Sterling Bank Easter Message: Ẹgbẹ́ CAN foríjin ilé ìfowópamọ́ Sterling àti adarí rẹ̀ Abubakar Suleiman

Oríṣun àwòrán, Youtube
Àwọn adarí ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kírísítì tí ilẹ̀ Nàìjíríà, CAN, ní àwọn ti foríjin ilé ìfowópamọ́ Sterling àti sgá àgbà ilé ìfowópamọ́ náà, Abubakar Suleiman lórí ìkéde ìkíni kú ọdún ayẹyẹ ọdún àjíǹde tí ilé ìfowópamọ́ náà ṣe.
Nínú ìkéde náà, ilé ìfowópamọ́ Sterling fi bí Jésù ṣe jíǹde wé búrẹ́dì Agege.
CAN ní ilé ifowópamọ́ náà ti kọ̀wé ráńṣẹ́ èyí tí Abubakar Suleiman tọwọ́bọ̀ fún ara rẹ̀ sí àwọn lọ́jọ́ kejìlélógún, oṣù kẹrin, ọdún 2022 láti fi tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn.
- Irọ́ ni pé Bola Tinubu fẹ́ kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Agbẹnusọ Aṣíwájú
- Èsì ìdánwò UTME abala àkọ́kọ́ yóò jáde lọ́sẹ̀ yìí- Àjọ JAMB
- Ẹbí kan pàdánù ọmọ mẹsan-án nínú èèyàn 435 tí omiyalé pa
- Ẹkún tún sọ ní Zamfara, àwọn agbébọn pa èèyàn 48
- Bí Jibrin ṣe kúrò ní ẹgbẹ̀ òṣèlú APC kò níi ṣe pẹ̀lú Bola Tinubu- Agbẹnusọ ìpolongo
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí akọ̀wé àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ CAN, Joseph Daramola fi síta ṣe sọ, ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló dìde tí wọ́n sì ń bẹ CAN láti lo ẹ̀mí ìdáríjì gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe fi kọ́ wọn.
Daramola ní fífi orí jin ilé ìfowópamọ́ Sterling jẹ́ títẹ̀lá ìlànà àti ìgbésẹ̀ tí Jesu là kalẹ̀ fún wọn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe foríji àwọn tó kàn-án mọ́ àgbélèbú.
Bákan náà ló rọ gbogbo àwọn Kírísítẹ̀nì káàkiri Nàìjíríà láti pawọ́pọ̀ jọ foríji ilé ìfowópamọ́ náà àti àwọn aláṣẹ ibẹ̀
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní kí gbogbo àwọn tó ti ń gbèrò láti gbé akoto ìfowópamọ́ wọn kúrò ní báńkì náà nítorí ọ̀rọ̀ náà láti jọ̀ọ́ jàre má ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, dípò bẹ́ẹ̀ kí wọ́n túnbọ̀ máa tẹ̀síwájú láti máa báwọn dòwòpọ̀.
Àtẹ̀jáde ọ̀hún fi kun pé kí àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá pàápàá àwọn ilé ìfowópamọ́ láti máa yiri gbogbo ohun tí wọ́n yóò bá gbé jáde wò dáadaa.
- Kí nìdí táwọn iléeṣẹ́ bàlúù ní Nàìjíríà ṣe fẹ́ wọ́gilé ìrìnnà òfúrufú ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Ajé?
- Wo ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní "ọ̀nà ikú" tí àwọn ènìyàn ṣì ń ṣe ìrìnàjò lórí rẹ̀ síbẹ̀
- Mo dúpẹ́ ó! Mo bẹ́ orí fún gbogbo àgbẹ̀ àti olùfọkànsìn tó ń dáwó fọ́ọ̀mù Ààrẹ fún mi àmọ́ ẹ jẹ́ n lo óògùn ara mi - Emefiele
- Ẹ gba ìpínlẹ̀ Eko kúrò lọ́wọ́ àwọn àjòjì - Atiku sí Bode George
- Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn tó gbalẹ̀ kan l'Ekiti, a ti f'òfin bọ ọ̀rọ̀ Pasito Ade Abraham - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ekiti
- Ṣé ó ṣeéṣe kí ẹgbẹ́ ASUU fi òpín sí ìyànṣẹ́lódì rẹ̀ lọ́jọ́ Aje?
Àti pé kí wọ́n jìnà sí gbogbo ọ̀rọ̀ tàbí ìkéde tó le fa ìjà ẹ̀sìn tàbí ẹlẹ́yàmẹ̀yà.
Daramola tún kí àwọn ọ̀dọ́ ọmọlẹ́yìn Kristi bí wọn kò ṣe ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ti ń pè fún tako ilé ìfowópamọ́ Sterling, tí wọ́n gbọ́ ìdarí àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ CAN.


















