Synagogue Fire Incident: Ilé ìjọsìn Synagogue ní àwọn ti pa iná náà

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ilé ìjọsìn Synagogue (SCOAN) ti fi ọ̀rọ̀ léde lórí ìjàmbá iná tó ṣẹlẹ̀ ní ilé ìjọsìn náà tó wà ní agbègbè Agodo, Egbe ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin ọdún 2022.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan tí ilé ìjọsìn náà fi léde lórí ẹ̀rọ ayélujára Facebook, ilé ìjọsìn náà kìí ṣe ibi ibojì òkú olùdásílẹ̀ ilé ìjọsìn náà, Wòlíì Temitope Balogun ni iná mú gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé ìròyìn ṣe ń gbe kiri.
Wọ́n ní yàrá ibi tí àwọn ń kó ẹrù gbogbo pamọ́ sí ni ìjàmbá iná náà ti wáyé lòdì sí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ tí àwọn ènìyàn ń gbé kiri.
- Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Morenikeji Lasisi, olórí ẹrú tó ti bá Aláàfin mẹ́ta ṣiṣẹ́
- Ìj̀à tó bẹ́ sílẹ̀ ní Sudan ti gbẹ̀mí ènìyàn 200 lára àwọn tó sá àsálà fún ẹ̀mí wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Janjaweed
- Ohun tó yẹ kó mọ nípa ìyípadà òfin tó dé ijinigbe ní Nàìjíríà rèé
- Iléẹjọ́ sún ìdájọ́ Abba Kyari síwájú, ìgbà wo ni wọ́n n gbée lọ jẹ́jọ́ Hushpuppi ní America ní ọ̀pọ̀ ń béèrè
- Ọwọ́ tẹ ọmọ ológun Nàìjíríà tó ń lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ISWAP, wo bí o ṣé gbà ẹ̀mí ará rẹ̀
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Ajé àti ọjọ́ Ìṣẹ́gun fún ìsinmi ọdún àti àyájọ́ ọjọ́ Òṣìṣẹ́
- Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló kú ikú àìtọ́jọ́ nítorí ẹnubodè tíjọba àpapọ̀ tì pa- Àwọn ènìyàn ìlú Idiroko tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀
Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn ọmọ ìjọ náà láti má bẹ̀rù tàbí fòyà lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé kò sí ènìyàn kankan tó farapa tàbí bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Wọ́n sọ síwájú wí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kò ì tíì mọ ohun tó fa ìjàmbá iná náà, àwọn ti ń ṣe ohun gbogbo tó yẹ láti fìdí ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá iná ọ̀hún múlẹ̀.
Wọ́n fi kun pé àwọn ti rí iná náà pátápátá nítorí bí ìjàmbá iná náà ṣe wáyé ni ẹ̀ka tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ilé ìjọsìn ọ̀hún ti jí gìrì sí ojúṣe wọn.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀?
Ní òwúrọ̀ ọjọ́rú ni ìròyìn gba orí ayélujára kan wí pé ìjàmbá iná ń wáyé ní ilé ìjọsìn Synagogue tó wà ní agbègbè Agodo ní Ikotun, ìpínlẹ̀ Eko.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ nǹkan bí ago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀.
- Indonesia fòfin de títa epo pupa rẹ̀ sílẹ̀ òkèèrè, wo ipa tí yóò ní lára Naijiria àti Africa lápapọ̀
- Ìgbẹ́jọ́ Ilànà Ọmọ oodua àti Náìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ ní Ekiti
- Mo ti 'ùnfollow' ẹ lórí 'social media'; Ọlọ́run a ṣe idajọ fún ẹyin méjèèjì- Iyawo Yul-Edochie
- 'Ẹran ẹtu ni mo yìnbọn sí, àmọ́ òkú ìmáàmù ni mo bá nígbà tí mo fẹ́ gbe e'
- Kìí ṣe nǹkan abàmì bí Alaafin, Soun àti Olubadan ṣe papòdà lèralèra - Elebuibon
- Látàri ìjà Russia àti Ukraine, Bí a ṣe fẹ́ dènà ìyàn oúnjẹ ní Naijiria rè é- Buhari
- Wo bí ètò Orò Ìje Oba Lamidi Adeyemi to wàjà ṣe lọ ní Oyo
- Ọlọ́pàá Eko kéde orúkọ ọlọ́pàá tó ṣíná ìbọn bolẹ̀ nílé ọtí, téèyàn méjì fi kú
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ṣe ojú mi kòró kan sọ fún àwọn akọ̀ròyìn, ó ní àwọn kò le sọ bóyá ènìyàn farapa tàbí bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀gá àgbà ajọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, Ibrahim Farinloye fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ àti wí pé àwọn ti pa iná náà.
Bákan náà ni òlórí ẹ̀ka àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná àti ìdóòlà ìpínlẹ̀ Eko, Margaret Adeseye ní ìjàmbá iná ọ̀hún ṣe àkóbá fún òrùlé ibi tí wọ́n sì olùdásílẹ̀ ilé ìjọsìn náà.



















