe oju opo Facebook ni oun ti pade afurasi naa lọdun 2021, awọn si ti n sọrọ lati igba naa wa.
Gẹgẹ bi ohun ti ọmọ naa sọ, afurasi naa sọ pe ki oun wa si ile rẹ loṣu Kẹta ọdun yii lati wa gba ẹgbẹrun mẹta naira owo ti oun yoo fi tun ẹrọ ilewọ oun to bajẹ ṣe.
Nigba to de ile rẹ ni afurasi na fun ni ẹlerindodo lati fi tura, amọ afurasi ọhun ti fi oogun orun sinu ẹlẹrindodo naa.
Ni kete ti ọmọ naa mu ẹlẹrindodo naa tan, to si sunlọ ni Adeshina ba ọmọ ọhun ni ibalopọ lodi si ifẹ inu rẹ.
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni ni kete ti Adeshina ba ọmọ naa lopọ tan.
O ya aworan ihoho rẹ, o si dukoko mọ pe oun yoo fi awọn aworan naa si ori ayelujara ayafi to ba fun oun ni owo ti iye rẹ to ẹgbẹrun lọna aadọta naira.
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
- Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó bẹntiró ń rúgbó bọ̀- IPMAN ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
Oyeyemi fi kun pe afurasi naa jẹwọ ẹsun ọhun ni agọ awọn lẹyin ti ọwọ ọga ọlọpaa, DPO Owode Egbado tẹ tan.
O fi kun pe kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ ki wọn tari ẹjọ rẹ si ẹka CID fun iwadii ni kikun, ko si le foju bale ẹjọ laipẹ.



















