Ayo Adebanjo tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ìdí tí ìpó Ààrẹ ṣe tọ́ sí ẹ̀yà Igbo

Ayo Adebanjo

Oríṣun àwòrán, @EmekaGift100

Olori ẹgbẹ́ Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo ti salaye ni ẹkunrẹrẹ lori ọrọ pe ẹ̀yà Igbo lo kàn lati jẹ aarẹ Naijiria.

O sọ eyi ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu iwe iroyin Punch pe,

asiko iha ila oorun Guusu ti tó, lati jẹ aarẹ.

Saaju ni àwọn eeyan kan n bu ẹnu ẹtẹ lu u, lẹyin to sọ ọrọ naa.

Adebanjo sọ fun BBC Yoruba pe, Ila Oorun Gusu Naijiria lo yẹ ki aarẹ ti wa, ti alaafia yoo ba jọba.

"Asiko iha ila oorun Guusu ni lati jẹ aarẹ.

"Mi o ki n sọ ọrọ ti yoo mu arinyanjiyan wa. Ilẹ Igbo lo yẹ ki ipo aarẹ lọ si ọdọ wọn.Amọ ki n to sọ pe Ilẹ Igbo njẹ a ni orileede bii?''

Ti aisegbe ati ibaraẹnidọgba yoo ba wa, ko tọ ki aarẹ Naijiria tun wa lati ibo mii ni Gusu Naijiria, bikoṣe ilẹ Igbo.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Oloye Adebanjo sọ pe Obasanjo to ṣe ọdun mẹ́jọ wa lati Iwọ oorun Gusu, Goodluck Jonathan to ṣe ọdún marun-un wa lati Gusu-Gusu, "ṣe Iwọ-oorun Gusu kii ṣe ara wa ni?".

"Àìṣègbè ati ibaraẹnidọgba, ni ilana to yẹ lati tẹle."

O salaye pe nitori iru nkan bayii ni pinpin nkan kaakiri gbogbo ẹ̀yà to wa ni Naijiria, ṣe wa ninu iwe ofin.

O ni ipo aarẹ gbọdọ lọ kaakiri gbogbo ẹ̀yà, nitori pe lara Naijiria naa ni ẹ̀yà Igbo wa.

"Mi o ki n sọ ọrọ ti yoo mu arinyanjiyan wa. Ilẹ Igbo lo yẹ ki ipo aarẹ lọ si ọdọ wọn."

Àkọlé fídíò, 'Fásitì Nàìjíríà kò gbà mi wọlé ló mú mi sá lọ Ukraine, àmọ́ ohun tí ojú mi rí nínú ogun náà rèé kí ń tó sá wá Nàìjíríà'

Ki lo tin ṣẹlẹ sẹyin?

Ọ̀rọ̀ Ayo Adebanjo pé kí Tinubu, Osinbajo yọwọ́ ní dídu ipò ààrẹ, ṣé gbogbo ẹgbẹ́ Afenifere lọ́wọ́ síi báyìí?

Aworan Osinbajo, Adebanjo ati Tinubu

Ẹgbẹ Afenifere ti sọ pe ọrọ to ba wu olori awọn, Ayo Adebanjo, lo le sọ paapa lori ki Asiwaju Bola Tinubu ati Igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo ma ṣe du ipo aarẹ.

Agbẹnusọ ẹgbẹ naa Jare Ajayi lo fidi ọrọ yi mulẹ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ.

O ni olori Afenifere si ni Ayo Adebanjo o si lẹtọ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria lati sọ nkan to ba wu nipa ẹni to ba fẹ ko du ipo aarẹ Naijiria.

Ko sọ pato boya erongba Adebanjo nipa pe ki Tinubu ati Osinbajo ma dupo aarẹ jẹ ti ẹgbẹ bẹẹ si ni ko tako Adebanjo.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Ajayi tẹsiwaju pe kii ṣe ibi ipade ẹgbẹ ni baba Adebanjo ti sọ ọrọ to sọ nitori naa oun ko le dahun si pe boya ohun ti gbogbo ẹgbẹ faramọ ni nkan ti Ayo Adebanjo sọ.

''Mi o fẹ ko ṣi mi gbọ wi pe mo ni erongba baba ni wọn sọ,baba sọ ọrọ wọn''quite alright'' ṣugbọn awọn ṣi ni olori ẹgbẹ wa, a si tako olori ẹgbẹ wa''

O ni lootọ ni ọrọ Yoruba jẹ awọn logun gẹgẹ bi ẹgbẹ Afenifere ati pe gbogbo nkan ti yoo ba mu ilẹ Yoruba tẹsiwaju lawọn duro le lori.

Njẹ Yoruba yoo tẹsiwaju pẹlu yiyan aarẹ Igbo gẹgẹ bi Adesanya ṣe sọ?

Akọroyin BBC Yoruba beere ọrọ yi lọwọ Agbẹnusọ Afenifere pe bayi ti Adebanjo ti ni ki Yoruba dibo fun Igbo,ṣe anfaani wa nibẹ fawọn ọmọ kaarọ o jiire.

Ninu idahun rẹ o ni ''olori Afenifere ti sọrọ'' ati pe nigba tawọn ṣe ipade awọn fẹnu ko si pe ki aarẹ wa lati apa Guusu Naijiria.

Ko sọ pato pe ẹgbẹ faramọ ki olori wa lati ilẹ Igbo ṣugbọn awọn ko lodi si ki aarẹ wa lati Guusu Naijiria.

''Ṣe ẹ mọ pe igun mẹta lo wa labẹ Guusu Naijiria, South South ni akọkọ, South South ni ẹlẹẹkeji, South East si ni ẹlẹẹkẹta.''

''Nkan taa si fẹnuko nigba taa lọ ẹ ipade pẹlu awọn Middle Belt ni pe ki gbogbo ẹgbẹ jẹ ki aarẹ wọn jade lati Guusu Naijiria''

O ni ori iyẹ n loun mọ pe ẹgbẹ Afenifere ṣi fẹnuko si ati pe ipinnu yi ko tii yi pada.

Àkọlé fídíò, Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn

Kini ọrọ ti Ayo Adebanjo sọ ninu ifọrọwerọ to n mu aweyewuye wa?

Lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin Naijiria Punch ni Oloye Ayo Adebanjo sọ pe ki igbakeji aarẹ Naijiria ati Asaiwaju Ahmed Tinubu wọgile erongba wọn lati di aarẹ.

Adari ẹgbẹ Afẹnifẹre yi ni idi toun fi sọ bẹ ni pe aarẹ to jẹ tẹlẹ Olusegun Obasanjo wa lati ipinlẹ Ogun ilẹ Yoruba ati pe Yemi Osinbajo naa wa lati ibẹ.

O lawọn mejeeji yi to lo ọpọ ọdun lori ipo tori naa ko ba ilana deede mu ki wọn tun gbe ipo aarẹ fawọn to wa lati agbegbe ti wọn ti jẹ ipo aarẹ tẹlẹ.

Nigba ti akọroyin Punch beere lọwọ rẹ boya yoo ṣatilẹyin fun Tinubu Osinbajo tabi oludije kankan to ba wa lati iha iwọ oorun Guusu o sọ pe

'' Bawo ni mo ṣe le gbe lẹyin oludije lati iwọ oorun Guusu Naijiria?Eleyi kii ṣe iṣedeede rarara.Ṣe Obasanjo ko ṣe ọdun mẹjọ gẹg bi aarẹ ni?ṣe Jonathan naa ko ṣe ọdun marun un ni?Ṣe ila oorun Guusu ki ṣe ara Naijiria ni?''

O tẹsiwaju pe a fẹ iṣedeede ati dọgba dọgba.Asiko iha ila oorun Guusu ni lati jẹ aarẹ. Mi o ki n sọ ọrọ ti yoo mu arinyanjiyan wa. Ilẹ Igbo lo yẹ ki ipo aarẹ lọ si ọdọ wọn.Amọ ki n to sọ pe Ilẹ Igbo njẹ a ni orileede bii?''

Ki lawọn igun Tinubu ati Osinbajo sọ?

Awọn igun kan to n ṣe atilẹyin fun igbakeji aarẹ ti sọ pe ohun ti Ayo Adebanjo sọ kii ṣe ero ọkan Afenifere.

Ninu wọn ni Kayode Ajulo to jẹ oludari ẹgbẹ awọn agbẹjọro to n ṣe atilẹyin fun Osinbajo.

O ni ''nibo ni iwe atẹjade ti Afenifẹre ti sọ ọrọ yi?Ipo aarẹ kii ṣe nkan taa kan mọ s nkan to ba wa lọkan wa.Mi o ti ri nkan to jọ bẹ lati ọdọ Afenifere''

Nigba ti BBC kan si Olugbani nimọran pataki si Bola Ahmed Tinubu, Tunde Rahman, o sọ pe ki afun oun lasiko lati jiroro ki oun to le fesi pada.