Afurasí Oníṣòwò ǹkan ìjà olóró méje kó sí pańpẹ́ Ọlọ́pàá ní Jos àti Taraba

Awon afurasi

Oríṣun àwòrán, Others

Afurasí Oníṣòwò nkán ìjà olóró méje kò sí pampẹ́ ọlọ́pàá ní Jos,Taraba

Ikọ ọtẹlẹmuyẹ ileesẹ ọlọpaa ni ilu Jos ni ipinlẹ Plateau ti kede pe awọn ti ri ogbori onisowo nkan ija oloro mẹrin mu tawọn si ri nkan ija oloro gba lọwọ wọn.

Wọn fi ọrọ yi lede ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lati ọwọ agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa lapapọ Naijiria,Muyiwa Adejobi.

O sọ pe awọn ibọn AK47 mẹtadinlọgọta ati awọn ọta ibọn ti onka rẹ ko mọ niwọn lawọn ri gba ni Plateau ati awọn ipinlẹ miran.

Bawo ni ọrọ ṣe ṣẹlẹ?

Muyiwa darukọ awọn afurasi yi gẹgẹ bi " Hamza Zakari (aka Hamzo) ẹni ogun ọdun, Abubakar Muhammed (aka Fancy)ẹni ọdun mejilelogun, Umar Ibrahim ẹni ọdun marundinlọgbọn ati Muhammed

Abdulkarim (aka Dan-Asabe) ẹni ọidun mẹtadinlogoji ti gbogbo wọn n gbe ni ilu Jos.''

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

O tẹsiwaju pe ọwọ tẹ awọn afurasi yi lẹyin ti awọn gbọ nipa iwa aburu ti wọn hu ni Jos ati agbegbe rẹ.

Gẹgẹ bo se sọ,awọn afurasi yi t jẹwọ iwa buruku wọn nipda kikopa ninu tita ati ipese nkan ija oloro fawọn ọdaran to n da omi alaafia Jos ati agbegbe rẹ ru.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Kini afurasi sọ?

Ko mọ bẹẹ, Muyiwa ni awọn nkan ija oloro ti wọn n ta a tun maa fun awọn alaburu mi lanfaani lati dunkoko mọ araalu lawọn apa ibomiran lorileede Naijiria.

''awọn ikọ oluwadii wa n tọ pipin awọn ti wọn jijọ n sisẹ pọ,laipẹ ọwọ yoo tẹ awọn naa''

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

Awọn wo ni agbofinro mu ni Taraba?

Bakan naa lo sọ pe awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa tun ribi mu awọn afurasi mẹta mii ni Taraba to se pe nkan ija oloro tita ni wọn yan laayo.

Ni ijọba ibilẹ Ibi ni ọwọ ti tẹ afurasi mẹta Bello Sani, Venab Puncat ati Yusuf Nahod.

''Lẹyin ifọrọwanilẹnuwo gbogbo awọn afurasi yi lo jẹwọ pe awọn ra ibọn AK47 ati ibọn SMG kan ni iye owo to to #900,000. A n gbiyanju lati ri awọn agbodegba wọn mu ki a si ri awọn nkan ija oloro gba lọwọ wọn''

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Ipinlẹ Taraba lẹnu ọjọ mẹta yi jẹ ibikan tawọn ọdaran ti n sọsẹ ti a si n gbọ iroyin ikọlu lorisirisi nibẹ.

Laipẹ lawọn kan se ikọlu pẹlu ado oloro si ile ọti kan to wa ni ijọba ibilẹ Ardo-Kola.

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Ninu ikọlu yi,ọpọ lo ku ti aimọye si farapa.

Yatọ si ikọlu iru eleyi t iki ọ agbesunmọmi ISWAP ti sọ pe awọn lawọn wa nidi rẹa, ikọlu a maa waye laarin awọn darandaran ati awọn agbẹ lagbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

Ọpọ ẹmi lo ti ba awọn irufẹ ikọlu yi lọ ti awọn araalu si ti kesi ijọba lati mura si ọrọ aalbo ati isọwọ bi awọn nkan ija oloro ti se n wa lọwọ araalu.

Ewẹ awọn ọlọpaa sọ pe awọn afurasi yi yoo foju ba ile ẹjọ ni kete tawọn ba ti pari iwadii.