Femi Branch on Bobrisky: Femi Branch ní bí àwọn èèyàn ṣe ń fi orí adé wọ́lẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá lòun sọ̀rọ̀ lé lórí nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bobrisky nílùú Benin

Femi Branch ati Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Instagram/ chief_femibranch/ bobrisky222

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ oṣere tiata, Femi Branch fariga fun ileeṣẹ iroyin abẹle kan lori ọr ti wọ̀n pe o sọ lori ohun ti oju Bobrisky ilumọọka ọmọ jayejaye kan nilu Eko lẹyin ti wọn ni o tabuku ọba ilẹ Bini.

Ọpọ awọn eekan ọmọ ilu Bini ni wọn fariga fun Bobrisky pe ohun to sọ nipa Ọba Benin kọja ẹnu rẹ, awọn ko si fẹ gbọ pe eegun to n baa jẹ orukọ tun ṣẹyọ mọ nilu naa.

Ninu fọnran kan to fi sita loju opo Instagram rẹ, Fẹmi Branch koro oju si ileeṣẹ iroyin naa pe irọ patapata ni wọn pa mọ oun ati pe ko si igba kan ti oun sọrọ pe inu oun dun si bi awọn eekan ilu Benin ṣe fọrọ gba agbari Bobrisky.

Fẹmi Branch ni oun ti oun sọ ni pe asiko to ki awọn eeyan bẹrẹ si ni gbe aṣa wọn larugẹ paapaa nilẹ kootu oo jiire.

Gbajumọ oṣere naa ṣalaye pe oun ti oun sọ ni pe ka ni ilẹ Yoruba leeyan kan ti fi ẹnu sọ isọkusọ si ọbalaye, ko ni si ẹnikẹni ti yoo da iru ẹni bẹẹ lẹkun.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ki ni Femi Branch sọ gan ninu fọnran to fi sita ti iwe iroyin gbe jade?

Ninu ifọrọwerọ kan ti Fẹmi Branch ṣe pẹlu ọmọ Naijiria kan to n gbe loke okun, gbajumọ oṣere naa kọminu lori bi awn eeyan maa n dẹyẹsi ede wọn ti wọn si n fi ede oyinbo ṣe olubori ede ti wọn n sọ.

O ni bi awọn obi ṣe n tọ awọn ọmọ wọn lati maa gbagbọ pe ede abinibi wọn kii ṣe ohun to dara to.

O ni asiko to ki awọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni ni idunnu ati ifọkanbalẹ to yẹ ninu sisọ ede wọn dipo sisọ ohun gbogbo to jẹ toke okun di oriṣa wọn.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Femi Branch sọrọ si awọn oṣere sinima akẹgbẹ rẹ to n sọ sinima Yoruba di eyi ti wọn ti n sọ ede Oyinbo

Femi Branch tun koro oju si bi awọn akẹgbẹ rẹ to n ṣe sinima Yoruba pẹlu ko tun ṣe n ṣe ohun to tọ nipa sisọ ede Yoruba ninu awọn sinima Yoruba gbogbo.

O ni pupọ sinima Yoruba lode oni lo jẹ pe ida aadọrin ninu ọgọrun ọrọ ti wọn ba sọ nibẹ ni yoo jẹ ede Oyinbo.

Àkọlé fídíò, Ọmọ ọdún mẹ́ta ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lu ìlù, kí n tó di onílù Yinka Ayefele

Femi ni: "Ko yẹ ko ri bẹẹ. Nṣe lo n da bi ẹni pe gbogbo eeyan lo fẹ ki wọn mọ pe awọn gbọ ede oyinbo.

O ni idi ti wọn fi n pe e ni sinima Yoruba."

O tẹsiwaju ninu fọnran naa to fi sita loju opo Instagram rẹ lọjọ diẹ sẹyin, pe o yẹ ki awọn ọmọ Yoruba o tubọ ri iyi ati ẹyẹ to pọ ninu aṣa wọn.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian

Femi Branch ni: "Mo fẹ s fun awọn oṣere sinima Yoruba, ẹyin akẹgbẹ mi lati tubọ jawe sobi. Gbogbo aṣa sis oyinbo ninu sinima Yoruba yii gbọdọ dawọ duro.

Bi ẹ ba fẹ sọ ede oyinbo, ẹ lọ maa ṣe sinima ede oyinbo.

Ẹ ṣiwọ sisọ ede Oyinbo ninu awọn sinima Yoruba gbogbo."

Àkọlé fídíò, Arinrinoge ti eyin rẹ kán

O ni awọn olorin lorilẹede Naijiria n gbiyanju ni tiwọn pẹlu bi wọn ṣe n fi ede abinibi ṣe alafibọ ninu orin wọn.

O kan sara si wọn fun ṣe koriya fun gbigbe ede larugẹ bi o tilẹ jẹ pe ko fẹ dabi ẹni pe bẹẹ naa lo ri nipa ti aṣa pẹlu ohun ti wọn n fi sita lori fidio wọn.

Femi Branch

Oríṣun àwòrán, chief_femibranch/instagram

Ki ni ọrọ rẹ lori Instagram nipa ihuwasi awọn Ọbalaye?

Fẹmi Branch tun sọ ọ ninu fọran miran to gbe jade pe ihuwasi awọn ọbalaye miran bayii ni ilẹ Yoruba n kọ ọpọ lominu to si n mu ọpọlọpọ ẹrẹ ba ede, iṣe ati aṣa Yoruba.

O ni ọpọlọpọ awọn Kabiyesi lo n wa sori ayelujara nisiyi lati maa farahan loju opo awọn eeyankeeyan.

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

Femi ni: Ọpọ igba lo ni oun ti ri awọn ọbalaye to n yọnusọ loju opo awọn obinrin fidijaye gbogbo ti wọn n pe ni 'slay mamas'

"Ẹnu maa n yami lọpọ igba ni ti maa tun maa bere pe abi ẹni kan ti fi ipa wọ oju opo Kabiyesi to wa n loo lorukọ wọn ni?

O ni lawọn igba kan sẹyin awọn eeyan maa n gbiyanju ati ṣe bi awn ọbalaye ni, ṣugbọn lọwọ yii awọn ọbalaye gan lo wa n ṣe bi eeyan lasan.

Àkọlé fídíò, 'Ká tó rí irú Akala, ó di "century" míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l'Ogbomoso'