Olubadan wife Islam: Orukọ̀ olorì tuntun ti di Khadijah Moshood Lekan Balogun

Olori Joyce aya Olubadan

Oríṣun àwòrán, @Olubadan

Àkọlé àwòrán, Olori Joyce aya Olubadan Balogun

Ìyàwó Olúbàdàn, Olorì Joyce ti darapọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Islam

Olori Joyce Anene to jẹ iyawo Olubadan ti ilu Ibadan, Ọba Moshood Balogun ti darapọ mọ ẹsin Islam.

Ileeṣẹ iroyin ti ijọba ipinlẹ Ọyọ, Broadcasting Corporation of Oyo state (BCOS) lo gbe iroyin naa jade.

Gẹgẹ bi wọn ṣe ṣọ, Imamu agba ti ilu Ibadan, Sheikh Sheikh Abdul Ganiyy Abubakry Agbotomokekere I lo kede rẹ fun gbogbo eniyan.

Iroyin ọhun ni olori naa gba ẹsin ti ọkọ rẹ Olubadan n ṣe lo ṣe darapọ mọ ilana ẹsin musumi ni asiko ẹkọ Ramadan ti wọn n ṣe ni Yidi Agodi, ni Ibadan.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Olori ni aafin wa n jẹ orukọ tuntun gẹgẹ bi Ilana Musulumi ti wọn si pe e ni Olori Khadijah Mahood Lekan Balogun, to si ka kalimatul-shahadah ni asiko ayẹyẹ naa.

Oṣu to kọja ni wọn ya Ọba Lekan Balogun gẹgẹ bi Olubadan ti ilu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyọ.

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Lara awọn to pejọ si ibi ayẹyẹ naa ni igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo, Igbakeji aarẹ tẹlẹri ni Naijiria, Atiku Abubakar, Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi, gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ati gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó