Nigeria 2019 Elections: Àna Awolowo, ọ̀jọ̀gbọ́n lẹ́ni ogójì ọdún àti àwọn ǹkan mìíran tí ẹ kò mọ̀ nípa Osinbajo

Igbakeji aarẹ Naijiria Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Profosinbajo/Instagram

Ki ti ẹ̀ ni àwọn oun tí ẹ mọ̀ nípa ayé ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo tó ń díje dupò fún sáà kejì gẹ́gẹ́ bíi amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Ààrẹ Muhammadu Buhari?

Ọlọ́run dóólà ẹ̀mí rẹ̀ ọjọ́ Abamẹ́ta níbi to ti lọ ṣe ìpolongo ìbò ní Kabba, Ìpínlẹ̀ Kogi.

Ṣe ni ọkọ̀ rẹ̀ dojú dé nígbà tí ó fẹ́ gbéra, ṣugbọ́n ko fi ara pa rárá, èyí tí àwọn ènìyàn fi ríi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ọ̀tọ̀.

Àwọn ǹkan méje tí ẹ lè má ràntí nípa ayé rẹ̀ rèé:

1. Ọmọ ọdún nmẹ́tàlélógún ló di olùkọ́ni ní fásitì

Ọdún 1957 ni a bí Oluyemi Oluleke Osinbajo nílé ìwòsàn kan nílùú Eko tí ó sì bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìla ní 1969 ní ilé ìwé àkọ̀bẹ̀rẹ̀ Corona nílùú Eko. Ó tẹ̀ síwájú lọ ilé ìwé girama Igbobi to wa ni Yaba nibi to ti gba ọpọlọpọ àwọn ẹ̀bùn fún orípípé.

Ó ló fásitì Eko, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ òfin ní ọdún 1978 nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mọ̀kànlélógún. Ọdún méjì lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n gbàá gẹ́gẹ́bíi olùkọ̀ nílé ìwé náà lẹ́yìn tó ti gbóye àgbà ni London School of Economics.

Igbakeji aarẹ Naijiria Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Profosinbajo/Instagram

2. Ọmọọmọ Olóyè Ọbafẹmi Awolọwọ ni lo di ìyàwó rẹ̀

Oṣinbajo fẹ Dolapo Soyọde, ọkan lára àwọn ọmọọmọ Oloye Obafẹmi Awolọwọ ọkan lara awọn agbaagba ilẹ Yoruba. Iya Dolapo ni ọmọbinrin Awolọwọ to ti ṣe alaisi, Ayo Soyode, ẹgbọn Tokunbo Awolowo Dosunmu.

Ita fi han wípé, nígbà tí Osinbajo wa ni ọmọ ọwọ, Awolọwọ gbọ́wọ́ lée lórí tó sì gbádúrà fun nígba tó pàdé àwọn òní rẹ̀.

Igbakeji aarẹ Naijiria Yemi Osinbajo ati Iyawo rẹ Dolapo

Oríṣun àwòrán, Profosinbajo/Instagram

3. Osinbajo bá Amòfin Àgbà orílẹ̀èdè Naijiria nígbà kan rí Bola Ajibola ṣíṣẹ́

Láàrin ọdún 1988 sí ọdun 1992, Amòfin Àgbà orílẹ̀èdè Naijiria nígbà náà Bola Ajibola yàn án gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́. Ibẹ̀ ló ti kọ́kọ́ rí ìtọ́wò ọ̀rọ̀ òṣèlú.

4. Ó di ọ̀jọ̀gbọ́n nígbà tó wà ní ẹni ogójì ọdún

Ní ọdún 1997, Osinbajo di ọjọ ní fásiti Eko ní ẹ̀ka imọ̀ òfin ti ìlú.

Igbakeji aarẹ Naijiria Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Profosinbajo/Instagram

5. Gomina Bola Tinubu sọ́ di amòfin àgbà ní Eko

Lẹ́yin ọdun méjì ti di ọ̀jọ̀gbọ́n ni Gomina Ipinlẹ Eko nígba náà Bola Tinubu sọ́ di amòfin àgbà àti kómọíṣọ́nà fún ìdájọ́ láàrin ọdiun 1999 sí ọdún 2007.

Bó ṣe kúrò ní ipò yìí ló padà sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa ofin ìlú ní fásitì Eko.

6. O di amofin agbà ní ile iṣẹ́ àdáni

Ní ọdún 2007 tó kùrò nínú ipòi òṣèlú ni Ilé Iṣẹ́ àwọn amòfin Simmons Cooper Partners sọ́ di ọ̀gá.

Igbakeji aarẹ Naijiria Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Profosinbajo/Instagram

7. Pásítọ̀ ni kó tó di igbákejì ààrẹ

Kí Osinbajo to di igbákeji ààrẹ ní ọdún 2015, oun ni àlùfáà olórí ijọ Redeemed (RCCG) kan tó wà ní Ikoyi. O máa ń sọ wípé òun ṣì ni olórí ìjọ náà àti wípé ìjọba àpapọ̀ yá òun lò ni.

Aarẹ Muhammadu Buhari ati Igbakeji aarẹ Naijiria Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Profosinbajo/Instagram

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ si:

Àkọlé fídíò, Festus keyamo: Ọ̀rọ̀ Obasanjọ sí Buhari ti di ìrégbè