IMF global report: Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ yóò wà ní Nàìjíríà, àtàwọn orílẹ̀èdè míràn wọ ọdún 2023 - IMF

Oríṣun àwòrán, Google
Ajọ to n ri si Iṣuna Agbaye, IMF ti kede rẹ pe ipa ti ikọlu Russia si Ukraine yoo ko lori mumu ki iye owo awọn ounjẹ o gb'owo lori sii ko ni kere o.
Bakan naa lo ni yoo se ọpọ akoba fun iye ti wọn n ta epo b ati afẹfẹ idana gaasi lọdun 2022 wọ 2023 lawọn orilẹede bii Naijiria atawọn orilẹede miran.
Ajọ IMF gbe eyi sita ninu abajade iwadi kan to pe akori rẹ ni "Awofin ọrọ aje agbaye: Ogun da imugboro ọrọ aje agbaye pada osu kerin ọdun 2022.'
- Ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ló le yanjú ìṣòro ètò ààbò tó mẹ́hẹ - Obasanjo
- "100m tí APC ń bèrè fún owó fọ́ọ̀mù kò ní jẹ́ kí àwọn tó nífẹ́ aráàlù dé ipò ìjọba"
- Awakọ̀ ṣekúpa òṣìṣẹ́ LASTMA
- Ẹ̀yà Igbo ni ipò Ààrẹ kàn, tá a ba fẹ́ àlàáfíà àti àìṣègbè - Adebanjo
- Rádaràda lẹ̀yin olórin ẹ̀mí tẹ́ẹ̀ ń ṣí ara sílẹ̀, tún kó elégbè mẹ́rin kó máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ onílù - Senwele Jesu
- Wo iye tó san to bá fẹ́ lọ sí Hajj ọdún yìí
Gẹgẹ bi ohun ti ajọ iṣuna agbaye naa sọ, ọwọngogo owo ori ọja yoo waye gẹgẹbi asọtẹlẹ rẹ atẹyinwa nitori ogun to n waye ni Ukraine yoo tubọ mu ki nnkan gbẹnusoke sii ju bi o ṣe yẹ lọ.
O fi kun un pe nitori ipa odi ti ikọlu Russia si Ukraine ni lori ikore lẹka eto ọgbin lọdun 2022 bayii, ọwọja ọwọngogo ounjẹ yoo waye wọ ọdun 2023 pẹlu.
IMF ni ọrọ yii yoo kan awọn idile to wa lawọn orilẹede ti ko tii r'ọwọ họri to boṣe yẹ pupọ, paapaajulọ pẹlu owo awọn ounjẹ oniyẹfun.
Atipe awọn orilẹede ti awọn ounjẹ bii agbado, Jero ati irufẹ ounjẹ bẹẹ wa kun ara ounjẹ paapaa lẹkun ilẹ olooru Afrika (Saharan Africa) wọn yoo foju wina ọwọngogo ounjẹ.
O pari rẹ si ori akori pe ọwọngogo ounjẹ yoo goke pupọ lọdun yii bi o tilẹ jẹ pe yoo pada wa dẹrọ diẹ lawọn akoko kan lodun 2023.
















