Kidnapping on Lagos-Ibadan expressway: Ọ̀rẹ́ mẹ́rin tí wọ́n jígbé ni Ibadan sí Eko ti gba òmìnira lẹ́yìn owó ìtúsílẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, olubunmi Olabiyi
Eeyan mẹrin ti awọn ajinigbe gbe salọ ni opopona Ibadan silu Eko ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ti gba ominira.
Ọjọ aiku ni iroyin jade pe awọn ajinigbe to wọ aṣọ ọmọ ologun ji awọn ọkunrin mẹrin naa gbe ni owurọ ọjọ naa nitosi Ishara-Remo nipinlẹ Ogun.
Ibi ayẹyẹ igbeyawo kan ni awọn ọkunrin naa ti n bọ ki wọn o to kagbako ajinigbe.
Iroyin naa waye lẹyin bi ọsẹ kan ti iru rẹ kọkọ jade pe awọn ajinigbe to wọ aṣọ ologun kọlu ọkọ akero Sienaa kan ni opopona Ibadan si eko, abule Onigari, ti wọn si pa awakọ ọkọ naa ki wọn to ji gbe lara awọn ero rẹ.
- Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Gbajabiamila pé: Kò yẹ kí ẹni tí kò kà ju WAEC bíi Buhari jẹ Ààrẹ Naijiria mọ́
- Ilé ẹjọ́ ní kí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò san 4.5m fún alájọgbélé wọ́n tí ariwo 'toilet' wọn kò jẹ́ kó rí oorun sùn
- Fayoṣe ló ń dá PDP Ekiti rú, inú iyàrá kan ni àwọn igún OPA ti kọ orúkọ àwọn aṣojú- Senato Olujinmi
- Àwọn àgbà oyè Ibadan fẹnukò láti gbé ẹjọ́ kúrò nílé ẹjọ́
- Lóòtọ́ ni àrùn Lassa ti wọ ìpìnlẹ́ Oyo, àmọ́ ẹ má mikàn- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Folahan Akinsola, to ṣe inawo sọ pe ibi ayẹyẹ igbeyawo aburo iyawo oun ni awọn ti n bọ lati ilu Ibadan.
O ṣalaye pe ẹyọkan lara awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn n gbe pada si Eko ni owurọ ọjọ Aiku lo ba jẹ si oju ọna.
Nibi ti wọn ti n gbiyanju lati fi okun so ọkọ naa mọ ọkọ miran ti yoo wọ́ ọ de Eko, ni awọn ajinigbe naa jade si wọn.
"A kọkọ ro pe ọmọ ologun ni wọn, ti inu wa si dun pe wọn yoo pese aabo fun wa nibi ti ọkọ wa bajẹ si.
"Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn ni ki gbogbo wa doju bolẹ, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn. Funra wọn ni wọn tọka si mẹrin lara awa meje ti a wa nibẹ pe ki wọn o niṣo ninu igbo."
Orukọ awọn ti wọn ji gbe ni Bude Nathaniel Adeola, John Segun, Demola ati Sola.
Ọgbẹni Akinsola tẹsiwaju pe wọn ni miliọnu lọna ọgọrin ni awọn nilo.
"Bi wọn ṣe gbe wọn wọ inu igbo, ni awa to ku lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ishara-Remo lati sọ nkan to ṣẹlẹ fun wọn. Lootọ ni awọn ọlọpaa tẹle wa de ibẹ, ṣugbọn wọn ni awọn ko le wọ inu igbo."
O fikun pe eyi lo mu ki awọn gbe ọrọ naa sori ayelujara Facebook, ti wọn si tun lọ si ileeṣẹ redio kan nilu Ibadan lati pariwo fun araye.
"Igbiyanju awọn ara adugbo wa nibi ti a n gbe nipinlẹ Eko, to fi mọ ẹbi, ara ati ọrẹ la fi ri miliọnu meje aabọ Naira ko jọ lati fi gba awọn eniyan wa pada."
Ẹni to gbe owo naa lọ fun awọn ajinigbe, sọ fun BBC pe ni oru ọjọ Aje mọju ọjọ Iṣẹgun ni awọn ri wọn gba pada.
O ni oun pẹlu eeyan meji miran to jẹ ẹbi ara awọn ti wọn ji gbe lo gbe owo naa lọ.
Idi ni pe awọn ajinigbe naa paṣẹ fun wọn pe ko gbọdọ ju eniyan mẹta lọ ti yoo gbe owo itusilẹ naa wa.
- Wo ibi ti ìgbẹ́jọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba méjì tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ji ọmọ arábìnrin tó ní arùn ọpọlọ gbé ní Akure
- Muhammed Alfa gún ìyàwó rẹ̀ ọlọ́mọ mẹ́jọ pa nítorí pé ó ń ti ilẹ̀kùn mọ́rí
- Wo ìlú tí wọ́n ti ń gbé òkú ọba wọn pọ̀n lórí ẹṣin lọ fún ìsìnkú nínú igbó
- Àlàyé rèé lórí bí àwọn agbébọn ṣe pa ṣọ́jà méjì, ọlọ́pàá àtọ̀pọ̀ olùgbé ìletò kan ní Kebbi
O ṣalaye pe foonu ẹnikan lara awọn ti wọn ji gbe ni wọn fi n pe lati beere owo itusilẹ.
"Lootọ ni a ko ba wọn duna-dura lori iye owo ti a fẹ ẹ gbe wa, ṣugbọn a ṣa n fi wọn lọkan balẹ pe a ti n ta dukia awọn to wa lọdọ wọn lati ri owo ko jọ."
Bakan naa lo fidirẹmulẹ pe akiyesi oun fihan pe ẹya Fulani ni awọn ajinigbe naa, botilẹ jẹ pe ede Pidgin ni wọn fi n ba awọn sọrọ.
O ni laarin oru ni nkan bi aago kan ni awọn fi n wa ọkọ ni opopona Ibadan si Eko.
Fidio yii lo ṣafihan asiko ti awọn eniyan naa pada sile wọn nilu Ikorodu nipinlẹ Eko
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Gẹgẹ bo sẹ sọ, o ni bi ẹẹmẹta ni awọn n lọ ti awọn n bọ ni opopona naa, eyi to mu ko ṣoro fun wọn lati mọ ibi pato ti wọn ti ri awọn eniyan wọn gba.
"Ẹnikan lara awọn eeyan wa mẹrin ni wọn kọkọ ti si ojupopo nibi ti wọn ni ka pada duro si. Lẹyin naa la gbe owo fun wọn, ti wọn si mu wa wọ inu igbo lati gba awọn mẹta yooku."
"Ẹbẹ la ṣa n bẹ wọn pe ki wọn o ṣaanu wa. Nitori pe wọn n dunkooko pe awọn le pa wa sinu igbo naa, ti awọn yoo si ta ẹran ara wa ni miliọnu mẹwa Naira."



















