Chris Ngige APC N100M form: Màá rí N100m láti fi gba fọ́ọ̀mù láti díje dupò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @SenChrisNgige
Minisita fun ọrọ iṣẹ ati igbanisiṣẹ, Chris Ngige ti ni oun ti ṣetan lati gba fọọmu ẹgbẹ oṣelu APC lati dije dupo aarẹ fun ọdun 2023.
Ngige ni aadọta miliọnu naira ni oun ni lọkan tẹlẹ pe yoo jẹ owo fọọmu amọ o ti da ọgọrun miliọnu naira.
O ni biotilẹ jẹpe igbeṣẹ ọgọrun biliọnu naira ti APC n bere fun ja oun ni aya amọ o da oun loju pe awọn ololufẹ oun yoo ri owo naa kojọ fun oun.
- Fayose kìí bá wọn jẹ ìjẹkújẹ, bí Aisha Buhari bá fẹ́ fún èèyàn l'Oúnjẹ ko wá aláìní lọ
- Ikú Dagrin pé ọdún méjìlá, wo àwọn ǹkan mánigbàgbé nípa rẹ̀
- Wo àwọn ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa gbajúgbajà olóri ẹ̀mí, Tope Alabi
- Erin wóó! Ààrẹ Kenya tẹ́lẹ̀, Kibaki jáde láyé lẹ́ni ọdun 90
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Ogun tẹ ọkùnrin ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá ba obìnrin lò nínú ṣọ́ọ̀ṣì
Ẹgbẹ oṣelu APC lo gbe afikun owo si ọgbọn miliọnu naira, ti owo fọọmu gangan si jẹ aadọrin miliọnu naira.
Ọpọlọpọ awọn eniyan lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ yii amọ ẹgbẹ oṣelu naa ni o da awọn loju pe awọn ọmọ Naijiria ni owo naa lati san.
Ngige to kede ni ọjọ meji sẹyin ni oun ko ni bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ẹgbẹ nitori o da oun loju pe awọn ọrẹ ati ojulumọ wa nilẹ ti yoo fun oun ni owo yii.
CISLAC on APC N100M form: Ọnà àti yọ ọwọ àwọn ọdọ́ àti obìnrin kúrò lawó òṣèlú ní owó fọ́ọ̀mù #100m tí APC kéde
Jakejado orilẹede Naijiria lawọn eeyan ti n mẹnu ba ikede iye owo fọọmu fawn to fẹ dije dupo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress APC.

Oríṣun àwòrán, PRESIDENCY
Ko si ṣẹyin owo ti wọn gbe le gbigba fọọmu naa ti ọpọ wo pe o kọja ikapa awọn to fẹ du ipo.
Ninu iye owo naa eleyi taa ri to mu iriwisi ọtọọtọ wa ni ti ipo aarẹ ti apapọ iye owo naa si jẹ ọgọrun miliọnu Naira.
Lọdun 2015, miliọnu marundinlaadọta lowo tawọn oludije san, amọ bayi o ti di miliọnu ẹgbẹrun Naira lowo fọọmu lati dije ipo aarẹ
Lara awọn to bẹnu atẹ lu iye owo yi ni oludari ajọ ajafẹtọ ọmọniyan kan CISLAC, Auwal Ibrahim Musa.
O fi itara rẹ han ninu atẹjade kan to fi sita kete ti APC kede iye owo yi. O sọ ninu rẹ pe ọna ati yọwọ awọn ọdọ obinrin ati awọn ti ko rọwọ họri kuro ninu awo oṣelu ni.
Ni pataki CISLAC ni igbesẹ ati ikede iye owo yi ti APC ṣe ti wọgile gbogbo wahala ati igbiyanju ti awọn kan ṣe lori mimu ki awọn ọdọ kopa ninu oṣelu.
O sọ pe abadofin Not Too Young to Run ti aarẹ Buhari buwọlu ti gbofo bayi nitori ipa awọn ọdọ ko le ka iye owo naa

Oríṣun àwòrán, APC
''Ki a fi sẹnu ka dakẹ ni wọn ṣe nitori ofutufẹẹtẹ lasan ni abadofin yi jẹ to si fihan pe owo nikan ni kẹkẹ ihiinrere oṣelu ifasẹyin taa n ṣe ni Naijiria''
''Oṣelu to ṣe pe owo lo n ṣatọkun rẹ, iwa baba isalẹ ati aiṣeede ninu ọrọ pinpin fawọn eeyan orileede Naijiria''
Idojuti ni pe aarẹ Buhari buwọlu owo fọọmu N100m
Auwal Ibrahim Musa tẹsiwaju pe idojuti nla lo jẹ pe ẹgbẹ oṣelu ti o jẹ ti aarẹ Buhari gaan lo buwọlu fọọmu iferongba han ati iyansipo lati dupo aarẹ oni N100m.
O ni ọrọ yi buru pupọ paapa lasiko to ṣe pe awọn araalu n pariwo pe asiko to ki awọn ọdọ bẹrẹ si ni kopa ninu oṣelu Naijiria.
Ibeere ti CISLAC wa n beere lẹyin ti ikede yi de eti igbọ araalu ni pe ''Ta lo le ri N100m lọna ẹtọ ti yoo si fi gba fọọmu idije ipo aarẹ?''
- 'Ó dá mi lójú pé kò ní sí ìdìbò sípò gómìnà ní Osun, Ekiti láíláí ní ọdun 2022!'
- Òṣìṣẹ́ ìjọba gba àṣẹ lọ rọọ́kún nílé nítorí ìròyìn òfégè ìkú nípa Gómìnà Akeredolu
- Oluwo, tètè yípadà nídìí títàbùkù Yorùbá tori ewe ń bẹ̀, òògùn wà
- Wo ìjìyà tó wà fún pínpín fọ́rán ìbálòpọ̀ ọmọdé lórí ayélujára
- Ọ̀rọ̀ Ayo Adebanjo pé kí Tinubu, Osinbajo yọwọ́ ní dídu ipò ààrẹ, ṣé gbogbo ẹgbẹ́ Afenifere lọ́wọ́ síi báyìí?
O ni ko wule nilo ki awọn eeyan duro de esi rẹ nitori pe idi ti APC fi gbe igbesẹ yi ni pe wọn ko fẹ kawọn kan kopa ninu eto oṣelu paapa ọdọ,obinrin ati awọn araalu.
CISLAC ni ohun to yẹ ni ki awọn ẹgbẹ oṣelu maa tẹti si ifẹ araalu ki wọn si maa foju oye wo ibi ti igbesẹ wọn yoo kangun si lara araalu.
Bawo ni APC ṣe fẹnuko lori iye owo tabua yi?
Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC lo kede pe awọn ti gbe ẹgbẹrun miliọnu Naira kalẹ gẹgẹ bi apapọ owo ti oludije ipo aar Naijiria yoo san lati fi gba fọọmu.
Nibi ipade ti ẹgbẹ naa ṣe ni ilu Abuja tawọn eekan ẹgbẹ naa wa lọjọ Iṣẹgun ni wọn ti buwọlu owo yi.
Aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari lalaga ipade taa n wi ti ikede yi ti waye ti ko si sọrọ tako iye owo yi.

Oríṣun àwòrán, APC
Ni afiwe iye owo fọọmu ti ẹgbẹ alatako PDP n gba fun awọn to fẹ dije ipo aarẹ, niṣe ni owo ti APC jina tefe si ogoji miliọnu tawọn n beere lọwọ oludije.
Ikede yi tun sọ nipa awọn igbesẹ kọọkan ti ẹgbẹ pinnu lati gbe nipa eto ṣaaju idibo ọdun 2023.
Lọjọ Kẹtalelogun oṣu Kẹrin ni wọn yoo bẹrẹ si ni ta fọọmu fawọn ipo orisirisi tawọn eeyan ba fẹ du.
Gẹgẹ bi akọwe igbimọ eleto ẹgbẹ Sulaiman Argungu ṣe sọ o ni''ni ibamu pẹlu awọn eto ti APC la kalẹ fun eto idibo gbogboogbo 2023,APC ṣetan bayi lati gbe ilana eto jade ni ibamu plu aṣ INEC''
Ninu alaye rẹ:
- Idibo abnu fawọn Gomina yoo waye lọjọ Kejidinlogun oṣu Karun un 2022
- Idibo abẹnu tawọn ile ile aṣofin yoo waye ni ogunjọ oṣu Karun un 2022
- idibo abẹnu ile aṣojusofin yoo waye ni ọjọ kejilelogun oṣu Karun un
- Idibo abẹnu ile aṣofin agba yoo waye ni ọjọ Krinlelogun oṣu Karun un 2022
- Wọn yoo pari gbogbo eto ni ọgbọnjọ oṣu Karun un plu idibo abẹnu fun ipo oludije aarẹ
Iye owo ti APC gbe le awọn fọọmu wọn
- Ile asofin ipinlẹ - N2 million
- Ile aṣoju sofin - N10 Million
- Ile aṣofin agba - N20 million
- Gomina - N50 million
- Aarẹ - N100 million
Lakotan wọn ni fọọmu fawọn oludije obinrin ati awọn to ni ipenija ara ọfẹ nii ṣe.
''Awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun marundinlọgbọn si ogoji dun yoo gba ẹdinwo ida aadọta ninu ida ọgọrun,50% ,''gẹgẹ bi Argungu ṣe sọ.












