A Week in Retrospect: Àwọn òṣìṣẹ́ ológun kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú tó já ní ìpínlẹ̀ Kaduna

Àwọn ológun pa ikọ̀ ọmọ ogun Boko Haram ogun, dóòlà àwọn obìnrin tó wà ní ìgbèkùn
Oríkò àjọ ọmọ ogun ní Ndjamena, Chad, èyí tó kún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Niger ti kéde wí pé àwọn ọmọ ogún ṣọṣẹ́ ní ẹkùn Lake Chad.
Wọ́n ní àwọn ṣàwárí àwọn ibi tí àwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram ní agbègbè Tumbun Fulani àti Tumbun Rago tí wọ́n sì pa ogun ènìyàn pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú.
Agbẹnusọ àjọ náà, Muhammad Dole ní lẹ́yìn tí ọkọ̀ òfurufú ti ṣe iṣẹ́ ọwọ́ tirẹ̀ ni àwọn ya wọ inú igbó náà láti tú àwọn tó wà nínú igbó náà ká.
Dole fi kun wí pé àwọn pàdánù ọmọ ogun kan níbẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn rí bi tú àwọn obìnrin kan sílẹ̀ ní àhámọ́ àwọn Boko Haram.
- Ọ̀pọ̀ ènìyàn pàdánù ẹ̀mí wọn bí ilé ìfọpo ṣe bú gbàmù
- Bí ètò ìdìbò ṣe ń lọ ní orílẹ̀-èdè France nìyí
- Àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí tó ń pèsè àdó olóró fún IPOB
- “Àìníṣẹ́ lọ́wọ́ ló mú mi pokùnso”
- Ìdí tí Osinbajo fi ṣèbẹ̀wò sí Olubadan àti ohun tí wọ́n sọ rèé
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ṣí gbogbo ẹ̀ka ilé ẹ̀kọ́ Chrisland padà
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ló ti rọ̀ tí ilẹ̀ ti fà mu.
Ọ̀kan ò jọkan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ló ti ṣẹ̀ nínú ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí tí a ní kí a mú wá fún yin-ín.
Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kọkàndínlógún, ọdún 2022 ni ọkọ̀ òfurufú tó jẹ́ ti Iléeṣẹ́ ológun òfurufú ìyẹn Nigerian Air Force (NAF), já lulẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kaduna.
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
- Ta ni Yorùbá ń pè ní Abọ́bakú?
- Ààrẹ Buhari, Ooni Ile Ife, Obasanjo kẹ́dùn Alaafin Oyo tó wàjà
- Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
- Kéte ti Baba dákẹ́ ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ l'Áàfin - Ẹ wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Aafin Oyo
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà

Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọ gbì tó wáyé nínú ọ̀sẹ̀ tó kọjá
Iléeṣẹ́ ológun òfurufú nígbà tí wọ́n ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní àwọn òṣìṣẹ́ méjì tí orúkọ wọn ń jẹ́ Abubakar Muhammed Alkali àti Elijah Haruna Karatu ló wà nínú ọkọ̀ òfurufú náà tí àwọn méjéèjì sì pàdánù ẹ̀mí wọn.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ náà, Edward Gabkwet ní àwọn yóò ṣe ìwádìí láti fi mọ ohun tí ó fa ìjàmbá ọkọ̀ náà.
- Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamidi Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà
- 'Aláàfin ti rí ikú rẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tó wàjà, ó sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó tó kú'
- Òrumọ́jú ní ara Oba Lamidi Adeyemi wọ káà ilẹ̀ lọ ní Ìbarà gẹ́gẹ́ bí ìṣe ìran Yorùbá ṣe làá kalẹ̀
- Nínú àwòràn, wo ìgbà ayé Aláafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta tó lọ bá àwọn Baba Ńlá rẹ̀
- Àṣírí ńlá tó ń bẹ láàrín Alaafin àtàwọn onílù rẹ̀ rèé
Àjọ NAHCON kéde iye tó ṣeéṣe kí owó Hajj jẹ́ ní ọdún yìí
Bí ìjọba Saudi Arabia ṣe ti kéde wí pé àwọn yóò gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ènìyàn láyè láti kún àwọn tí kópa nínú Hajj ọdún yìí ló ti ń fa awuyewuye láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ọdún kẹta rèé tí àjàkálẹ̀ àìsàn COVID 19 ti ṣe ìdíwọ́ fún ètò Hajj lílọ.
Àjọ tó ń rí sí ètò alálàájì ní Nàìjíríà, NAHCON lọ́jọ́bọ̀ tó kọjá ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn gbogbo àwọn olórí àjọ náà ní ìpínlẹ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè yìí.
Níbi ìpàdé náà ni ìkéde ti wáyé wí pé ó ṣeéṣe kí owó tí àwọn ènìyàn tó bá fẹ́ lọ sí Hajj lọ́dùn yìí wọ mílíọ̀nù méjì àbọ̀.

Aisha Buhari pe àwọn olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà síbi àpèjẹ Iftar
Bí ìwé ìpè tí Aisha Buhari, aya Ààrẹ Muhammadu Buhari, fi ráńṣẹ́ sí gbogbo àwọn olùdíje sípò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú ti lu sórí ayélujára ni ẹnu ti ń kùn ún.
- Àlè kun abilékọ bíi ẹran ọ̀yà láti fi ṣe òògùn owó, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ
- Fayose kìí bá wọn jẹ ìjẹkújẹ, bí Aisha Buhari bá fẹ́ fún èèyàn l'Oúnjẹ ko wá aláìní lọ
- Ẹ wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí àwọn òṣèré fíìmù Yorùbá ti gbé àwọn olólùfẹ́ wọn ní ‘handicap'
- Bí mo ṣe máa rí N100m tí mo fẹ́ fi gba fọ́ọ̀mù APC rèé...
- Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ yóò wà ní Nàìjíríà, àtàwọn orílẹ̀èdè míràn wọ ọdún 2023 - IMF
Àwọn olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP túká, ìmọ̀ràn wọn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Ohun tó tún fa awuyewuye tún ni ìdarí tó wà nínú ìwé ìpè náà ni wí pé àwọn àlejò náà kò gbọdọ̀ mú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ dání wá síbi àpèjẹ náà.
Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ló ń kọminú wí pé báwo ni Aisha Buhari yóò ṣe máa pe irú àwọn èèkan bíi Bola Ahmed Tinubu, Atiku Abubakar, Nyesom Wike, Yemi Osinbajo, Chris Ngige, Bala Mohammed, David Umahi àti Rocha Okorocha tí yóò si fi ìdarí si wí pé kí wọ́n má mú fóònù wá.

Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọ gbì tó wáyé nínú ọ̀sẹ̀ tó kọjá
Àwọn olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP túká
Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto, Aminu Tambuwal ní àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí àwọn parapọ̀ láti fa ẹnìkan kalẹ̀ nínú àwọn kò ì tíì fẹnukò.
Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà ni Bukola Saraki, Gómìnà ìpínlẹ̀ Bauchi, Bala Muhammad, Muhammad Hayatudeen àti Aminu Tambuwal.
Ó ní gbogbo ìjíròrò àwọn ló forí sọ́pọ́n.
Àwọn Kọmíṣọ́nnà kọ̀wé fipò sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun
Kò dín ní àwọn olóṣèlú mẹ́sàn-án tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ lábẹ́ ìṣèjọba gómìnà Gboyega Oyetola láti lọ dupò òṣèlú.
Ìwádìí fi hàn wí pé àwọn kọmíṣọ́nà mẹ́ta, olùbádámọ̀ràn mẹ́ta, alága àjọ bọ́ọ̀dù méjì àti adarí àpapọ̀ kan ló ti fipò sílẹ̀.
















