Kunle Afod: Idí nìyìí tí àwọ́n òṣèré ayé òde òní fi ṣe orííre ju ti àwọn ìsáájú lọ

Afod

Oríṣun àwòrán, KunleAfod/Imstagram

Àkọlé àwòrán, Òṣèrébìnrin tí wọ́n bá fi ìbálòpọ̀ lọ̀ 'torí ìṣẹ́, kó bọ́ síta láti sọ̀rọ̀ - Kunle Afod

"Ìgbà kò sàn wá nínú iṣẹ́ òṣèré bíi ti àwọn ayé òde òní".

Gbajugbaja oṣere, Kunle Afod ti sọ idi ti awọn oṣere aye ode oni fi lọla ju ti awọn asaaju lọ.

Afod sọ eyi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori idagbasoke ni agbo osere.

Ninu idahun rẹ si ibeere rẹ pe ṣe o ro pe iṣẹ oṣere le sọ eniyan di ọlọla, Afod ni fun awọn ẹlẹgbẹ oun, ko si oun to jọ bẹẹ, amọ fun awọn oṣere aye ode oni, ọpọlọpọ wọn ni onile ati ọlọna.

''Awọn baba wa ninu oṣere bi Baba Suwe ati Baba Sala ko ni atilẹyin awọn ileeṣẹ ijọba nla nla bii awọn oṣere aye ode oni bi Odunlade Adekola ti ọpọlọpọ eniyan fẹ jẹ ko ṣoju awọn lori ẹrọ ayelujara.''

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

''Pupọ ninu wọn lo ni oju opo YouTube ti owo ti n wọle fun wọn, nitori naa ni a ṣe gbe igbesẹ lati da ti wọn, ti a si ti gbiyanju lati ni oju opo tiwa naa ki owo le ma a wọle.''

Bakan naa lo ni o ko nilo lati jẹ ọrẹ igun kan lati ṣe oriire ni Nollywood, amọ ti o ba dọrẹ pẹlu awọn eniyan to ga, o di dandan ki iwo naa ga.

Kunle Afod fikun un pe ọrọ naa dabi eni to kọ is agbẹjọro to kọkọ sisẹ pẹlu agbẹjọro to jẹ ilumọọka ki o to lọ da tiẹ silẹ.

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...