Bandits attacks in Kebbi : Àwọn agbébọn pa ṣọ́jà méjì, ọlọ́pàá àtọ̀pọ̀ olùgbé ìletò kan ní Kebbi

Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, defence hq nigeria

Ọpọlọpọ ẹmi lo bọ lasiko ti awọn agbebọn tun kọlu ileto kan ni ipinlẹ Kebbi lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria.

Ni ọjọ Ẹti ni ikọlu yii waye ni ileto Dankade lagbegbe Danko-Wassagu.

Bi o tilẹ jẹ pe iroyin nipa ikọlu naa to tii fi bẹẹ kuna to, ṣọja meji ati ọlọpaa kan wa lara awọn ti awọn agbebọn naa ṣekupa lasiko ikọlu naa.

Awọn iroyin kan n fi iye awọn eeyan to ku si bii aadọta tabi ju bẹẹ lọ.

Bakan naa ni iroyin n sọ pe pupọ awọn to ku ni wọn yinbọn pa ti wọn si du ọpọ miran lọrun.

Awọn olugbe ileto naa tun ṣalaye pe ọpọ eeyan ninu eyi tawọn obinrin wa lawọn ajinigbe naa tun ji gbe salọ.

Àkọlé fídíò, Mo mọ èsì ọ̀rọ̀ kẹ̀, Queen Salawa Abeni ló kọ́kọ́ ta sí mi pé èmi 'Alaragbo ọmọ bàbá olójú kan' ní 1980s - Kuburat Alaragbo

Olugbe ileto naa kan ti ori ko yọ ṣalaye fun BBC pe mọlẹbi oun mẹtala lawọn agbebọn naa pa.

O fi kun unpe ko si ẹni to lee sọ boya baalẹ ileto naa ṣi wa laye tabi ko si laaye mọ.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Olubadamọran fun gomina ipinlẹ Kebbi lori ọrọ abo, Garba Rabiu ṣalaye fun BBC pe iroyin to n tẹ awọn lọwọ ni pe iye awọn to ku ko ju ogun lọ.

O ni awọn agbofinro pa lara awọn agbebọn naa.

Àkọlé fídíò, Èmi ni mo yọ "wipe" fi nu omi ẹkún to ti gbẹ́ àti ikun imú nímú òkú ọmọ tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́ - Ìyá Ojo Emmanuel

Ipinlẹ Kebbi pa aala pẹlu ipinlẹ Zamfara, nibi ti awọn agbebọn ti pa awọn eeyan ti ko din ni igba nigba ti wọn kọlu awọn ileto kan nibẹ.

Ẹkun yii n ba ọwọja ikọlu awọn agbebọn finra, bẹẹni ẹnu ko si lara awọn alaṣẹ fun bi wọn ko ṣe ri nnkan ṣe sii gbọnmọgbọnm ikọlu awọn agbebọn naa.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Ni ọjọ Aiku ni Aarẹ Buhari ṣẹṣẹ gbe aṣẹ kalẹ pe ki awọn ologun o tẹmpẹlẹmọ gbigbogun ti awọn agbebọn lagbegbe naa, paapaajulọ ni ipinlẹ Niger nibi ti igbagbọ ti wa pe awọn agbebọn to wa nibẹ ni ajọṣepọ pẹlu awọn agbebọn Boko Haram.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian