KNUST student murder: 100 Cedis owó ilẹ̀ Ghana tó jẹ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló mu gbẹ̀mí rẹ̀

Aworan afihan afurasi

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Ghana ni ọwọ ti tẹ ọkunrin kan to pa ọrẹ rẹ nitori Iye owo ọgọrun Cedis to jẹ ologbe ti ko fẹ san pada.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni kete ti wọn de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni wọn ri pe ọrun oloogbe naa wu, ti ẹjẹ si n jade lati imu rẹ.

Bakan naa ni wọn ri igi nla to ṣeese ki o fi pa oloogbe naa ni bii ogun mita si ibi ti ara oloogbe naa wa.

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...

Bi ipaniyan naa ṣe waye

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ni ilẹ Ghana ṣe ṣọ, oloogbe naa Nana Gyamfi lo ṣabẹwo si afurasi Emmanuel Boateng ni ile rẹ ni agbegbe Esaso-Kwabiafo.

Awọn mejeeji ni wọn jọ kuro ni ile amọ oloogbe naa ko pada si ile mọ.Ẹyin igba naa ni wọn ri oku rẹ ni irọlẹ Ọjọ Ẹti.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni afurasi Emmanuel Boateng jẹwọ pe oun loun tan ọrẹ rẹ lọ si inu igbo ki oun le ṣeku pa.

Idi ti afurasi ṣe pa ọrẹ rẹ

Ileeṣẹ ọlọpaa ni afurasi naa ni oun pa ọrẹ oun nitori oun ko fẹ san ọgọrun Cedis ti oun jẹ.

Agbẹnusọ Ọlọpaa, Godwin Ahianyo ni ẹnu ẹkọṣẹ aranṣọ ni afurasi naa wa ki iṣẹlẹ ọhun to waye, to si ji ẹrọ ilewọ rẹ, Iphone 11 Pro Max.

Ijọba ni o ṣeeṣe ko jẹ pe kii ṣe nitori owo nikan lo ṣe pa ọrẹ rẹ, ki nkan mi wa lẹyin rẹ.

Bakan naa ni baba oloogbe, Yaw Adugyamfi ni o da oun loju pe nitori foonu ọwọ rẹ ni wọn ṣe pa.

Tani ologbe to jẹ akẹkọọ fasiti KNUST?

Ologbe naa, Nana Gyamfi lo jẹ akẹkọọ ipele keji ni fasiti Ẹkọ imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ, Kwame Nkrumah University of Science and Technology (KNUST).

Ẹkọ imọ biological science ni Gyamfi ni ohun nkọ ki o to ku iku aitọjọ.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Awọn ara agbegbe Kumasi ni iyalẹnu ati ibanujẹ ni iku akẹkọọ naa jẹ fun wọn ni ilu ọun.

Nibayii, Boateng wa ni panpẹ ọlọpaa lọwọlọwọ, ti o si foju balẹ ẹjọ pẹlu ni Ọjọ Karundinlọgbọn, Oṣu Kẹrin, ọdun 2022.