Rice Pyramid Buhari: Ṣé ìrẹsì gogoro ayédèrú ní Aàrẹ Buhari ṣé ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní tàbí òòtọ̀ ?

Buhari

Lẹnu ọjọ mẹta yi, awuyewuye lori aworan iresi onile gogoro ti ijọba Naijiria safihan rẹ ni Abuja ti n da igboro ru.

Ko si sẹyin bawọn kan se n sọ pe iresi yi ko ga to bi wọn ti se lo ga to ati pe wọn fi pako tẹ nidi ni ko ba lee dabi ẹni pe o ga ni tootọ.

Ileesẹ BBC naa ri awọn aworan to lu sita lori ọrọ yi taa si se ayẹwọ finifini nipa ẹka wa ti a gbe kalẹ lati mọ ohun to jẹ ootọ ati irọ nipa iroyin to n jade.

Iwadii wa ti wa pari lori ọrọ yi ta si setan lati sọ okodoro nipa iresi aarẹ Buhari ati awọn ohun to ruju ati eleyi ti ko ruju nipa rẹ.

Njẹ aarẹ tiẹ se ifilọlẹ irẹsi gogogo kankan nilu Abuja?

Ibi lẹbẹ taa ti mu ọọlẹ jẹ ree.

Lootọ ni aarẹ se ifilọlẹ irẹsi yi ni Abuja lootọ.

Buhari

Oríṣun àwòrán, Others

Aworan to wa safihan pako ti wọn fi tẹ irẹsi onilegogoro yi nidi nkọ?

Se o wa lati ibi ifilọlẹ yi ni tabi o jẹ ti ibomiran?

BBC samulo imọ tẹkinọji taa n pe ni 'Reverse image search' ti a si ri pe aworan yi jẹ ti irẹsi gogoro ti wọn tẹ nidi lootọ sugbọn kii se lati ibi ifilọle ti aarẹ se ni Abuja.

Buhari

Oríṣun àwòrán, others

Aworan taa n wi yi la ri loju opo Nairaland sugbọn o wa lati ibi ifilọlẹ irẹsi gogoro eleyi ti wọn se ni ọdun 2018 ni ipinlẹ Ogun.

Wọn ti lo aworan yi lati igba naa titi di asiko taa n wi yi lọpọ ibi loju opo ayelujara.

Abuja ni wọn ti se ifilọlẹ Aarẹ Buhari sugbọn awọn eeyan n se alabapin aworan yi loju opo Whatsapp ati Facebook lati bẹnu atẹ lu ifilọlẹ yi botilẹ jẹ wi pe ipinlẹ Ogun lorisun aworan naa.

Ki lawọn eeyan sọ lori aworan ati irẹsi gogoro yi?

Se ẹ ranti pe amugbalẹgbẹ aarẹ kan Lauretta Onochie lo kọkọ se fidio kan to ti safihan irẹsi onile gogoro ijọba?

Ko pẹ si igba to se fidio rẹ lawọn eeyan da esi pada fun lori ayelujara pe iroyin ẹlẹjẹ lo n gbe seti igbọ araalu.

Iresi

Die ree lara esi ti wọn kọ lori aworan yi:

"Lauretta Onochie,to ba setan pẹlu fọnran ayederu irẹsi gogoro aarẹ to n polowo, ko gbe aarẹ Buhari lọ sibẹ ko lọ ra ninu irẹsi naa''

Iwadii BBC fi han pe irẹsi ti wọn safihan nileesẹ okoowo ati eto ileesẹ ni Abuja ko ni pako labẹ.

Wọn gbe awọn irẹsi yi lori lẹda ti omi ko le duro sara rẹ yatọ si eleyi ti o wa ninu aworan ọdun 2018 tawọn eeyan n pin kaakiri.

Bakan naa awọn apo irẹsi to wa ninu aworan naa yatọ si ei to wa nibi ifilọlẹ ti aarẹ se lAbuja.

Lauretta Onochie se afihan ibi ti wọn ti n ja irẹsi Abuja yi ati pe kii se iresi ti wọn ti bo lo wa ninu apo ti Abuja bi kii se iyangbo irẹsi .

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Alaga ẹgbẹ awọn agbẹ onirẹsi RIFAN arakunrin Aminu Goronyo salaye fun BBC pe osu mẹta ni wọn fi to irẹsi yi debi to ga de.

Eto iranwọ fawọn agbẹ taa mọ si Anchor Borrowers Programme ileesẹ banki apapọ Naijiria lo sagbatẹru iranwọ fawọn agbẹ lati le mu adinku ba rira ounjẹ lati ilẹ okere.

Àkọlé fídíò, Eba

Ijọba sọ pe irẹsi gogoro tawọn to yi lo ga julọ ni Naijiria ati pe lati igba tawọn ti bẹrẹ eto iranwọ fawọn agbẹ irẹsi, iye irẹsi ti wọn n gbin lati 2015 ti fẹ to ilọpo meji ti tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi