Bola Tinubu: INEC ní PVC kìí parí iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ni ọjọ́ kìí lọ lórí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/Tinubu
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó tẹ́lẹ̀ rí, Bola Ahmed Tinubu, tí tọrọ àforíjì fún sísọ wí pé ọjọ́ ti lọ lórí káàdì ìdìbò tó wà lọ́wọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Tinubu, tó ti fi èròńgbà rẹ̀ hàn láti dupò Ààrẹ lọ́dún 2023, tọrọ àforíjì náà nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ àgbẹnusọ rẹ̀, Tunde Rahman lónìí nílùú Èkó.
Ẹ ó rántí pé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, nígbà tí Tinubu ń bá àwọn ikọ̀ obìnrin láti Ìpínlẹ̀ Èkó sọ̀rọ̀, níbi àpérò àwọn obìnrin ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Abuja sọ wí pé kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò káàdì ìdìbò tó wà lọ́wọ́ wọn dáadáa.
Ó ní kí wọ́n ri dájú pé ọjọ́ kò ì tíì lọ lórí àwọn káàdì ìdìbò náà.
Àtẹ̀jáde ọ̀hún ṣàlàyé pé Tinubu lo ọ̀rọ̀ ọjọ́ lílọ lórí dípò kó sọ pé káàdì wọn lé nílò àtúnṣe tàbí àtúngbéyẹ̀wò.
- Irọ́ ni Tinubu ń pa o, PVC kìí parí iṣẹ́ – INEC
- Ìjọba Buhari, o gbọdọ̀ san bílíọ̀nù kan náírà(N1bn ) owó gbà máàbínú fún Nnamdi Kanu- Adájọ́
- Akẹ́kọ̀ọ́, ìyá rẹ àtàwọn jàndùkú dá bàntẹ́ ìyà fún olùkọ̀ọ́ l'Ogun
- Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀
- Wo àwọn kìnìún tó ń ṣe ọ̀fìnkìn lẹ́yìn tí wọ́n kó covid-19 lára àwọn èèyàn
- Wo bí àwọn ara Ogbomọṣọ ṣe n ṣàárò Olóògbé Alao Akala ní ìpalẹ̀mọ́ dé ètò ìsìnkú rẹ̀
Bákan náà ló yin àjọ INEC lákin fún ṣíṣe ètò ìdìbò tí kò ní ẹja ń bákàn nínú, tó sì tẹmpẹlẹmọ́ ìdí tó yẹ kí àwọn ènìyàn máa kópa níbi ètò ìdìbò lójúnà à ti mú kí ètò ìjọba àwaarawa dúró ire.
Bẹ́ẹ̀ náà ló rọ àwọn obìnrin láti lọ gba káàdì ìdìbò, kí wọ́n sì rí dájú pé wọ́n kópa níbi ètò ìdìbò káàkiri ẹsẹ̀ kùkú.
Tinubu là àwọn obìnrin lọ́yẹ̀ láti ṣe àtúngbéyẹ̀wò orúkọ wọn lọ́dọ̀ àjọ INEC kí wọ́n le ri dájú pé ó pé pérépéré.
Ó kọminú pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fi orúkọ sílẹ̀ ni kì í gba káàdì ìdìbò wọn.
Irọ́ ni Tinubu ń pa o, PVC kìí parí iṣẹ́ - INEC
Ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC, ti sọ fun BBC pe kaadi idibo, PVC, ki pari iṣẹ lodi si ọrọ ti oludije sipo Aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu sọ.
Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti fidio kan ti Tinubu ti sọ pe ọpọ kaadi idibo to wa lode lo ti pari iṣẹ tawọn eeyan ko si mọ.
Ninu fidio naa, nibi ti oloṣelu naa ti wọ ibomu, lo ti sọ pe "Wọn le ma tete sọ fun yin… PVC ti pari iṣẹ."
Tinubu tẹsiwaju pe "Ẹ ni lati tete pin ọrọ yii kaakiri awọn ijọba ibilẹ atawọn wọọdu, lai wo bi yoo ṣe lera to."
- Ọlọ́run Tinubu kìí ṣé Ọlọ́run témi torínáà mi o ní gbè lẹyìn rẹ̀ ní 2023- Ojudu
- Ki gan an ló mú kí awuyewuye pọ̀ lórí ìkéde èròngbà Tinubu láti du ipò ààrẹ Nàìjíríà?
- Ìdìbò 2023: Àwọn ìpèníjà tí Bola Tinubu yóò kojú nínú ìrìnàjò rẹ̀ nìyí
- Tinubu hùwà ọdàlẹ̀, Ọlọ́run kó sì ní gbà fún un lórí èròngbà rẹ̀ - Ohanaeze Ndigbo
- Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀
Bo tilẹjẹ pe a ko le sọ ohun ti Tinubu ni ki awọn eeyan oun pin kaakiri awọn wọọdu, ṣugbọn o tẹsiwaju pe "Adinku n ba bi eto idibo ṣe n waye nitori pe awọn kaadi ti idibo ti n pari iṣẹ."
Ẹwẹ, nigba ti BBC kan si alaga ajọ INEC ni ipinlẹ Anambra, Nkwachukwu Orji, o ni ko si nnkan to n jẹ pe kaadi idibo, PVC, n pari iṣẹ.
Gẹgẹ bii nnkan to sọ, ayipada kan ṣoṣo to le waye si kaadi idibo ki ẹni to ni kaadi paarọ ibi to n gbe, ko si ni ki ajọ INEC yi adirẹsi ounn ati ibudo idibo pada.
Oṣiṣẹ INEC mii ti ko fẹ ki a darukọ oun ṣalaye pe "Kaadi idibo ko dabi kaadi to fun awọn awakọ laṣẹ lati wa ọkọ loju popo, ọjọ kii lọ lori rẹ, bẹẹ si ni kii pari iṣẹ."
- Super Eagles Nàìjíríà gún Guinea Bissau ní kẹ́ṣẹ́ pẹ̀lú 2-0
- Iléẹjọ́ ní Abuja tó fi ẹ̀sùn tuntun kan olórí ẹgbẹ́ IPOB, Nnamdi Kanu ti sún ìgbẹ́jọ́ sí oṣù tó ń bọ̀
- Wo bí ọ̀rẹ́ mẹ́rin tí wọ́n jígbé ni Ibadan sí Eko ṣe gba òmìnira lẹ́yìn owó ìtúsílẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́ ọlọ́pàá
- Wo àwọn kìnìún tó ń ṣe ọ̀fìnkìn lẹ́yìn tí wọ́n kó covid-19 lára àwọn èèyàn
- Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀
BBC kan si awọn alabaṣiṣẹ Tinubu lori ọrọ naa ti adari wọn sọ amọ wọn kọ lati gbe ẹrọ ilewọ wọn.
Ọsẹ to kọja ni Tinubu kede erongba lati dije du ipo Aarẹ Naijiria lẹyin to ni oun ti kọkọ fi ọrọ ọhun to Aarẹ Muhammadu Buhari leti.
Ninu ọrọ rẹ lọjọ naa lọhun, o ni afọbajẹ ni oun, ko sì sí ofin kankan to sọ pe afọbajẹ naa ko gbọdọ dade Aarẹ.















