Wo bí Lukman ti ẹbí gbé òkú ìkókó fún pé kó bá wọn sin ín ṣe gbẹ̀yìn ẹ̀bi lọ bẹ́ orí òkú ọmọ náà

Lukman

Boroboro ni baale ile kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Kushimọ Lukmọn n ka laarọ oni, ọjọ Iṣẹgun, lẹyin to ge ori oku ọmọdekunrin kan ni itẹku, pẹlu erongba lati ta a fun etutu owo.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC YORUBA lọwọ laipẹ yii, wọn ni awọn obi ọmọ naa lo gbe oku rẹ wa fun Lukmọn, ẹni to n ṣiṣẹ alaabo ni itẹku MABOD to wa ladugbo Oke-Yidi si Abule-Ọlọni niluu Abẹokuta lọjọ Aje, ni ana.

Wọn ni iwaju awọn obi ọmọ yii ni Lukmọn ti sin in ni nnkan bi agogo meje irọlẹ ọjọ Aje, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu ti a wa yii.

Lukman

Nnkan bi agogo mẹfa aarọ oni la gbọ pe Lukmọn lọ hu oku ọmọ naa jade, to si ge ori rẹ lati lọ ta a fun ẹni ti wọn lo bẹẹ lọwẹ ori oku.

BBC YORUBA ri i gbọ pe nibi ti Lukmọn ti n wa iyẹpẹ bo ẹya ara oku ọmọ naa to ku lawọn oṣiṣẹ eto aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps ti kofiri rẹ, ti wọn si lọ ba a nibẹ.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Wọn ni ṣe lo ba awọn oṣiṣẹ So-Safe Corps ọhun wọya ija nigba ti aṣiri rẹ tu si wọn lọwọ. Diẹ lo ku ko na papa bora, ṣugbọn ti wọn ko jẹ ko raaye salọ.

Latibẹ la gbọ pe wọn ti gbe e lọ si ọfiisi wọn to wa ni Oke-Ilewo niluu Abẹokuta lati fi oju rẹ han fun ọga wọn.

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Bawo ni ọmọ naa ṣe ku.

A gbọ pe aisan kidinrin lo n ba ọmọ naa ja, ko to di pe awọn obi rẹ gbe e lati ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ wa si ọsibitu Federal Medical Center to wa ni Idi-Aba, Abẹokuta fun itọju.

Ko din ni oṣu kan gbako ti wọn ni ọmọ naa lo ni ọsibitu FMC yii, to si jẹ pe ọjọ Aje, Mọnde ana lo pada ku.

Lati ma maa gbe oku rẹ kaakiri lo jẹ ki wọn gbe e lọ si itẹku MABOD yii lati sin in sibẹ.

Bi wọn ṣe de'bẹ ni wọn ti ri Lukmọn to n ṣiṣẹ ọlọdẹ nibẹ, ẹni to ṣeleri lati ba won sin oku ọmọ naa lẹyin ti idunadura wọ laaarin wọn.

Nnkan bi agogo meje irọlẹ la gbọ pe Lukmọn sinku ọmọ ọhun ko to di pe awọn oni rẹ gba ilu Ibadan ti wọn ti wa lọ.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Agbẹnusọ ileeṣẹ So-Safe Corps sọrọ

Ọgbẹni Mọruf Yusuf nigba to n ba BBC YORUBA sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ fun ọga awọn, Sọji Ganzallo nigba to gbọ, bo tilẹ jẹ pe o.gbe oriyin fun awọn ọmọṣẹ rẹ to rọwọ to Lukmọn.

Yusuf wa jẹ ko di mimọ pe Lukmọn jẹwọ fun wọn pe Oloye kan ti wọn n pe ni Ifalonishe, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Lanroye lo ran an oun niṣẹ naa, lẹyin adehun ẹgbẹrun lọna aadọta naira ti wọn jọ ṣe.

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

Yusuf sọ pe ọga awọn ti paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ wọn tẹsiwaju iwadii lati ri awọn to ran Lukmọn, ẹni to n gbe ni ojule kẹsan, adugbo Abule-Ọlọni, Oke-Yidi, Abẹokuta, iyẹn nitosi itẹku naa mu, ati pe ki wọn lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

O ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ni wọn lọ fa Lukmọn le lọwọ fun iwadii siwaju si i.

Lati fi idi iroyin naa mulẹ, BBC YORUBA ba agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ, ṣugbọn to sọ pe oun ko ti i gbọ si iṣẹlẹ naa, ati pe oun yoo ṣe iwadii, ti oun yoo si jẹ ka mọ abọ iwadii oun.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú