Sri Lanka protests: Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si

Sri Lanka foju wina awọn olufẹhonuhan to n dana sun dukiya fun alẹ keji lọjọ Iṣẹgun, gẹgẹ bi ọpọlọpọ dukiya ṣe ṣofo niluu Negombo to n bẹ ni itosi olu ilu naa tii ṣe Colombo.
Ọgọrọ awọn olufehonuhan lo yawọ ibudo igbafẹ kan ti o jẹ ti ọmọ olootu agba tẹlẹri, Mahinda Rajapaksa.
Lọjọ Aje ni irora ti awọn eeyan ilu n ke lori eto ọrọ aje kọja amojuto lẹyin ti awọn alatilẹyin ijọba ṣe ikọlu si awọn olufẹhonuhan ti wọn fẹ ki Aarẹ Gotabaya Rajapaksa kọwe fi ipo silẹ.
- Àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe Poly ní Nàìjíríà , ASUP bẹ́rẹ́ ìyanṣẹ́lódì, wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀
- Buhari pàṣẹ fún àwọn mínísítà tó bá fẹ́ dupò òṣèlú láti kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ ní kíá
- Genevieve Nnaji fi fídíò sí Instagram, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ìròyìn sọ pé ó ní àrùn ọpọlọ
- Johnson Sulemann sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn tí Stephanie Otobo fi kàn án
- Wo àwọn tó ra fọ́ọ̀mù ipò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Buhari kò ní fi oṣù mẹ́fà kún ìjọba rẹ̀ bí àwọn kan ṣe ń bèrè - Ìjọba àpapọ̀̀̀
Eeyan mẹjọ lo ti jade laye bayii, gẹgẹ bi awọn eeyan to le ni igba ṣe fi ara pa ninu iṣẹlẹ naa.
Orilẹede Sri Lanka ti n koju ifẹhonuhan fun ọpọlọpọ ọsẹ bayii lorii airajaja ọrọ aje ti o si ti ṣe akoba fun owo ti wọn n na lorilẹede naa, 'Sri Lankan rupee' de ibi ti ounjẹ ati epo ti di ọwọngogo.
Awọn ile itaja ati ileeṣẹ mii ni yoo maa jẹ titi pa fun ọjọ kẹta nipasẹ aṣẹ konile-o-gbele to gbode titi di owurọ Ọjọbọ.
Ipade laarin awọn adari ẹgbẹ oṣelu Sri Lanka ti di ohun to n waye lori itakun ayelukara bayii, nitori ipenija eto aabo.
Bo tilẹ jẹ pe wi pe wọn ti paa laṣẹ fun awọn ẹṣọ aabo ti wọn fọn si igboro lati yinbọn fun ẹnikẹni ti wọn ba ri to n tapa si ofin ilu, eleyii ko mu ki awọn olufẹhonuhan dẹkun ariwo ti wọn n pa ni agbegbe 'Galle Face Green' wi pe Aarẹ Rajapaksa ti da oju eto ọrọ aje orilẹede naa de, o si gbudọ fi ipo silẹ.
- Ṣé lóòtọ́ ni Jonathan ti gbẹ̀yìn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC? Nkan tí PDP àti APC sọ rèé
- Wo ìdí tí Ilé aṣòfin àpàpọ̀ Nàìjíríà ṣe yí òfin ìdìbò padà fún ààrẹ, gómìnà, àwọn aṣòfin àtàwọn míràn
- Kò sí akẹ́kọ̀ọ́ ìpínlẹ̀ Sokoto, Zamfara tí yóò ṣe ìdánwò WASSCE lọ́dún 2022
- Ìdí mẹ́ta tí Goodluck Jonathan kò fi lè díje dupò lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan lásìkò yìí
- Wo àwọn obìnrin mẹ́wàá tí ipa wọn kò ṣe fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní ààfin Oyo
Ẹni ti o jẹ ẹgbọn fun Aarẹ orilẹede naa, Mahinda ti fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bii olootu agba l'ọjọ Aje ninu igbiyanju lati pẹtu si awọn olufẹhonuhan naa lọkan, ṣugbọn igbesẹ naa ko yin wọn lọkan pada.
Aarẹ Rajapaska ti n ṣe ipade pọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu ti o ku lati le ṣe agbekale igbimọ ti yoo dele fun awọn alakoso orilẹede naa, ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu alatako fi ọrọ lede wi pe awọn ko ni kopa ninu igbimọ naa, afi ki Aarẹ fi ipo rẹ silẹ.



















