ASUP strike 2022: Àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe Poly, ASUP bẹ́rẹ́ ìyanṣẹ́lódì, wo ohun tó kàn báyìí

Oríṣun àwòrán, other
Ẹgbẹ awọn olukọ ileẹkọ gbogboniṣe Poly lorilẹede Naijiria bẹrẹ iyanṣẹlodi jakejado Naijiria lọjọru, ọjọ kọkanla, oṣu karun un,ọdun 2022.
Osẹ meji ni wọn yoo kọkọ fi ṣe ikilọ fun ijọba pẹlu iyanṣẹlodi yii.
Ọgbẹni Anderson Ezeibe to jẹ aarẹ ẹgbẹ naa ṣalaye fun BBC pe bi ijọba ṣe kuna lati ṣiṣẹ lori adehun to wa laarin wọn lati ọdun to kọja.
Bi iyanṣẹlodi yii ba tẹsiwaju, a jẹ wi pe gbogbo awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga fasiti ati gbogboniṣe Poly to jẹ ti ijọba lorilẹede Naijiria ni wọn wa nile bayii nitori iyanṣẹlodi awọn olukọ lawọn ile ẹkọ giga naa.
- Genevive Nnaji fi fídíò sí Instagram, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ìròyìn sọ pé ó ní àrùn ọpọlọ
- Johnson Sulemann sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn tí Stephanie Otobo fi kàn án
- Buhari kò ní fi oṣù mẹ́fà kún ìjọba rẹ̀ bí àwọn kan ṣe ń bèrè - Ìjọba àpapọ̀̀̀
- Wo àwọn tó ra fọ́ọ̀mù ipò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Buhari pàṣẹ fún àwọn mínísítà tó bá fẹ́ dupò òṣèlú láti kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ ní kíá
- Ṣé lóòtọ́ ni Jonathan ti gbẹ̀yìn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC? Nkan tí PDP àti APC sọ rèé
- Kò sí akẹ́kọ̀ọ́ ìpínlẹ̀ Sokoto, Zamfara tí yóò ṣe ìdánwò WASSCE lọ́dún 2022
Awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ fasiti gbogbo to jẹ ti ijọba lorilẹede Naijiria ti wa lẹnu iyanṣẹlodi lati oṣu keji ọdun 2022, ti wọn si tun ti fi ọsẹ mejila kun un bayii.
Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ nile ẹkọ gbogboniṣe Poly lorilẹede Naijiria, ASUP ni iyanṣẹlodi awọn naa ṣe pataki nitori gbedeke ọsẹ mẹrin ti awọn fun ijọba lati ṣiṣẹ lori ẹhonu wọn ti pe, ko si so eso kankan.
O ṣalaye pe lọjọ kẹrin oṣu kẹrin ọdun 2022 ni gbedeke ti wọn fun ijọba bẹrẹ to si ti pari ni ọjọ kẹrin oṣu karun un.
Kọmureedi Anderson Ezeibe fidi rẹ mulẹ pe o ṣeeṣe ki iyanṣẹlodi awọn bẹrẹ lọjọru ọjọ kọkanla oṣu karun un ọdun 2022.
Ki lawọn ẹhonu ẹgbẹ ASUP?
Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly lorilẹede Naijiria, ASUP Kọmureedi Anderson Ezeibe ṣalaye pe ohun mẹta lawọn n ja fun.
Akọkọ ni owo agbedide ti ijọba ṣeleri lati fun wọn, ṣugbọn ti awọn ko tii ri ṣiṣi gba ninu rẹ.
- Báwo ni ọ̀rọ̀ ilé ṣe fa Gbas-gbos láàrín Mercy Aigbe, ìyáále rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀?
- Human Rights Watch fẹ̀sùn àìbìkítà kan ìjọba Naijiria lẹ́yìn ikú awọn olùwọ́de lásìkò ìwọ́de EndSARS
- Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Uche Igwe di èrò iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pínpín fídíò ìbálòpọ̀ ọmọdé
- Kọ́ńdọ̀ọ̀mù méjìlá lá rí ní iyàrá ilé ìtura tí wọ́n ti fípa bá arábìnrin Ulochi lòpọ̀- Olọ́pàá
- Èmi ò gbé'ṣẹ́ rán ẹnikẹ́ni láti ra fọ́ọ̀mù ìdíje ààrẹ fún mi o, ẹ máà kóbá mi -Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Goodluck Jonathan fún Miyetti Allah lésì
- Wo àwọn òjé tí àwọn olóṣèlú máa fi ń jẹ àwọn ènìyàn bí ètò ìdìbò bá ti ń súnmọ́lé
- Ìpapòda Aláàfin kò ní dá ètò ìfinijoyè Gbajabiamila dúró- Ọyọmesi
- Ó pé ọdún 35 tí Obafemi Awolowo kú, wo àwọn nkan mánigbàgbé tí o kò gbọ́ rí nípa rẹ̀
O ni ninu ẹgbẹrin biliọnu Naira ti awọn ni ki ijọba fi ṣe agbedide ẹka eto ẹkọ naa, biliọnu marundinlogun naira ni ijọba gba lati san, ninu rẹ, wọn ko si tii san kọbọ.
Ẹhonu keji ti wọn n ja fun ni atunṣe ilana iṣẹ wọn. O ni lati oṣu kejila ọdun 2021 ni wọn ti bẹrẹ ijiroro lori rẹ, ṣugbọn ọrọ naa ko tii yọri si ibi to dara.
Koko ẹhonu kẹta ti o n fa wahala laarin ẹgbẹ̀ ASUP ati ijọba lorilẹede Naijiria bayii ni ọrọ owo oṣu to kere julọ tawọn oṣiṣẹ le gba.
ASUU, ASUP pẹlu iyanṣẹlodi lọwọ kan naa
Awọn olukọ fasiti lorilẹede Naijiria, ASUU n gun le iyanṣẹlodi lorilẹede naa bayii; bi awọn olukọ ile ẹkọ gbogboniṣe Poly lorilẹede Naijiria, ASUP ba tun lọ darapọ, a jẹ wi pe gbogbo awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga to jẹ ti ijọba lorilẹede Naijiria lo di ero ile.
Kii si i ṣe oni, bẹẹni kii ṣe ana ti awọn olukọ nile ẹkọ giga fasiti, ASUU ati ti gbogboniṣe Poly lorilẹede Naijiria, ASUP ti n ja fun eto igbayegbadun to dara ṣugbọn bi awọn ijọba ṣe n kuna lati ṣika adehun wọnyii lo n fa ọpọlọpọ wahala lẹka yii lọpọ igba.

















