Building Collapses In Lagos: Àlàyé lẹ́nu ará àdúgbò níbi ilé alájà mẹ́ta dàwó l'Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Gẹgẹ bi ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Eko ṣe ṣe afikun, eeyan mẹwaa lo ti jẹ Ọlọhun nipe nibi ile to dawo .
Atẹjade ti ajọ naa fi sita lalẹ ana ti wọn si kọ si isalẹ ọrọ wọn pe eyi ni iye eeyan to kẹhin to ha sabẹ ile naa ti awọn n reti.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Awọn ti wọn ri yọ laaye jẹ ọkunrin mejilelogun ati obinrin kan gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.
Awọn ti wọn ri yọ amọ to ti di oku jẹ ọkunrin mẹfa ati obinrin kan ti gbogbo eyi si kasẹ nilẹ ni nkan bii ago mẹrin kọja iṣẹju mẹẹdogun nirọlẹ ana.
Bi Ọlọrun ṣe ko awa ara fulaati mi ni akasọ kini ile naa yọ ree

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe Ibadan ni Ebute Meta, ipinlẹ Eko ti ile naa ti wo ba BBC Yoruba sọrọ:
"Ko sẹni ti ko mọ pe ile yii ti kẹ́ra, a si ṣepade pẹlu awọn onile pe ki wọn da owo wa pada fun wa".
Arakunrin naa ni nitoun, oun ti wa ile mii o ti ko jade kuro nibẹ nigba ti awọn onile kọ ti wọn ko da owo ti awọn beere fun pada.
Ẹlomiran da ẹbi iṣẹlẹ yii ru awọn abaniwale to jẹ wipe ere ori owo ile ti awọn fẹ gba ni wọn n le kiri ti wọn a si mu ẹni to n wa ile lọ ilekile ti wọn ba ri.
Ọmọ ọdún méje àti mẹ́sàn-án tó jẹ́ ọmọ ìyá kan wà nínú ilé tó dàwó

Oríṣun àwòrán, lasema
Ẹlomiran lara awọn to n gbe ninu ile alaja mẹta naa amọ ti ori ko oun ni tirẹ yọ to ribi sa jade pẹlu awọn mii naa sọrọ.
"Èmi, ọmọ mi, atawọn alabagbe mii la n gbe ni akasọ kini, nibẹ a si ni fulaati marun, emi ni mọlẹbi mẹta, arabinrin yii ni meji, ẹlomii ati ẹlomii naa ni meji meji amọ gbogbo wa ye e, a sa jade".

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Bakan naa ni awọn ile ti fulaati akasọ Keji naa ni awọn mọlbi to n gbe nibẹ.
O ni awọn n reti ọmọdebinrin kekere kan ti wọn ko tii foju kan ati ọmọ arakunrin kan.
Nigba ti akọroyin bi wọn pe ṣe lootọ ni wọn ti paṣẹ fun wọn ṣaaju pe ki wọn ko kuro ni ile naa, arakunrin naa ni ko ri bẹẹ.
"Wọn mu iwe akiyesi wa fun wa latọdọ awọn onile pe ki a ma sanwo kọja oṣu kẹfa ọdun yii fun "landlady" tori pe ẹmi gigun ile yii yoo pari ninu oṣu kẹfa a si ẹpade ninu oṣu Keji."
O ni wọn ṣalaye fun awọn pe onile yoo gbe akoso ile ọhun fun awn abanikọle ti ijọba ipinlẹ Eko lẹyin oṣu Kẹfa ọhun.
Iroyin to kọkọ jade laarọ kutu ni pe eeyan meji ni wọn ri to ku ninu ile alaja mẹta kan to dawo lojule kẹrinlelogun, ni adugbo Ibadan, to wa ni Ebute-Meta, niluu Eko amọ o tun ti yipada bayii, o ti le sii.
Iroyin ni nnkan bii aagọ mẹwaa alẹ ọjọ Aiku ni ile naa dawo.
Awọn eeyan adugbo ọhun sọ fun awọn akọroyin pe ọpọ awọn eeyan lo wa ninu ile ọ̀hún lasiko to dawo.
- Ìrọ̀rùn dé l'Edo- A óò bẹ̀rẹ̀ sí san 40,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù lóṣù yìí-Obaseki
- Dídi ọlọ́là nínú eré Tíátà kò jọ ọ́ fún àwa kan, ìdí rèé - Kunle Afod
- Omoyele Sowore gúnlẹ̀ sí Ondo láti lọ gba ìmọ̀ràn
- Alaafin Oyo tuntun yóò gorí ìtẹ́ láìpẹ́ - Makinde
- Owó ńlá ti fẹ́ ṣe mí léṣe ní London o! Ẹ wá wo bí mo ṣe ń jayé orí mi bíi skódà - Portable
- Òṣìṣẹ́ ìjọba pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn ọjọ díẹ̀ tó gba iṣẹ́
- Russia na ìka àlébù sí Ukraine,o ní àwọn ló n ṣekú pa aráàlú wọn ní Kherson
- À ń wá àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá, ẹ kàn sí wa tí ẹ bá mọ̀ wọ́n - ọlọ́pàá Naijiria
- Ṣé fífi omi gbóná jó ojú ara lẹ́yìn ìbímọ ní anfààní fún obìnrin?
Ninu atẹjade ti ọga agba ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu fi ṣọwọ si BBC, o ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa lawọn oṣiṣẹ oun tẹkọ leti lọ sibẹ.
LASEMA ṣawari awọn to ha sabẹ ile naa
Oke-Osanyintolu ni "Nigba ti a de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ile alaja mẹta kan to ni ọpọ yara lo dawo."

Oríṣun àwòrán, lasema
Iwadii wa fi jan pe iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bii aago mọkanla alẹ amọ a ko le sọ iye eeyan to ha sabẹ ile naa."
"A yọ ogun eeyan jade labẹ ile ọhun laaye, amọ awọn meji farapa yanyana, asi ti gbe wọ lọ sile iwosan LASUTH fun itọju to peye."
Eeyan meji ku, mẹtalelogun moribọ
Nigba to di nnkan bi aago meji kọja iṣẹju die ni orumọju ọjọ Aje ni LASEMA tun fi atẹjade mii ṣọwọ si BBC Yoruba lori ibi ti wọn ba isẹ de.
Inu atẹjade naa ni Oke-Osanyintolu ti sọ iye awọn ti wọn ti ri yọ labẹ ile naa atawọn to jade laye.
O ni "Ibi ti a ba iṣẹ de ree lori ile to dawo ni Ebute-Meta."
"A ri okunrin mejilelogun ati obinrin kan yọ laaye."
"Bẹẹ naa ni a ti ri oku okunrin kan ati oku obinrin kan gbe jade ni aago meji kọja iṣẹju mẹwaa."
Oke-Osanyintolu pari ọrọ rẹ pe awọn agbofinro, to fi mọ awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi bii LASBCA, NEMA ati Red Cross lo ti wa ni ikalẹ lati yọ awọn to ṣi wa labẹ ile naa.




















