Ilé ẹjọ́ ní kí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò san 4.5m fún alájọgbélé wọ́n tí ariwo 'toilet' wọn kò jẹ́ kó rí oorun sùn

Ile igbọnsẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ kan ni orilẹ-ede Italy ti kede gẹgẹ bi owo itunu fun tọkọ-taya kan nitori wọn gbọ ariwo lati ile igbọnsẹ alajọgbele wọn fun ọpọlọpọ ọdun.

Gẹgẹ bi iwe iroyin kan nilu Milan, II Giornale ṣe sọ, idajọ naa waye lẹyin ọdun mọkandinlogun ti tọkọtaya naa to n gbe nile kan ni tosi La Spezia, pe ẹjọ pe ile igbọnsẹ tuntun alajọgbele pọ wọn ṣe, ko jẹ ki wọn o ri oorun sun.

Eyi ni wọn ni ko ṣẹyin bi ariwo omi ṣe ma n pọ lasiko ti awọn to n gbe ni ẹgbẹ́ wọn ba 'flush' laarin oru.

Ile ẹjọ kekere kan ti kọkọ fakile ẹjọ ti tọkọtaya naa pe ṣugbọn wọn pe ẹjọ kotẹmilọrun sile ẹjọ giga nilu Genoa.

Ile ẹjọ naa lo si paṣẹ pe ki iwadii waye lori nkan to mu ki ariwo ile igbọnsẹ naa pọ to bẹẹ.

Iroyin sọ pe awọn arakunrin mẹrin to n gbe ninu 'flat' to wa ni ẹ̀gbẹ́ tọkọtaya naa so àgbá omi ti wọn fi n flush mọ ara ogiri to wa laarin ile igbọnsẹ wọn ati ibi ti ìgbèrí ibusun tọkọtaya naa wa.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Ariwo iro omi ti wọn ba flush, paapaa ni aarin oru ti wọn ma n lo ile igbọnsẹ ni aimọye igba ṣe okunfa bi tọkọtaya naa kii ṣe ri oorun sun.

Àkọlé fídíò, Ọmọ ọdún mẹ́ta ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lu ìlù, kí n tó di onílù Yinka Ayefele

Ile ẹjọ sọ pe o tako ẹtọ wọn gẹgẹ bi ọmọniyan lati gbe igbeaye irọrun, paapaa ni abẹ ofin ilẹ Europe ati ofin to wa fun eto ilera ni orilẹ-ede Italy.

Nitori naa ni ile ẹjọ naa ṣe paṣẹ pe dandan ni awọn arakunrin naa gbe agba omi kuro nibẹ, ki wọn o si san $565 owo Dọla fun tọkọtaya naa fun ọdun kọọkan ti wọn fi lo ẹrọ naa lati ọdun 2003.

Apapọ owo naa lo jẹ $10,760.