Maiduguri IDP camp Atrocities: Ọmọ ọdún 14 gún ara rẹ̀ pa lẹ́yìn tí okùnrin ẹni ọdún 35 fi ipá balòpọ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Bornu ti kede pe awọn ti n ṣe iwadii oṣiṣẹ iranwọ kan ti wọn fẹsun kan pe o ba ọmọ ọdun mẹrinla lopọ ni ibudo awọn aṣatipo ti Boko Haram le kuro nile wọn.
Wọn ni afurasi naa, Huzaif Adam, ẹni ọdun marundinlogoji, to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ kan ti kii ṣe ti ijọba, wu iwa ọdanran naa lọjọ Iṣẹgun ni ilegbe 303 Housing Estate to wa niluu Maiduguri.
Iroyin ni ṣe ni afurasi naa tan ọmọ ọhun lasiko ti oun atawọn ọrẹ kan n wa iṣẹ kekeke lagbegbe fasiti ilu Maiduguri.
- Wo bí àbẹ̀wò ọjọ́ méjì tí Aarẹ Buhari ṣe sí Kaduna yóò ṣe lọ
- A óò yọ àwọn ọmọ Naijiria kúrò nínú ìṣẹ́, òṣì, ìṣòró ètò aàbò àti àìmọ̀kan- Tinubu
- Ọlọ́pàá Oyo bẹ̀rẹ̀ kán lu ìgbó láti wá àwọn ajínigbé lópópónà Lagos-Ibadan Expressway
- Njẹ́ ọ̀rọ̀ ipò gómínà Osun ní 2022 kò fẹ́ ẹ̀ da ẹbí Adeleke rú báyìí?
- Àwọn gbajúmọ̀ ọmọ Yorùbá márùn ún tó gbégbá àpótí òṣèlú ní Nàìjíríà
Wọn ni Adam tan ọmọ ọhun pe ko wa ba oun ṣiṣẹ ninu ile oun, amọ niṣe lo ki ọmọ naa mọlẹ to si ṣi laṣọ wo.
Ọkan lara awọn ọrẹ ọmọ naa ni "Ni kete to wọ inu ile rẹ ni okunrin naa tan ina, amọ lẹyin iṣẹju diẹ ni a bẹrẹ si n gbọ igbe ẹkun rẹ."
"A ko ara wa lọ siwaju ile naa, a si bẹrẹ si n kan ilẹkun ṣugbọn okunrin naa kọ lati ṣi ilẹkun ọhun… lẹyinorẹyin, o ṣi ilẹkun naa, si sọ fun wa pe ọrẹ wa n ba oun ṣiṣẹ lọwọ."
"Lẹyin naa ni a ri ọrẹ wa to n wa ẹkun mu, to si n ṣẹ epe fun okunrin naa.
"Ọrẹ wa ni o pe oun ki oun ku ju ki oun mu idiju ba idile ounlo."
- Oluwo: Ààrẹ Buhari, ẹ dájọ́ ikú fún gbogbo ẹni tó ń gbé òògùn olóró, agbésùnmọ́mi àti afinisoogun owo
- Afárá Marina yóò ṣì wà ní títì pa fún ìgbà díẹ̀ fún àtúnṣe
- Àṣìta ìbọn ọlọ́pàá ba akẹgbẹ́ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ìyàwó, ikú dé!
- Hajiya Binta Balarabe Kubaus rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he lẹ́yìn tó lu jìbìtì ₦5.5m
- Iléẹjọ́ ní Abuja tó fi ẹ̀sùn tuntun kan olórí ẹgbẹ́ IPOB, Nnamdi Kanu ti sún ìgbẹ́jọ́ sí oṣù tó ń bọ̀
- Wo àwọn kìnìún tó ń ṣe ọ̀fìnkìn lẹ́yìn tí wọ́n kó covid-19 lára àwọn èèyàn
Lẹyin iṣẹlẹ ọhun ni ọmọdebinrin naa gun ara rẹ lọbe, to si gba ibẹ jade laye.
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Gwange ti fi afurasi naa si atimọle bayii lẹyin ti ọrọ naa to wọn leti.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bornu, Sani Kamilu Muhammad, lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.
O ni awọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ bi ọrọ naa ṣe jẹ, ati pe afurasi ọhun yoo foju bale ẹjọ laipẹ
Ọdọ awọn obi rẹ ni ọmọ ti ọrọ naa kan n gbe lagbegbe Kaleri niluu Maiduguri ṣaaju iṣẹlẹ laabi ọhun.















