Yul Edochie new wife: Iyabo Ojo sọ pe kò sí òṣèrékùnrin tí kìí yan àlè

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyobo Ojo

Gbajugbaja oṣerebinrin, Iyabo Ojo, ti sọ pe ko si oṣerekunrin ti kii ni ibalopọ pẹlu obinrin miran yatọ si iyawo wọn.

Iyabo to jẹ olukopa ninu eto ori ayelujara kan ti agbohunsafẹfẹ, Ifedayo Olarinde Daddy Freez ṣe lọjọbọ sọ pe ko si oṣerekunrin ti kii yan ale.

Ijiroro wọn ọhun waye lori awuyewuye to tẹle ikede gbajumọ osẹrekunrin, Yul Edochie, to kede lọjọ Isẹgun pe oun ti fẹ obinrin miran to bimọ fun oun gẹgẹ bi iyawo keji.

Ikede ti Yul ṣe yii ti n fa awuyewuye lati ọjọ naa laarin awọn gbajumọ ati gbogbo ọmọ Naijiria.

Iyabo Ojo sọ pe oun ko ri oṣerekunrin kankan ri to jẹ olotitọ si iyawo rẹ.

"Ko si oṣerekunrin kankan to jẹ olotitọ si iyawo rẹ. Ẹka iṣẹ ti mo wa ni, o mo mọ daju pe awọn iyawo wọn kan n rọju ni."

"Kii ṣe nkan ti oju ko riri tabi to jẹ ajoji, pe ibalopọ lode igbeyawo wọpọ laarin awọn oṣerekunrin, botilẹ jẹ pe ọpọ n ṣe bi ẹni pe kii ṣẹlẹ."

Arabinrin Ojo ni o ṣoro fun ọkunrin to ba jẹ elere tiata lati jẹ olotitọ si iyawo wọn, nitori bi awọn obinrin ṣe ma n ṣù bo wọn.

"Obinrin to ba fẹ oṣerekunrin ni ọkọ, gbọdọ ni amumọra, nitori pe o ṣoro fun wọn lati jẹ olotitọ."

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Kilo de ti awuyewuye pọ bẹẹ lori igbeyawo Yul Edochie tuntun?

Awọn nkan to mu ki ariwo pọ lori iyawo keji ti Yul fẹ ko ṣẹ

Iyalẹnu ni ikede ti Yul Edochie ṣe pe oun ti ṣanwo ori iyawo keji.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Eyi ko ṣẹyin bo sẹ jẹ gbajugbaja oṣere, ti baba rẹ naa Pete Edochie ati iyarẹ, Rita Edochie ṣe jẹ agba oṣere.

Ọpọ igba lo si ti gboriyin fun iyawo rẹ akọkọ, Mary, pe o duro di oun nigba ti oun ko ti laluyọ.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Bakan naa ni igbeyawo wọn ti pe ọdun mẹtadinlogun, pẹlu ọmọ mẹrin.

Idi re e ti ọpọ fi gbagbọ pe iwa ọdalẹ ni yul wu plu bo ṣe fun akẹẹgbẹ rẹ obinrin, Judy Austin loyun, to si tun sanwo ori rẹ lẹyin to bimọ.

Yatọ si eyi, Ọgbẹni Yul ni erongba lati dupo aarẹ Naijiria lọdun 2023, ti ọpọ si ri iwa rẹ asiko yii gẹgẹ bi eyi ti ko yẹ fun ẹni to fẹ di aarẹ.