Alao Akala: Àwa àti ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo la jọ ń ṣèpàdé, ohun tí mọ̀lẹ́bí sọ gangan rè

Aworan Alao Akala

Oríṣun àwòrán, Facebook/Otunba Adebayo Alao Akala

Ẹbi gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ to ṣalaisi, oloogbe Otunba Adebayo Alao-Akala ti ni iroyin eto bi isinku oloogbe naa yoo ṣe waye to gba ori ayelujara kan kii ṣe ọwọ awọn lo ti wa pe ahesọ ọrọ lasan ni.

Ninu ọrọ kan ti agbẹnusọ mọlẹbi naa, Tolu Mustapha fi sita, o fihan pe digbi ni ijọba ipinlẹ naa n da si bi gbogbo eto isinku naa yoo ṣe lọ.

O sọ eyi ninu atẹjade kan ni ọjọ Iṣẹgun wipe ifọrọjomitoro ọrọ ṣi n waye lori ọna ti wọn yoo gba ṣe eto isinku naa.

Àkọlé fídíò, 'Ká tó rí irú Akala, ó di "century" míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l'Ogbomoso'

Atẹ́jade naa ka bayii pe: Gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Otunba Adebayo Alao-Akala yoo gba eto isinku to ni iyi latọd ijọba ipinlẹ tori naa, ijọba n lọwọ si gbogbo eto isinku rẹ.

ifọrọjomitoro ọrọ ṣi n lọ lọwọ a o si fi gbogbo eto ti a ba la kalẹ fun eto isinku to ni iyi to gbogbo ara ilu leti bi asiko ba ti to".

O ni "mo fi n daa yin loju pe wọn yoo bu ọla fun Otuna jake jado ipinlẹ Oyo".

Ẹwẹ, awọn iroyin kan ti n jade to n sọ pe wọn ti dajọ eto isinku fun gomina Oyo tẹlẹ yii si ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹẹdogun ati ọjọ Ẹti ọjọ kejidinlogun oṣu Keji ọdun 2022.

Amọ o ni ko sohun to jọ bẹẹ to jade wa lati ọdọ awọn.

Ẹ o ranti pe Alao-Akala dagbere faye ni owurọ Ọjọru ọjọ Kejila oṣu Kinni ọdun 2022 ni ile rẹ to wa ni ilu rẹ, Ogbomoso.