Alaafin: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ní Alaafin tuntun yóù gorí ìtẹ́ láìpẹ́

Oríṣun àwòrán, Vanguard News
Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe oun yo yan Alaafin Oyo tuntun laipẹ, ki awọn eeyan ilu naa lọ ṣe suru.
Gomina ipinlẹ ọhun, Seyin Makinde lo sọ bẹẹ nibi adura ọjọ kẹjọ, fidau, eyii to waye ni iranti Ọba Lamidi Adeyemi Alaafin to papoda.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii ni Alaafin dakẹ nile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun ti fasiti Afe Babalola, to wa niluu Ado-Ekiti.
- Ṣé fífi omi gbóná jó ojú ara lẹ́yìn ìbímọ ní anfààní fún obìnrin?
- Ìjọba gbé ilé ìtura tì pa lẹ́yìn tí wọ́n gé ẹ̀yà ara obìnrin kan lọ níbẹ̀
- Owó ńlá ti fẹ́ ṣe mí léṣe ní London o! Ẹ wá wo bí mo ṣe ń jayé orí mi bíi skódà - Portable
- Ǹkan tí èmi àti Alaafin jọ ṣe sílẹ́ lórí àṣà Yorùbá kìí ṣe kèrémí - Òyìnbó òṣìṣẹ́
- Sultan kéde ọjọ́ Ajé gẹ̀gẹ́ bíi ọjọ́ ọdún ìtúnu àwẹ̀ ní Naijiria
- 'Mo bá ajá ní ìbálòpọ̀ nítorí ₦1.4m', ka ǹkan tí òfin Nàìjíríà ṣọ nípa ìwà yìí
- Wòlíì Olubọla ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó jí ọkọ̀ ọmọ ijọ̀ lọ ní Abeokuta
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó pa ọ̀rẹ́ rẹ̀ nítorí gbèsè tó jẹ ẹ́
- Afurasí Oníṣòwò ǹkan ìjà olóró méje kó sí pańpẹ́ Ọlọ́pàá ní Jos àti Taraba
- Wo ohun mánigbàgbé mẹ́fà nípa Gbenga Adeboye lẹ́yìn ọdún 19 tó kú
Makinde, ti oloye Bayo Lawal, to jẹ kọmiṣọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ṣoju fun sọ pe, ijọba ipinlẹ Oyo mọ pe awọn eeyan ilu ọhun ti n reti lati ni Alaafin tuntun.
O ni "Awọn eeyan ti n reti lati ni Ọba tuntun amọ a ni lati tẹle awọn ilana to yẹ."
"A ṣeleri lati maṣe ṣe magomago kankan pẹlu yiyan Alaafin tuntun, amọ ko ni pẹ, ko si ni jina."
Ṣaaju nibi eto adura naa ni Imaamu Masud Ajokidero ati alufaa Eyitayo Sulola ti kọkọ sọ pe ki awọn eeyan ilu Oyo ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ bo ṣe wa tẹlẹ lasiko ti Alaafi Adeyemi wa loke eepẹ.
Awọn ojiṣẹ Ọlọrun mejeji ke si awọn afọbajẹ, iyẹn Oyo Mesi, lati tẹle ilana to yẹ lati yan Alaafin tuntun nigba ti asiko ba to, ki wọn ma si ṣe wo ti awọn ti owo wa lọwọ wọn lati fi wọn sori itẹ.
Nigba to n sọrọ, Iyalode ilẹ Yoruba, oloye Alaba Lawson juwe Alaafin to waja gẹgẹ bii baba fun gbogbo ọmọ kaarọ oojire, o si jẹ ẹni to maa n ja fun ẹtọ awọn eeyan rẹ.
O ni "Alaafin maa n tẹti si ẹbẹ awọn ọmọ Yoruba ni gbogbo igba, o si jẹ ẹni to mọ itan Yoruba daadaa."
"Adura mi ni pe ki Alaafin to n bọ maṣẹ ya kuro ninu awọn ilana to fi lelẹ."
















