Bukola Akinade Senwele Jesu: Warisi, Zah zuh, Galalala, wo àwọn àṣàkàṣa tí Senwele ní kò bá òfin Ọlọ́run mu

Oríṣun àwòrán, Senwele Jesu
"Eleyi to maa n bi mi ninu ju laye ati ọrun ni ki wọn ti pe ẹ koo wa kọrin too ti ko elegbe ati onilu ẹ lẹyin too tun wa n fi ẹnu tun nkan ti onilu filu sọ sọ sita.
Waa tun wa ko bii elegbe mẹta mẹrin ki wọn maa pariwo tun nkan ti onilu sọ sọ.
Ariwo a wa pọ lọ rẹpẹtẹ ko ni jẹ ka gbọ nkan ti Ọlrun ran si wa. K'olorin maa kọrin kiwọ naa maa ṣe 'Ọba baba digbẹ digbẹ n gbẹ" o maa n run mi ninu".
Toun ti imura awọn to n gberin lẹyin ga wọn lo bu ẹnu atẹ lu to ni gbogbo iwa yii ko si laarin awọn olorin to gbe iṣẹ orin ẹmi le awọn lọwọ.
"Igba too mọ pe o le da gbogbo ẹ ṣe, ki lo ko wọn lẹyin si".
Ki ni Senwele ri to fi ṣe fidio yii sita?
Gbajugbaja olorin ẹmi, Bukola Akinade figbe yii bọ ẹnu loju opo ayelujara rẹ pe kini kan wa to n dun oun lọkan.

Oríṣun àwòrán, Senwele Jesu
"Rádaràda ni ẹ̀yin olórin ẹ̀mí, tẹ́ẹ̀ ń ṣí ara sílẹ̀ lórí pẹpẹ àti kẹ́ẹ máà kó elégbè mẹ́rin tó ń túmọ̀ ìlù".
O ni awọn kan wa ninu awọn to n hu iwa yii to jẹ ọmọ, ọrẹ ati akẹgbẹ fun oun.
Mama Bola Arẹ, Funmi Aragbaye, Baba Timi Orokoya, Baba Ayewa, Ebenezer Obey gbogbo awọn wọnyii lo darukọ pe wọn kọrin laye atijọ titi di asiko yii ti awọn eeyan ṣi n wari fun.
Olorin yii ti oun naa figba kan jẹ ọdọ amọ to ti di bi ẹgbọn ati iya fun awọn to ṣẹ n gbera dide labẹ akoso ijọ tun ni ko dara bi awọn ọdọ iwoyii ṣe maa n bẹ kiri bi Ẹranko Igala lori pẹpẹ.
"Mo ti sọ pe mo maa tẹ awọn eeyan mọlẹ gidi pẹlu ọ̀rọ̀ ti mo fẹ sọ yii tori awọn eeyan mi wa nibẹ to n hu iwa naa".
Ọna abayọ
Senwele Jesu ni ki wọn da iwa mimọ pada sinu kikọ orin ẹmi ka pada si oju opo ti awọn baba nla wa ati awọn nla wa ninu iṣẹ yii fi wa si".
O ni lẹnu ọjọ mẹta yii, awọn aṣakaṣa kan ti wọ inu agbo orin Kristẹni to jẹ wipe "igba mii ẹ maa wa nibi ti wọn pe ni ṣọọṣi, inu a dẹ maa rin ẹ́".

Oríṣun àwòrán, Senwele Jesu
O ni gbogbo nkan to n gbana jẹ lori ayelujara ni wọn n ko wọ inu ṣọọṣi bayii ti ẹ o wa ni da orin ti Ọlọrun mọ yat si ti Eṣu mọ, gbogbo ẹ ti jọju pọ afi bii ẹni ti wọn ni ko rin wọ inu ina toun naa si n rin lọ.
Senwele ni kii ṣe pe oun jẹ ẹni to mọ ju ẹnikẹni lọ o amọ oun o ba gbogbo nkan ti wọn n ṣee yi nilẹ nigba toun bẹrẹ orin.
"Ẹẹ máa bẹ́ gàràgàrà kiri lórí pẹ̀pẹ̀ lórúkọ pé ẹ fẹ́ "Trend", àwọn ijó tí kò yẹ kí wọ́n bá lẹ́sẹ̀ ọmọ tó ń bẹ nídì ògún, ẹsẹ yin ni wọn a ti ba a".
O ni ki wọn ko gbogbo wọnrọn-wọnrọn ti wọn a maa jo lorii pẹpẹ kuro.
Wariisi
Zah Zuh Zeh
Galalala
Atawọn mii bẹẹ bẹẹ lọ to ni ko tilẹ ye oun bi wọn ṣe n gbe awọn aṣa yii wọ inu orin ẹmi.
"Awọn lo maa n waa yin wa tẹlẹ amọ wọn o le wa mọ tori gbogbo nkan ti wọn n ṣe ninu aye lẹ ti ko wọ inu ijọ". O ran wọn leti ẹsẹ bibeli to sọ pe "lootọ inu aye la wa amọ a o ki n ṣe ti aye".
O ni orin ihinrere nikan kọ leeyan fi le ṣe oriire laye, o darukọ Dadakuada, Takasufee to si ni ẹni ti ko ba ṣetan lati kọ orin mi ko yọ ara rẹ kuro.
Ṣa ka ra ba ba ba bo bo bo - Ifedefọ eke ti run ko fun un yin
"Eyi to buru ju ni ede ti ọrun tẹẹ sọ di yẹyẹ fi ta eyin, awn baba nla ẹ o dẹ to bẹẹ tẹ o maa fi ede ti a ko fi fun yin latrun fọ lori pẹpẹ, waa jẹ iya ẹ oo ni rẹni gba ẹ silẹ".
Bukola Akinade ni oun ko kan ṣaa le sun ni ti ọkan oun ko balẹ afi to n ni ki oun sọ ọrọ yii sita.
O wa gba wọn nimọran pẹlu bẹ pe ki wn ko gbogbo aṣa buruku kuro ninu orin ẹmi kikọ tori pe wọn o le ṣee ki wọn mu u jẹ.
Ẹwẹ, o ni oun o bẹru ẹnikẹni to ba ni esi lati fọ pe ki wọn jade wa koju oun.























