Army couple kiled in Imo: Mọ̀lẹ́bí ṣàlàyé kíkún nípa bí agbébọn ṣe ṣekúpa Gloria Mathew àti àfẹ́sọ́nà rẹ̀ nínú igbó ní ìpínlẹ̀ Imo

Bí agbebọn ṣe ṣe ikú pa Ọmọ Ológun, ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ àti àwọn méjì mìíràn ní ìpínlẹ̀ Imo - Mọ̀lẹ́bíIkú àwọn Sójà tọkọ-taya tí wọ́n gé lórí kò yẹ àwùjọ ọmọ ènìyàn rárá - Ààrẹ́ Buhari
Ilé isẹ BBC ti fi idi ẹ mule pe ọmọ ologun Naijiria, Private Gloria Matthew padanu ẹmi rẹ pẹlu ọkọ afesona rẹ ologun fẹyinti Linus Musa Audu ati awọn mọlebi wọn meji ni agbegbe kan to n jẹ Orlu ni Ipinle Imo.
Ọkan lara molebi awọn oloogbe to bá BBC soro ninu ifọrọwerọ ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti awọn gende ọkunrin mẹrin kan se ikọlu si wọn ni 'Banana junction' ni agbegbe Orlu.
Ninu ọrọ mọlẹbi naa, "O sẹlẹ nibi agọ mẹta ọsan nigba ti wọn n bọ lati ilu Eko lọ si Nkwerre."
- Ṣé 'skit' àbí òótọ ni bí olùdárí eré ṣe ni dandan ni kí Biola Fowosere wọ aṣọ oníhòhò? Ohun ti a mọ̀ rèé
- Fathia Balogun kéde aṣọ ẹbí ₦150,000 àti ₦120,000 fún ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Mo tọrọ àforíjì pé mo parọ́ ìgbéyàwó! Mi ò ṣe ìgbéyàwó kankan!
- Àwọn iléeṣẹ́ bàlúù ní Nàìjíríà ronúpìwàdà lórí wíwọ́gilé ìrìnnà òfúrufú ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Ajé, ohun tó fàá nìyí
- Wo ohun táwọn èèyàn ń sọ sí Mercy Aigbe torí àṣírí tí ìyàwó àkọ́fẹ́ Adekaz tú síta
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì á bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn nítorí ìyansẹ́lódí ASUU
- Ẹgbẹ́ CAN foríjin ilé ìfowópamọ́ Sterling, ìdí rèé

Mọ́ sii nipa ohun ti Molebi rẹ sọ:
Molebi ọhun ṣalaye pe awọn mejeeji pẹlu awọn molebi meji naa to tẹlẹ wọn wa lori irinajo fun ayẹyẹ igbeyawo Private Matthew ati Audu to yẹ ko waye ni ọjọ keji oṣu kaarun ni ijoba ibile Nkwerre.
"Audu wa lati guusu Kaduna ṣugbọn o n gbe ni Makurdi ti Gloria si wa ni Sokoto. Awọn mejeeji de si ilu eko ni ojọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹrin lati gbe iya Gloria ki wọn le jọ rin irinajo naa papọ fun igbeyawo wọn."

Molebi naa ni oun ọ le sọ boya ọjọ ọgbọ̀n oṣù kẹrin ni tàbí ọjọ kini oṣù karun ṣugbọn wọn rí aworan òkú wọn ní oju opo WhatsApp ni ọjọ kini oṣu karun. Eleyi ni o ṣẹlẹ lẹyin ti awon agbebọn naa pe wọn lori ẹrọ ibanisọrọ Private Matthew lati lọ wo.
"Wọn pa molebi Linus ni ọjọ to sele, olori awọn agbebon ni ki wọn yin wọn ní ìbọn nítorí wọn jẹ Hausa. Wọn pa a niwaju ọmọ Gloria ati iya rẹ." Molebi kan sọ fun BBC
Agbẹnuso Ile ise ologun, Onyema Nwachukwu fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ti Aare Muhammadu Buhari wa ti na ika abuku si awọn ọmọ ajijagbara ''The Indigenous people of Biafra' (IPOB), pe awọn ni wọn sẹku pa awọn oloogbe naa.
Ajọ aja fun ajijagbara IPOB si tini awọn ko mo nipa iṣẹlẹ naa.















