Ẹ pa APC àti PDP tì kẹ́ẹ fa ọgbọ́n orí tuntun mọ́ra - Sowore tún ti ń fọhùn lórí òṣèlú

Aworan Sowore

Oríṣun àwòrán, omoyele

Oludije si ipo Aarẹ labẹ Asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress ti kesi awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ma ṣe gba ẹgbẹ oṣelu to wa lori oye, All Progrssives Congress ati ẹgbẹ

alatako, Peoples Democratic Party gbọ ninu idibo ọdun 2023.

Gbajugbaja ajafẹtọ yi ni eeyan ti orilẹede nilo bayii ni ẹni to ni imọ ati ọgbọn amulo tuntun to si koju osuwọn lati gba ijọba lọwọ aarẹ Muhammadu Buhari.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni papakọ ofurufu ilu Akure ni kete to balẹ si ipinlẹ Ondo lo tẹnu mọ ọ pe awọn to n ṣejọba lọwọ ti kuna lati ṣe daadaa pẹlu pẹlu gbogbo ileri ti wọn ti ṣe sẹyin.

O fi kun un pe iya ti jẹ awọn ọmọ Naijiria labẹ iṣejọba PDP ati APC to ni wọn ti wọn ti n mu ifasẹyin ba orilẹede lati ọdun mẹrindinlogun sẹyin.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọmọ Naijiria paapaa julọ awọn ọdọ nilo lati pe awọn to n wa agbara oṣelu ṣaaju idibo ọdun to n bọ nija.

"Igba yii ni asiko to lati gbena woju awọn to wa ni ijọba ki a si gbe awọn to ni imọ tuntun wọle ti wọn lee yi itan orilẹede Naijiria pada.

Ati APC o, ati PDP o, wọn o tii ni oludije wọn o si ni layelaye ni oludije ti yoo jẹ itẹwọgba loju awọn ọmọ Naijiria. Opin ti de fun ẹgbẹ oṣelu mejeeji".

Sowore ni asiko lati ṣe fun awọn eeyan ti de bayii ati pe asiko to yẹ ki orilẹede ṣiṣẹ fun awọn araalu ti de bayii.

"Awọn ẹgbẹ oṣelu mii tilẹ ti n lọ si oko igbagbe a o si ran wọn lọwọ lati ti wọn sinu ile ilẹ itan lai pẹ lai jina".

Sowore ni fun awọn ara ipinlẹ Ondo ati awọn ti ko tii gbọ, "emi Omoyele Sowore ni yoo jẹ aarẹ Naijiria to n bọ".

Aworan Sowore

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore

Sowore ni inu oun dun bi awọn alatilẹyin rẹ atawọn ara ilu Kiribo ni agbegbe Ẹsẹ Odo ipinlẹ Ondo ṣe tu yaaya lade wa tori ti oun.

Lori ẹwọn ti ijọba Naijiria ti ju Sowore si ri

Sowore ṣapejuwe bi ijọba Naijiria ṣe ju u sẹwọn lẹyin ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS fi panpẹ ofin mu u gẹgẹ bii "fifi akoko ṣofo".

O fi kun un pe oun ti ni agbara ati igboya sii bayii ti wọn ti tu u silẹ lati lee rin kaakiri orilẹede to si ni oun yoo tẹsiwaju lati maa sọrọ lodi si irufin nilu.

"Ifakoko ṣofo ni nitori ko si ẹni to lee doju ija kọ itan. Ko si ile ẹjọ to lee mu aridaju kan gboogi fi ran eeyan kan lọ si ẹwọn bẹẹ si ni orilẹede yii nilo idajọ ododo".

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...

Sowore ni pẹlu gbogbo bi ijọba ṣe n ba oun ja ti wọn n fi ọlọpaa gbe oun amọ lẹyin ọdun mẹta o ni wọn fi aridaju han pe oun ko jẹbi.

"Gbogbo awọn to gbe mi lọ si Abuja lati fi mi si ahamọ DSS l ti ri itiju gba bayi bẹẹ si ni wọn yoo to gbe agbara silẹ".

O fi kun un wipe awọn ọdọ ti wọn ti wọn n ba ja naa ti ni igboya sii bayii.