Sleeping with Dog: Dókítà ní bíbá ẹranko lòpọ̀ ń fa àìsàn àìmọ̀dí tó pọ̀ yanturu; lára rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita ni ko ṣeeṣe ki eniyan to n ba aja tabi ẹsin tabi ẹranko miran lopọ pẹ ni aye labẹ bo ti wu ko ri.
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo ṣi n fi aidunnu wọn han lori fidio to gba oju ẹrọ ayelujara kan nibi ti awọn obinrin kan ti n ba aja lopọ nitori owo.
Awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ayelujara koju oro si iru ihuwasi yii ti wọn si ni ko bojumu rara.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria ni awọn n wa awọn obinrin naa nitori ihuwasi wọn lodi si ofin Naijiria, eleyii to si mu ijiya ẹwọn ọdun mẹrinla dani fun ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ to n ba aja lọpọ.
Kini imọ Sayẹnsi sọ nipa biba ẹranko lopọ?
Orukọ ti awọn onimọ nipa Sayẹnsi pe biba ẹranko lopọ ni awọn oloyinbo n pe ni 'bestiality'.
Eleyii tunmọ si ibalopọ laarin eniyan ati nkan ti kii ṣe eniyan.
Eleyii si jẹ ọkan lara ọna ibalopọ ti awọn eniyan ko mọ ọpọlọpọ nkan nipa rẹ.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ imọ eto ilera gbogboluse lorilẹede Naijiria gbe jade, ni iwadii nipa nkan to mu ki eniyan maa ni ibalopọ pẹlu ẹranko ati ipa to n ni lara wọn ṣọwọn.
Ninu iwadii ti wọn ṣe ni Virginia laarin ọdun 2003 si 2017 fihan pe eniyan mẹtalelọgbọn ninu awọn eniyan to le ni ẹgbẹrun un ni wọn n hu iwa ipa ati ibalopọ pẹlu awọn ẹranko.
Wọn ni o ṣeeṣe ko jẹ awọn eniyan ti wọn ti fi ipa balopọ ni kekere ni wọn wa n hu iwa ipa pẹlu ẹranko.
Kini ipalara to wa ninu biba ẹranko lopọ?
Awọn aisan to ṣeeṣe ko ṣuyọ ti eniyan ba ba ẹranko lopọ ni;
•Aisan Zoonotic ti o ma n wa lati ara ẹranko si eniyan, to si n fa ajakalẹ arun ati aisan aifojuri bii bacteria, fungi, virus ati parasite. Eleyii si le pa eniyan
•Aisan Leptospirosis to n wọ ara eniyan lati ara itọ ẹranko
•Echinococcosis
•Aisan Rabies to n pa awọn eniyan ni kiakia
•Aisan jẹjẹrẹ ori nkan ọmọ ọkunrin
•Aisan ọpọlọ
•Awọn aisan to le ṣuyọ lẹyin ti eniyan ba ṣe nkan ti ko ba ni lara mu.
Dokita Christopher Otabor to ba BBC Pidgin sọrọ ni Abuja ni lara awọn aisan naa kii ni iwosan.
O ni nkan to si ma n jẹ ki awọn eniyan ku ni kiakia nitori rẹ ni ojuti lati sọ nkan to n ṣe wọn.
Dokita ni biba aja lopọ n ṣẹlẹ daadaa amọ awọn eniyan ko sọrọ sita lori rẹ, nitori itiju atipe ẹrọ ayelujara lo ṣẹṣẹ n gbe jade bayii.
O ni awọn miran ma a wa pẹlu aisan ti ko gbogun ti awọn a si sa gbogbo ipa awọn, amọ ti wọn yoo pada ku.
Dokita naa fikun un pe ko ṣeeṣe ki eniyan to n ba aja tabi ẹsin tabi ẹranko miran lopọ pẹ ni aye labẹ botiwu ko ri.

















