Femi Gbajabiamila: Ó yẹ ká sẹ àtúnṣe ìwé òfin wa lórí ìwé ẹ̀rí tó kéré jù tí Ààrẹ yóò ní

Oríṣun àwòrán, @Gbajabiamila
Agbẹnusọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Femi Gbajabiamila ti sọ pe ko yẹ ki ẹni ti ko kawẹkọja ile ẹkọ girama bii Aarẹ Muhammadu Buahri maa dari iṣakoso Naijiria mọ.
Gbajabiamila sọ pe niwọn igba ti wọn ti din ọjọ ori awọn to lẹtọọ lati dije du ipo kuni Naijiria, o yẹ ki wọn le ṣafikun iye gbedeke ẹkọ ti irufẹ awọn eeyan naa yoo ka.
O ni "Yoo jẹ ọna lati ṣe atunṣe si eto idibo orilẹ-ede wa."
- Ilé ẹjọ́ ní kí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò san 4.5m fún alájọgbélé wọ́n tí ariwo 'toilet' wọn kò jẹ́ kó rí oorun sùn
- Fayoṣe ló ń dá PDP Ekiti rú, inú iyàrá kan ni àwọn igún OPA ti kọ orúkọ àwọn aṣojú- Senato Olujinmi
- Àwọn àgbà oyè Ibadan fẹnukò láti gbé ẹjọ́ kúrò nílé ẹjọ́
- DSS, ẹ jẹ́ kí Kanu pààrọ̀ aṣọ tó ń wọ̀ wá sílé ẹjọ́ mi bí bẹ́ẹ̀ kọ́.......- Adajọ Binta Nyako
- Ṣé lóòtọ́ ni gómìnà ìpínlẹ̀ Abia àti Imo wọ àṣo àsíí Biafra bí o ṣe jáde lórí ayélujára?
Gbajabiamila lo sọ ọrọ naa lasiko to n ṣe idanilekọọ nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade awọn akẹkọọ fasiti ilu EKo, UNILAG, ikejilelaadọta iru rẹ.
Agbẹnusọ naa rọ ile igbimọ aṣofin agba lati ṣe agbeyẹwo ati atunṣe ofin Naijiria lọna ati le mu erongba naa ṣẹ.

O ṣalaye pe "Mo gbagbo pe o yẹ ki ile igbimọ aṣofin agba gbe ofin abala 131(d) ninu iwe ofin ọdun 1999 wa yẹwo lọna ati ṣe atunṣe si iwe ẹri to kere ju ti ẹni ti yoo ba du ipo Aarẹ gbọdọ ni, lodi si iwe ẹri to kere ju, to jẹ ti ile ẹkọ girama to wa lọwọ yii."

Ṣaaju ni ọpọ awuyewuye ti kọkọ n waye lori iwe ẹri Aarẹ Muhammadu Buhari ki eto idibo ọdun 2015 to waye.
Ẹwẹ, nigba to di ọdun 2018, ajọ WAEC ṣafihan iwe ẹri Buhari, wọn si fi iwe ẹri naa le lọwọ lọdun naa lọhun.

Sibẹsibẹ, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n sọ pe iwe ẹri WAEC naa ko yatọ si risiiti iwe ina NEPA lasan.
Buhari, to ti kọkọ fi igba kan jẹ adari ijọba Ologun Naijiria ri, ni ọpọ eeyan n pohunrere ẹkun labe iṣejọba rẹ nitori eto ọrọ aje ati eto abo to dẹnu kọlẹ.
Nigab to kọkọ bẹrẹ ijọba naa lọdun 2015, o gba Buhari to nnkan bii oṣu mẹfa ko to kede awọn alabaṣiṣẹ rẹ, eyii to mu ki awọn ọmọ Naijiria kan fun ni orukọ "Baba go slow."
- Ìdìbò 2023: Àwọn ìpèníjà tí Bola Tinubu yóò kojú nínú ìrìnàjò rẹ̀ nìyí
- Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti pín l'Osun, báyìí ni ọ̀rọ̀ ṣe di gbas gbos láàrin Aregbesola àti Oyetola
- Dandan ni kí agbára ìṣèjọba padà sí Gúsù Naijiria ní 2023 - Àwọn olórí ẹ̀yà ní Gusu
- Lórí ìdigunjalè sí Kemi Afolabi, ohun tí òṣèrè náà sọ fáwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ rèé
- Àwọn àwòrán tó ta lẹ́nu nìyí látibi ayẹyẹ ọdún 51 Alafin Oyo lórí àpèrè
- Kí ni Saheed Balogun àti Shina Peters wá lọ sí ilé Ààrẹ Buhari l'Àbuja?
Wayi o, Buhari ti wa sọ lẹnu ̣ọjọ mẹta yii pe iṣẹ Aarẹ ko fi bẹẹ rọ oun lọrun mọ nitori agba ti n de, ṣugbọn ọpọ araalu ni yoo mọ riri iṣẹ takuntakun ti oun ṣe fun Naijiria ti saa oun ba pari.














