ASUU stike: Ṣé ó ṣeéṣe kí ẹgbẹ́ ASUU fi òpín sí ìyànṣẹ́lódì rẹ̀ lọ́jọ́ Aje?

Awọn adari ẹgbẹ ASUU nibi ipade

Minisita fun eto ẹkọ ni Naijiria, Mallam Adamu Adamu, ti bẹ awọn olukọ fasiti ijọba apapọ, lati pada si ẹnu iṣẹ wọn.

Ẹbẹ yii waye lẹyin ti ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ASUU, ti wa ni iyanṣẹlodi ọsẹ mẹjọ, ti wọn fi kun eyi ti wọn kọkọ̀ bẹrẹ.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, si ni ọsẹ mẹjọ naa yoo apri.

Ṣugbọn, ko ti i daju boya awọn olukọ naa yoo pada si ẹnu iṣẹ.

Akọwe agba fun ileeṣẹ eto ẹkọ, Andrew David Adejo, lo gba ẹnu Mallam Adamu sọ ọrọ naa ni Ọjọbọ.

Oun lo ṣoju minisita nibi ipade ti minisita fun ọrọ oṣiṣẹ, Chris Ngige, pe lati yanju wahala iyanṣẹlodi naa.

Ọgbẹni Adejo ni ni ki awọn oṣiṣẹ naa dari jin ileeṣẹ eto ẹkọ.

O ni o ṣe koko ki wọn o yanju ọrọ iyanṣẹlodi naa, nitori wahala to ti n fa ni ilu.

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn akẹkọọ fasiti Ibadan (UI) ati Benin (Uniben) ṣe iwọde, lati fi ẹhonu wọn han si iyanṣẹlodi awọn olukọ wọn.

Ṣe o ṣeeṣe ki iyanṣẹlodi ASUU pari lọjọ Aje?

Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2022, ni ASUU bẹrẹ iyanṣẹlodi, ti wọn si tun kede afikun ọsẹ mẹjọ lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta.

ASUU bẹrẹ iyanṣẹlodi naa lati mu ki ijọba fun wọn ni igbe aye idẹrun, fifi owo gidi gbọ bukaata eto ẹkọ, ati ṣiṣe amulo ilana owo oṣu ti wọn ṣe funra wọn, UTAS, dipo ti ijọba, IPPIS.

Awijare ijọba, lati ẹnu minisita ọrọ osiṣẹ, Chris Ngige, ni pe oju opo ayelujara ti ASUU ṣe funra rẹ fun sisan owo oṣu wọn, ko koju osuwọn to,.

O ni ayẹwo ti awọn sẹ fihan pe oju opo naa le pese anfaani fun awọn to ba fẹ ṣe jibiti ati awọn ole ori ayelujara.

Bakan naa ni wọn fẹ imuṣẹ adehun ti ijọba ṣe fun wọn ni ọdun 2009.

Ṣaaaju ni minisita keji fun eto ẹkọ, Emeka Nwajiuba, sọ pe kii ṣe ẹgbẹ ASUU, ni yoo sọ ilana ti ijọba apapọ yoo ma a gba san owo oṣu fun wọn.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀gá ni ooru Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ orílẹ̀èdè ti mo ti wálé; Bí mo ṣe parí iṣẹ́ 'AC' tó ń ló iná òòrùn rèé'

Titi di asiko yii, ko ti i si apẹẹrẹ pe awọn olukọ naa yoo pada si ile ẹkọ ni ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ti ọsẹ mẹjọ naa yoo pari.

Amọ o, minisita fun ọrọ oṣiṣẹ, Chris Ngige, sọ pe ijọba yoo bẹrẹ ijiroro pada pẹlu ASUU lọsẹ to n bọ.

Iye igba ti ASUU ti yanṣẹlodi laarin 2009 si 2022

2020 - Oṣu mẹsan-an

2018 - oṣu mẹta

2017 - Ọjọ mẹrindinlogoji

2014 - iyanṣẹlodi ọlọsẹ kan

2013 - osu mẹfa, nitori ibeere fun afikun ọjọ ori ti awọn ọjọgbọn yoo ma fẹhinti, ati afikun si owo ti ijọba n na sori eto ẹkọ

2011 - iyanṣẹlodi ọlọjọ mọkandinlọgọta

2010 - iyanṣẹlodi oṣu marun-un

2009 - iyanṣẹlodi oṣu mẹrin