Abubakar Malami: Mínísítà fétò ìdájọ́, Abubakar Malami náà ti darapọ̀ mọ́ ìdíje láti dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi

Oríṣun àwòrán, other
Minisita feto idajọ to tun jẹ agbẹjọro agba fun ijọba Naijiria, Abubakar Malami ti darapọ mọ awọn ti yoo dije dupo gomina nipinlẹ̀ Kebbi.
Malami ni oun tẹwọ gba ipe awọn eeyan ipinlẹ̀ naa lati dije fun ipo ọhun.
Abẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ni Malami ti fẹ dije.
Ninu ọrọ to sọ nilu Birnin Kebbi lasiko ifọrọwerọ pẹlu awọn alẹnulọrọ lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ̀ Kebbi, Amofin Malami sọ pe, "Niwọn igba ti ẹ fẹ ki n dije dupo gomina ipinlẹ yii, mo gba ipe yin nitori pe ohun ti ẹ fẹ niyi."
O niọkan o jọkan awọn eeyan ipinlẹ naa ni wọn ti n kan si oun niwa lẹyin pe ki oun dije fun ipo gomina ipinlẹ̀ Kebbi lọdun 2023.
Ọpọlọpọ igba lawọn iroyin kan ti n ru jade pe minisita feto idajọ ni Naijiria naa n gbero lati di aarẹ tabi igbakeji pẹlu ipo gomina.
Jijade rẹ lati fifẹ han fun ipo gomina ti fopin si awọn iroyin wọnyii.








