Obafemi Awolowo: Ó pé ọdún 35 tí Obafemi Awolowo kú, wo àwọn nkan mánigbàgbé tí o kò gbọ́ rí nípa rẹ̀

Obafemi Awolowo

Oríṣun àwòrán, other

Oni, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2022, lo pe ọdun marundinlogoji, ti Obafemi Jeremiah Awolowo, kú.

Ọjọ kẹsan, oṣu Karun-un, ọdun 1987 lo ku si ilu Ikenne, nipinlẹ Ogun, lẹni ọdun mejidinlọgọrin.

Odu ni oloogbe Awolowo laarin awọn ọmọ Naijiria, ati nilẹ okeere, nitori ipa ribiribi to ko ninu idagbasoke Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ọkọ̀ Awólọ́wọ̀ yìí ti lọ yíká Nàíjíríà

Tani Oloye Obafemi Awolowo?

Wọn bi Awolowo ni ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun 1909, nipinlẹ Ogun.

O kẹkọọ gboye nipa eto ọrọ aje, to si tun gboye imọ ofin ni orilẹ-ede England lọdun 1945.

Ṣaaju asiko yii, Awolowo ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọroyin, to si da ileeṣẹ iroyin Nigerian Tribune silẹ lọdun 1949.

Nigba to pada si Naijiria lẹyin eto ẹkọ rẹ, o di olori ẹgbẹ oṣelu Action Group,

Lẹyin naa lo di olootu ijọba ẹkun Gusu Naijiria.

Gẹgẹ bi olootu ijọba, o ṣe idasilẹ eto ẹkọ ọfẹ nile ẹkọ alakọbẹrẹ, ati eto ilera ọfẹ, jakejado Gusu Naijiria.

Yatọ si eyi, oloogbe Awolowo, lo ṣagbatẹtu bi ijọba ṣe kọ papa iṣere akọkọ ni Naijiria, Liberty Stadium, nilu Ibadan.

Ipa kekere kọ ni Oloye Awolowo kó ninu ijagbara fun ominira Naijiria kuro lọwọ awọn oyinbo amunisin.

Lọdun 1963, ijọba ju si ẹwọn fun ẹsun pe o ru awọn eeyan soke lati tako ijọba. Ọdun 1966 lo to gba ominira, to si di minisita eto isuna.

Àkọlé fídíò, Awo Stage Play: Wo eré, ijó àti orin tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ayé Awolowo àti aya rẹ̀

Awọn nkan mii ti Awolowo ṣe ninu itan Naijiria

Awolowo lo fun owo Naira ni orukọ, nigba to fi jẹ minisita akọkọ fun eto iṣuna.

O da ileeṣẹ tẹlifisan akọkọ ni Africa, Western Nigeria Television silẹ nilu Ibadan, lọdun 1959. Ileeṣẹ tẹlifisan naa lo pada di NTA.

Oun lo kọ Ile gogoro 'skyscrapper' akọkọ ni Africa, Cocoa House, silu Ibadan

Obafemi Awolowo ni ẹni akọkọ ti wọn fun ni orukọ 'Asiwaju Omo Oodua', gẹgẹ bi olori oṣelu nilẹ Yoruba.

Awọn iwe to kọ ko to o ku ni:

•Path to Nigerian Freedom

•Awo - Autobiography of Chief Obafemi Awolowo

•My Early Life

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

•Thoughts on the Nigerian Constitution

•The People's Republic

•The Strategy & Tactics of the People's Republic of Nigeria

•The Problems of Africa - The Need for Ideological Appraisal

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

•Awo on the Nigerian Civil War

•Path to Nigerian Greatness

•Voice of Reason

•Voice of Courage

•Voice of Wisdom

•Adventures in Power - Book 1 - My March Through Prison

•Adventures in Power - Book 2 - Travails of Democracy

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

•My march through prison

•Socialism in the service of New Nigeria

•Selected speeches of Chief Obafemi Awolowo

•Philosophy of Independent Nigeria

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

•Memorable Quotes from Awo

•The Path to Economic Freedom in Developing Country

•Blueprint for Post-War Reconstruction

•Anglo-Nigerian Military Pact Agreement

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua