Ọlọ́pàá Eko kéde orúkọ ọlọ́pàá tó ṣíná ìbọn bolẹ̀ nílé ọtí, téèyàn méjì fi kú níbi àṣeyẹ ọjọ́ ìbí 'Obama'

Oríṣun àwòrán, other
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede orukọ ọlọpaa to ṣina ibọn bolẹ nile ọti kan to wa ni Egbeda, niluu Eko, nibi ti ẹ mi eeyan meji ti sọnu, ti awọn mii si farapa.
Iṣẹlẹ na waye lasiko ti awọn eeyan ọhun n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi nile ọti naa.
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fi lede, lo ti kede orukọ ọlọpaa naa gẹgẹ bii Isipẹtọ Mohammed Hussini.
- Mọ̀ nípa Baṣọ̀run ìlú Oyo, Oloye Yusuf Akinade Ayoola tí yóò delé de Aláàfin tuntun
- Wọ́n ti ṣe ìsìnkú àpapọ̀ fún èèyàn 50 lára àwọn tó jóná níbúdò ìfọpo tó gbiná ní Imo
- Ìyàwó Olúbàdàn, Olorì Joyce ti darapọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Islam
- Èèyàn bí méjì kú, ọ̀pọ̀ farapa lásìkò tí àwọn afurasí ọmọ Auxiliary àti Isota kọlu ara wọn ní Ibadan
O ni "Lọjọ Aiku, ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii, ni nkan bii aago mẹsan an alẹ iṣẹlẹ naa waye nile ọtin La Silva Bar, ni Egbeda, eyii to yọri si iku eeyan meji, ti awọn mii si farapa."
"Nigba ti iwadii n lọwọ ni a ṣawari pe ọlọpaa kan ti ko si lẹnu iṣe, Inspr Mohammed Hussini, lo yin ibọn naa, ọrẹ si ni oun ati ọlọjọ ibi funra rẹ."
Hundeyin sọ siwaju si pe ọlọjọ ibi ọhun ko si nile ijo naa lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, ati pe kii ṣe pe ọlọpaa naa lọ ṣiṣẹ nibẹ ni.
O ni awọn ti bẹrẹ si n wa ọlọjọ ibi naa, Ifeanyi, ti ọpọ awọn ọrẹ rẹ mọ si Obama, awọn si n reti ki afurasi naa wa fi ara han ni agọ awọn.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Abiodun Alabi ti ṣeleri pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ aburu naa ni yoo foju bale ẹjọ.
Alẹ ọjọ Aiku ni fidio iṣẹlẹ ọhun si n tan kaakiri, eyii to ṣafihan oku okunrin kan nilẹ ninu agbara ẹjẹ, nigba ti ibọn ti ba omiran lẹsẹ jẹ.













