Bola Tinubu: A óò yọ àwọn ọmọ Naijiria kúrò nínú ìṣẹ́, òṣì, ìṣòró ètò aàbò àti àìmọ̀kan

Tinubu / Adebanjo

Oríṣun àwòrán, Others

Olori ẹgbẹ Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo ti sọ pe bi igba ti Tinubu n pe awọn ọmọ Naijiria, paapaa ẹya Yoruba ni ọ̀dẹ̀ ni ọrọ to sọ pe eto aabo Naijiria yoo dara si i ti oun ba fi di aarẹ.

Adebanjo sọ ọrọ naa fun BBC Yoruba pe kii ṣe igba akọkọ re e ti ẹgbẹ oṣelu APC ti Tinubu wa ti n sọ pe awọn yoo tun eto aabo Naijiria ṣe.

Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, ni Tinubu sọ ọrọ naa gẹgẹ bi ara ipinnu to ni fun awọn ọmọ Naijiria to ba fi wọle si ipo aarẹ lọdun 2023. Ki gan an ló mú kí awuyewuye pọ̀ lórí ìkéde èròngbà Tinubu láti du ipò ààrẹ Nàìjíríà?

Ṣugbọn Adebanjo sọ pe bi wọn ṣe sọ ni ṣaaju idibo to gbe wọn wọle lọdun 2015 ati 2019 niyẹn, amọ ti ko si ayipada kankan. Eyi to tumọ si pe ẹtanjẹ lasan ni.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Adebanjo ni ẹgbẹ Afenifere ko ni i gba eto idibo kankan, ayaafi ti wọn ba fagile ofin ti Naijiria n lo lọwọ, ti wọn si pada si eyi ti Obafemi Awolowo, Nnamdi Azikiwe, Tafawa Balewa ati awọn baba nla Naijiria fi ọwọ si.

Àkọlé fídíò, Kaun

Kini Tinubu sọ?

Lara nkan ti Tinubu tun sọ pe ẹgbẹ APC yoo ṣe ni pe yoo mu awọn ọmọ Naijiri kuro ninu iṣẹ ati oṣi ti wọn ba le dibo fun awọn.

Bola tinubu

Oríṣun àwòrán, @Bola Tinubu

Tinubu lo sọ ọrọ naa ninu fidio kan to n milẹ titi lori ayelujara, nibi to ti n ba awọn alatilẹyin rẹ kan sọrọ lori erongba ẹgbẹ naa fun awọn ọmọ Naijiria.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Bola Tinubu ni pe: "…A oo ṣe eyii ki a ma baa yọ ẹnikẹni silẹ, eyii ko si ni nnkankan n ṣe pẹlu bi wọn ṣe toṣi to."

"Ami ẹgbẹ wa ni igbalẹ, ami to si wa lori fila mi ni jija ajaga… A oo ja ajaga oṣi, a oo ja ajaga iṣẹ ati ajaga aimọkan."

Tinubu tẹsiwaju pe Naijiria nilo alaafia ati ọna lati fopin si bi awọn janduku ṣe n da omi alaafia Naijiria ru.

Lẹyin naa lo rọ awọn alatilẹyin rẹ lati ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu APC nitori ẹgbẹ onitẹsiwaju ni ẹgbẹ naa jẹ, gẹgẹ bii ohun to sọ.

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni Tinubu kede pe oun yoo dije du ipo Aarẹ Naijiria, ati pe oun ti fi erongba naa to Aarẹ Muhammadu Buhari leti.

Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ n lọ nigboro, ti ọpọ patako ajuwe si n kede pe Tinubu yoo dije du ipo Aarẹ, amọ ko sọ nnkankan nipa ipinnu rẹ titi di akoko to kede pe oun ti fi ọrọ naa to Aarẹ leti.

Wayi o, pupọ awọn ọmọ Naijiria lo ti n fi erongba wọn lede lori erongba Tinubu lati dije du ipo Aarẹ.

Bi awọn kan ṣe gbagbo pe oun ni ade Aarẹ naa tọ si nilẹ Yoruba nitori awọn iṣe ribiribi ti wọn ni o ti ṣe sẹyin.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Lawọn mii n sọ pe ipo naa ko tọ si rara nitori bo ṣe dakẹ gbera lasiko ti awọn ọdaran Fulani n pa awọn ọmọ Yoruba, ati atubọtan iwọde EndSARS lọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Eba

Ẹwẹ, awọn ẹgbẹ mii lero pe idibo kọ lo kan ninu ọrọ awọn ọmọ Yoruba lọwọ yii bi ko ṣe ki wọn pin, ki olukaluku si da ọmu iya rẹ gbe.

Gbogbo ẹ gbogbo ẹ, ẹkọ yoo foju mimu han ti asiko eto idibo naa ba to lọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe làlùyọ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí èmi náà ń lọ ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba - Raymond Adegoke