Pa Olabode Olajide: Dẹ́rẹ́bà Awolowo ti jáde láyé l'ẹni ọdún 89
Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe awakọ to wa Chief Obafemi Awolowo nigba aye rẹ ti jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọrun.
Pa Olabode Olajide la gbọ pe o ki duniya pe o di gbere lẹyin aisan ranpẹ.
Mọlẹbi baba kan to fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC sọ pe iku agbaọjẹ dirẹba yi waye lẹyin ọjọ mẹta ti iyawo rẹ papoda.
- Kiki Osinbajo gbóṣùbà fún Seyi Awolowo, MC Oluomo tọrọ ìbò fún Mike ní BBNaija
- Àwọn èèkàn ìlú péjú s'Ibadan níbi ìsìnkú màmá Omotola àkọ́bí obìnrin Awolowo tó wọ káà ilẹ̀ lọ
- Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é
- Day 13: Àwọn ńkan méje tí ẹ lè má mọ̀ nípa Igbákejì Ààrẹ Osinbajo #BBCNigeria2019
''Daddy wa ati Mummy wa ti ku.Pa Olajide Olabode ku ni nkan bi ago marun un aarọ.Mummy wa naa ku ṣaaju wọn ni ijẹta.Baba ku ni ana.''
Olabode Oladapo to jẹ ọmọ Pa Olabode ṣalaye pe wọn ku si Ado lẹyin ti wọn ṣaaju gbe wọn lọ si ile iwosan ni Ife.
''Wọn gbe wọn lọ si Ife ṣugbọn a gbe wọn pada wa si Ado. Nibẹ ni wọn ku si.''
Baba Olabode Olajide ni awakọ to wa ọpọlọpọ awọn aṣaaju orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Naija Gist
Ni gbogbo akoko to fi wa wọn, ko si eyi ti ko ranti ninu wọn to fi mọ igba ti awọn adari orilẹede mii lagbaye naa ba wa ṣe ibẹwo si awọn ti Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe baba Olajide ni awọn obi ko ri owo tọ ọ kọja ile iwe alakọbẹrẹ, o tiraka lati sọ ara rẹ di akọṣẹmọṣẹ ninu iṣẹ awakọ lai mọ wi pe eyi yoo sọ oun di mọlumọka to di lonii.
Laipẹ yi ni awọn eeyan tun ranti Pa Olabode nigbati igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo ṣabẹwo si baba ati iyawo rẹ.













