Oluwo of Iwo: Ààrẹ Buhari, ẹ dájọ́ ikú fún gbogbo ẹni tó ń gbé òògùn olóró, agbésùnmọ́mi àti afinisoogun owo

Oríṣun àwòrán, oluwo
Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti rọ ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari lati gbe idajọ iku kalẹ fun gbogbo awọn to n gbe oogun oloro, awọn agbesumọmi atawọn to n gbenipa ṣẹṣo.
Oluwo ni Naijiria yoo dojuru patapata ti ijọba ko ba gbe idajọ iku naa kalẹ lọna ati dẹkun awọn iwa ibajẹ ọhun.
O ni oogun oloro ti awọn agbesumọmi n lo ni ko jẹ ki wọn loju aanu, ati pe nnkan yoo yatọ ti ijọba ba ṣagbekalẹ ofin WAI to wa nilẹ laye iṣejọba Tunde Idiagbon ati Buhari lọdun 1984.
Aarin ọdun 1984 si 1985 ni wọn gbe ofin WAI naa kalẹ, eyii to mu ki alaafia wa laarin ilu, gẹgẹ bii ohun ti Oluwo sọ.
Oluwo gbóríyìn fún Awujale, Akarigbo fún àyípadà òfin lórí àṣà àtijọ́ fún yíyàn Ọba, ṣíṣe ìsìnkú Ọba
Oluwo ni, oogun ti awọn agbesumọmi n lo ti jẹ ki wọn di ọdaju patapata, o si yẹ ki ijọba apapọ gbe idajọ iku kalẹ fun gbogbo awọn to n lọwọ ninu oogun oloro naa.
Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Ali Ibrahim, ori ade naa ni ko si ọjọ kan ti kii si iroyin nipa awọn ajinigbe tabi awọn agbesumọmi, eyi ko si ṣẹyin oogun oloro ti wọn n lo.
Adewale Akanbi sọ pe Buhari gbọdọ pada si ofin oju fun oju to wa nilẹ lọdun 1984 to ba fẹ rẹyin awọn kọlọrọsi to n da omi alaafia Naijiria ru.
O ni "Ti janduku kankan ba gba ẹmi eeyan, ni ṣe lo yẹ ki wọn gba ẹmi oun naa pẹlu."
"Ko yẹ ki ẹni ti ko loju aanu ri aanu gba."
Oluwo pari ọrọ rẹ pe ijọba gbọdọ pese awọn ohun amayedẹrun fun awọn araalu nitori ikuna awọn ijọba to kọja lati ṣe awọn ohun to yẹ fun awọn araalu lo sun Naijiria de ibi to wa lonii yi.














