Osinachi Nwachukwu: Ọkọ Osinachi, Peter Nwachukwu yóò fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ikú ìyàwò rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Osinachi Nwachukwu
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria ti sọ igba ti awọn yoo gbe Peter Nwachukwu to jẹ ọkọ̀ olorin ẹmi Osinachi Nwachukwu lọ si ileẹjọ.
Ọga Agba ọlọpaa ni Naijiria, Usman Alkali Baba lo kede rẹ ni Ọgunjọ, Oṣu Kẹrin, ọdun 2022 lasiko ti o ṣabẹwo si minisita fun ọrọ obinrin, Dame Pauline Kedem Tallen.
Ọga Alkali ni pẹlu bi ọrọ naa ṣe wuwo ni ara eniyan ni yoo mu ki awọn tete bere fun idajọ otitọ.
- 'Ọkọ Osinachi sọ fún un pé kó sùn sílè aṣẹ́wó dípò ilé mi'
- Nǹkan márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Peter, ọkọ Osinachi, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ikú aya rẹ̀ kàn
- Ọdún mẹ́jọ ni ọkọ ọmọ mi kò jẹ́ ki n fojú kan ọmọ mi lẹ́yìn ìgbéyàwó - Ìyá Osinachi
- Ọ̀nà àti yọ ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ àti obìnrin kúrò láwo òṣèlú ni owó fọ́ọ̀mù #100m tí APC kéde - CISLAC
- 'Ó dá mi lójú pé kò ní sí ìdìbò sípò gómìnà ní Osun, Ekiti láíláí ní ọdun 2022!'
- Oluwo, tètè yípadà nídìí títàbùkù Yorùbá tori ewe ń bẹ̀, òògùn wà
- Ṣé lóòtọ́ ni pé mo leè jẹ́ ''virgin" kí ẹ̀jẹ̀ má sì yọ lálẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó? - Ìwádìí fìhàn
''Ileeṣẹ ọlọpaa ti kan si ileewosan ijọba ni ilu Abuja lati sayẹwo oloogbe naa ki wọn le mọ iru iku to pa a.''
''Eleyii yoo mu ki wọn mọ ẹsun ti wọn maa fi kan ọkọ naa fun iwadii boya lootọ oun lo ṣokunfa iku iyawo rẹ.''
''Iku gbigbona ni arabinrin yii ku ti gbogbo ika si na si ọkọ rẹ gẹgẹ bi ẹni to ṣeeṣe ko pa iyawo rẹ.''

Oríṣun àwòrán, Peter Nwachukwu/Facebook
''Iru ihuwasi to jọmọ ifiyajẹni ninu igbeyawo jẹ eleyii ti ko bojumu rara, ti awọn si lodi si patapata.''
Ninu ọrọ rẹ, minisita fun ọrọ awọn obinrin, Kedem ni bi wọn ṣe n fi iya jẹ awọn obinrin ninu igbeyawo ti peleke si ni awujọ bayii.
Bakana naa ni awọn mọlẹbi to wa nibi ipade naa ni awọn fẹ idajọ ododo ni kiakia lori iṣele naa, nitori ijiya naa pọ fun Osinachi.
Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni ariwo iku olorin ẹmi naa, Osinachi Nwachukwu sọ kaakiri ẹrọ ayelujara, ti awọn mọlẹbi si tọka si ọkọ rẹ, Peter Nwachukwu gẹgẹ bi ẹni to lọwọ ninu iku rẹ.
Ọga Agba ọlọpaa ni Naijiria, Usman Alkali Baba ni ẹka ileeṣẹ awọn ni ilu Abuja ni wọn mu ọkọ Osinachi ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ninu ile wọn ni agbegbe Lugbe, ni ilu Abuja.















