Virginity Hymen: Ṣé ìbálé mi ṣì wà níbẹ̀? Àwọn ìròyìn òfégè tó rọ̀ mọ́ ''virginity '' rèé

A silhouette of a girl

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ilẹ Yoruba, iwuri lo jẹ fun obinrin lati jẹ wundia ti Ibale rẹ wa nibẹ lai ja a titi di alẹ ọjọ igbeyawo.

Ni aye atijọ ati ni aye ode oni, ti obinrin ba ni ibalopọ ni alẹ ọjọ igbeyawo rẹ, wọn ma n tẹ aṣọ funfun, eleyii ti wọn lero wi pe yoo ni apa ẹjẹ, to fihan pe obinrin naa pe laini abuku.

Amọ iwadii tuntun ti fihan pe awọn obinrin miran ti wọn tilẹ jẹ wundia le ma yọ ẹjẹ ni idi fun igba akọkọ ti wọn ba ni ibalopọ.

Bakan naa ni awọn miran wa ti o tilẹ jẹ pe ayederu ibale ni wọn fi sibẹ, ki awọn eniyan ma baa tabuku wọn pe wọn ko ni ibale mọ gẹgẹ bi obinrin to peye.

Amọ, Ajọ Eto Ilera ni agbaye ni ọdun 2018 fi lede pe o ti di itapa si ẹtọ ọmọniyan lati maa ṣe ayẹwo ibale ṣaaju igbeyawo.

Ya "vagina selfie" ki o le mọ boya ibale r wa nibẹ abi o ti ṣi ...

Arabinrin Sarras to sọ iriri rẹ ni oun ṣe akoso oju opo ikansiraẹni awọn ololufẹ ni ede Arabic Facebook ni awọn kan bere ni ọwọ oun pe ṣe oun ti sayẹwo ibale oun.

Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn sọ fun un pe o pọn dandan lati ya ihoho abẹ rẹ ki o le mọ boya wundia rẹ wa nibẹ abi abẹ rẹ ti ṣi.

''Mo korira ọrọ yii ti wọn pe ni ''maftuuha'' eleyii to tunmọ si bii awọn eniyan ṣe n bere pe ''ṣe abẹ rẹ ṣi?''

Amọ, iwadii imọ Sayẹnsi ko fi idi rẹ mulẹ pe ẹni ti ẹjẹ ko ba yọ ni abẹ rẹ fun igba akọkọ to ba ni ibalopọ ko tunmọ si pe o ti lo ara rẹ bajẹ.

Kini iwadii fihan lori jija ibale?

Bi o tilẹ jẹ pe ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan kaakiri agbaye lo gbagbọ pe jija ibale niise pẹlu bi ọmọbinrin ba ṣe lo ara rẹ si, amọ iwadii ni ọrọ ko ri bẹẹ.

Aworan to farajo abale

Oríṣun àwòrán, Prashanti Aswani

Ibale ti awọn oloyinbo n pe ni ''hymen'' ni o wa ni ile oju ara obinrin, ti o si kere lọpọ

Awọn miran gbagbọ pe nise lo bo oju ara obinrin, amọ ko ri bẹẹ, nitori to ba bo o, obinrin ko ni le e ṣe nkan oṣu. Awọn to si ni iru iṣọro bayii nilo iṣe abẹ lati ṣi oju ọna naa.

Bakan naa ni awọn miran gbagbọ pe ibalẹ lee ja ti eniyan ba na ju bo ṣe yẹ lọ, tabi ki ọmọbinrin ma fi ọwọ kan ara rẹ tabi ni ibalopọ.

Iwadii fihan pe eyi ko fi idi mulẹ pe obinrin ti ko ba ni ibalẹ kii se wundia ti ko mọ ọkunrin ri.

Iwadii ti wọn ṣe fun awọn omidan mẹrindinlogoji ti wọn sayẹwo wọn fihan pe awọn miran ti ni ibalopọ lorisirisi ti ibale wọn si wa nibẹ, nigba ti awọn miran ti ko mọ ọkunrin ri ko ni ibale wọn.

Iwadii fihan pe o ṣeeṣe ki oju abẹ obinrin miran ṣe ejẹ ni igba akọkọ ti wọn ba ni ibalopọ, ti awọn miran ko si ni ṣe ẹjẹ.

''Awọn ileewosan kan n e ibale pada fun awọn eniyan to ba f''

O ya ni lẹnu pe awọn kan n ṣe abale wọn pada lẹyin ti wọn ba ti ni ibalopọ lọna ati le jẹ ki awọn eniyan wọn gba wọn ti ọwọ ti ẹṣẹ lalẹ ọjọ igbeyawo.

Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwadii fihan pe ṣiṣẹ ayipada oju abẹ ki ibale le wa nibẹ ni wọn n pe ni ''Hymenoplasty'' ti awọn dokita ayederu kan ma n ṣe fun awọn eniyan lati jẹ ki oju abẹ o ri bi o ṣe wa tẹlẹ.''

Amọ awọn kan gbagbọ pe ọna lati fopin si wahala to rọmọ ibale ni ki wọn yi orukọ rẹ pada.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Bakan naa ni wọn ke si awọn onimọ nipa ibalopọ lati maa kọ awọn eniyan paapaa ọdọ ni nkan to yẹ ki wọn mọ nipa ibalọpọ.

Bẹẹ si ni awọn orilẹede kọọkan ti n gbe igbesẹ lati rii pe wọn fofin de ṣiṣe ayẹwo ibale ''virginity test'' tabi ṣiṣe atunṣe oju abẹ ''hymen repair''.