Oyo Chieftancy Coronation: Ìpapòda Aláàfin kò ní dá ètò ìfinijoyè Femi Gbajabiamila dúró- Ọyọmesi

Alafin ati Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ti baba ba ku, baba nii ku, adiyẹ kii si ku kaa dọmọ rẹ nu.

Ni kete ti Alaafin ilu ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi tẹri gbaṣọ ni ọpọlọpọ ti sọ pẹ oye Aarẹ Baasofin ti ilẹ Yoruba ti Alaafin fẹ fi da Abẹnugan ile igbimọ aṣojuṣofin orilẹ ede Naijiria, Femi Gbajabiamila lọla ni o ṣe ṣeeṣe ki o ma waye mọ.

Ṣugbọn ọrọ yipada ni ọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ, oṣu karun-un, ọdun 2022 nigba ti Oyomesi ni ipapoda Alaafin ko ni da jijẹ oye naa duro.

Basorun ilu Oyo, Oloye Olayinka Ayoola lo sọ ọrọ naa nigba ti Gbajabiamila ṣe abẹwo si Aafin ilu Oyo lati ba idile Alowolodu, Oyomesi ati gbogbo ilu Oyo kẹdun Alaafin Adeyemi to lọ darapọ mọ awọn babanla rẹ

Oloye Ayoola ni ifinijoye naa jẹ nnkan ti Ọba Adeyemi fẹ ko ṣeeṣe ki wọn to waja ṣugbọn àwọn alalẹ ko kọ.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Ninu ọrọ mọlẹbi Alowolodu, Ọmọọba Akeem Adeyemi sọ pe tori Gbajabiamila jẹ ọkan lara awọn Yoruba to gbe Aṣa ati iṣe ẹya naa larugẹ ni Ọba Lamidi fi ni pe oye naa tọ sii.

O ni "Alaafin ni gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, Gbajabiamila koju oṣuwọn lati di Aarẹ Baasofin ilẹ Yoruba, o si di dandan lati di ṣiṣe."

Ayẹyẹ ifinijoye naa lo yẹ ko waye lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu karun-un, ọdun 2022 lati fi ṣami ayẹyẹ ọjọ ibi abẹnugan naa.