Hymen and virginity: Wo àwọn nǹkan tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ara obìnrin tí kò bá ní ìbálòpọ̀ fún ọjọ́ pípẹ́

Aworan Obinrin ati Ọkunrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Tí ó bá ti pẹ́ tí ènìyàn ti ní ìbálòpọ̀, àyípadà máa ń bá ẹ̀yà ara, tí àwọn onímọ̀ sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ara yóò mọ́ yàtọ̀ tí èèyàn bá tún bẹ̀rẹ̀ padà.

Àwọn onímọ̀ ni onírúurú àyípadà tí àìní ìbálòpọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ máa ń fà sí àgọ̀ ara jẹ́ èyí tó máa ń fojú hàn sí ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ orísìírísìí.

Tí obìnrin bá ṣe tán láti máa ní ìbálòpọ̀ padà, ẹ̀rù le máa bà á lórí bí yóò ṣe rí lára rẹ̀, tí yóò sì tún rí àpẹẹrẹ ohun tí àwọn onímọ̀ ìlera ń pè ní "post hiatus" èyí tó túmọ̀ sí pé ó ti ní ìbálòpọ̀ fún ọjọ́ pípẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àwọn onímọ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé ènìyàn padà sí ipò ìbálé.

Àkọlé fídíò, Kìí ṣe ọmọbìnrin nìkan ni Ọlọ́run pàṣẹ fún láti pa ìbálé mọ́

Dókítà Khadijah Abubakar tó jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó nípa inú àti abẹ́ tí àwọn òyìnbó ń pè ní Obstetrician and Gynaecology ní Ìpínlẹ̀ Niger sọ fún ikọ̀ ìròyìn BBC pé kò ṣeéṣe kí ènìyàn padà sí ìbálé tí ó bá ti ní ìbálòpọ̀ rí.

Ṣe o maa n dun eeyan?

Abubakar ní ó ṣeéṣe kí obìnrin jẹ irú ìrora tí ó ní nígbà tó ní ìbálòpọ̀ àkọ́kọ́ nígbà tó bá ti pẹ́ kó tó súnmọ́ ọkùnrin.

Nípa pé ṣé ó ṣeéṣe kí ojú ara obìnrin dí padà, dókítà Abubakar ní ó ṣeéṣe nípasẹ̀ iṣẹ́ abẹ ni èyí tí yóò mú kí obìnrin ṣe ẹ̀jẹ̀ tó bá ní ìbálòpọ̀ nígbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí ó bá ṣiṣẹ́ abẹ náà.

Àkọlé fídíò, Eba

Ṣe eeyan lee di apọn ti ko mọ ọkunrin pada?

"Rara". Idahun ti Dokita Khadijah fọ nigba ti a bere ibeere yii.

O ni "ko ṣeeṣe ki obinrin pada si ipo aimọ ọkunrin kankan lẹyin ti o baba ni ibalopọ".

Kí ni hymen?

Gẹ́gẹ́ bí èrò àjọ onímọ̀ ìlera ilẹ̀ UK, hymen ni ẹ̀yà ara kékeré tó bo ojú ara obinrin, ó máa ń wà ní sẹ̀ǹtímítà kan sí méjì ojú ara obìnrin.

Tí obìnrin bá ní ìbálòpọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ni hymen yìí máa ń ya tó sì máa ń fa ẹ̀jẹ̀.

Àmọ́ ṣá, kìí ṣe ìbálòpọ̀ nìkan ló máa ń fà á tí hymen fi máa ń ya, ó le ya lásìkò eré ìdárayá.

Hymenoplasty ni iṣẹ́ abẹ tí a fi ń dá hymen tó bá ti já padà, kìí ṣe pé yóò dá ìbàlé padà ṣùgbọ́n yóò mú kí obìnrin ṣe ẹ̀jẹ̀ tó bá kọ́kọ́ ní ìbálòpọ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ yìí.