Alao Akala's burial: Wo bí àwọn ara Ogbomọṣọ ṣe n ṣàárò Olóògbé Alao Akala

Akala

Kò dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì àwọn ọmọ bíbí ìlú Ogbomoso tí wọ́n péjú pésẹ̀ ni ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kìíní, ọdún 2022 síbi ètò títan fìtílà yíde káàkiri Ogbomoso fún ṣíṣe ẹ̀yẹ fún olóògbé Ọ̀túnba Àlàó-Akala.

Àwọn ènìyàn Ogbomoso sì ń kọrin arò lẹ́yìn Ọ̀túnba Christopher Adebayo Àlàó-Akala, tó fi ìgbà kan jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀ rí papòdà ní Ọjọ́rú tó kọjá, látàrí ipa ribiribi tó ń kó sí ìlú rẹ̀.

Láti ìgbà tí Àlàó-Akala ti dágbére fáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá ni ilu Ogbomoso ti kan bóbó bí í wí pé ọmọdé ló kú látàrí ìfẹ́ tí ó ní sí ìlú rẹ̀ àti Ìpínlẹ̀ Oyo lápapọ̀.

Lásìkò ìwọ́de títan fìtílà náà, onírúurú orin arò gba gbogbo ìgboro kan. Ní Oja-agbo, Aromole, Oja Akande àti àwọn ọjà mìíràn, àwọn ọlọ́jà kọ orísìírísìí orin bíi orin ìbílẹ̀, orin ẹ̀sìn láti fi kí Àlàó-Akala pé ódìgbà.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Àwọn tó ṣe ìwọ́de yìí wọ aṣọ dúdú, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de wọn láti ilé Akala ní Randa ní aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ gba Takie, Apake, Star Light, Òkè Ado Akintola, Orita Naira, Oja'agbo, Ijeru, Aromole, Maternity Adeoye, Ologbon, ọjà Akande, Caretaker, Seminary kí wọ́n tó padà sí ilé Akala ní aago méje ìrọ̀lẹ́.

Àkọlé fídíò, Ẹlẹ́wọ̀n: Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo ti kàwé yege ní ìdánwò Jamb

Yàtọ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ tó kópa nínú ìwọ́de yìí àwọn àgbàlagbà lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí ikú Akala jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fùn ún náà kópa.

Bákan náà ni àwọn èèkàn nínú olóṣèlú Ìpínlẹ̀ Oyo bíi Olawumi Oladeji, Segun Dokun Odebunmi Bunvic, Jacob Adejumo Ajao, Mulikat Akande Adeola náà wà lára àwọn tó kópa níbi ìwọ́de náà.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn obìnrin, oníṣẹ́ ọwọ́, lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́, àwọn àkàndá ènìyàn, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú lọ́kan ò jòkan kún ibẹ̀ fọ́fọ́ láti ṣẹ̀yẹ fún Bobagunwa Ogbomoso tó di olóògbé .

Èyí ṣàfihàn pé Akala kò fi ti ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe nígbà ayé rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Eba

Ṣaájú ni àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ olóṣèlú ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bíi Bola Ahmed Tinubu, gómìnà ìpínlè Oyo, Seyi Makinde, gómìnà Ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola àti àwọn mìíràn tí ṣe àbẹ̀wò sí àwọn mọ̀lẹ́bí Akala láti báwọn kẹ́dùn ikú rẹ́.

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́